Èwo nínú yín ló fẹ́ẹ́ pa Portable Ọmọ Ọlálọmí lẹ́yìn ọjọ̀ọ̀bí ọgbọ̀n ọdun?

Portable

Oríṣun àwòrán, BBC

Ọjọ kejila oṣu kẹta 2024 yii ni Habeeb Okikiọla tawọn eeyan mọ si Portable ọmọ Ọlalọmi, pe ọgbọn ọdun laye. Ṣugbọn lẹyin ayẹyẹ naa lo kede pe ọkan ninu awọn ọrẹ oun fẹẹ pa oun.

Portable tawọn eeyan tun mọ si Idaamu adugbo, sọ pe lọjọ keji ọjọọbi naa lẹni ọhun wọle oun wa pẹlu ero ibi.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni oogun lẹni naa lo wọle ti ẹnikẹni ko fi ri i.

Were olorin tun sọ pe o ya oun lẹnu bawọn aja oun paapaa ko ṣe gbo lasiko ti ẹni to waa pa oun naa wọle.

‘’Yàrá àṣírí ọlà mi ló fẹẹ wọ̀, kò mọ̀ pé yàrá ikú òun ni’’

Portable tẹsiwaju loju opo Instagram rẹ to ṣalaye yii si, o ni yara kan wa ti apaayan naa fẹẹ wọ, o ro pe yara agbara oun ni.

O ni ko mọ pe yara iku tiẹ ni yoo ja si, bo ṣe gbabẹ yọ sajule ọrun niyẹn, tẹni naa dagbere faye.

‘’Ṣalanga lo gba d’ọrun, ọrun rere kọ lo lọ o, ọrun apaadi ni.’’

Olorin Zazu waa kilọ fun gbogbo eeyan lati ṣọra, o ni ki wọn ma jẹ kaye mọ aṣiri ọla wọn. Ki wọn ma baa gba a sọnu lọwọ wọn.