Wọ̀nyí làwọn ohun tó sọ ''June 12'' di mánigbàgbé ní Nàìjíríà títí di òní

Aworan Oloogbe MKO Abiola ati Ibrahim Badamosi Babangida

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

Fun awọn eeyan ti ki i ṣe ọmọ ana, bi a ba n darukọ June 12 ni Naijiria, o ti ye wọn yeke pe ibo alaafia kan ti ko siru ẹ ri, to waye ni 1993, ṣugbọn ti ko pada ri bi wọn ṣe fẹ la n mẹnuba.

Ọjọ kejila, oṣu Kẹfa ọdun 1993, eyi ti i ṣe ọdun mejilelọgbọn bayii ni ibo aarẹ waye kaakiri Naijiria. Baṣorun Moshood Kasimawo Olawale Abiola (MKO), lo dije dupo naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, (SDP), nigba ti Bashir Tofa ti wọn jọ dupo naa jade ninu ẹgbẹ oṣelu National Republican Convention (NRC).

Tolori-tẹlẹmu lo dibo naa fun MKO lai ruju, gbogbo awọn ayẹbowo lo si fidi ẹ mulẹ pe MKO lo jawe olubori.

Afi bi ṣọja to n ṣejọba lọwọ nigba naa, Ọgagun Ibarahim Badamosi Babangida (IBB) ṣe loun fagile ibo naa, to ni Abiola ko ni i di aarẹ.

Ọrọ di wahala, Abiola pada kede ara rẹ gẹgẹ bi aarẹ.

Wọn gbe e ju satimọle, Babangida gbejọba fidihẹ-ẹ de, o ni ki Ernest Shonekan maa ṣe e lọ.

Ọrọ pada kan Sani Abacha, ṣọja kan tawọn ọmọ Naijiria ko le gbagbe lae.

Rogbodiyan ṣẹlẹ lori June 12, Abiola tun ku satimọle, ariwo sọ, oku sun, awọn mi-in ko si bọ ninu wahala naa titi doni, bi wọn ba ti n ranti June 12 ni wọn n ranti adanu wọn.

Ṣugbọn ko too pada di ohun ti iyan ogun ọdun tun n jo IBB lọwọ yii, to waa n kede pe oun kabaamọ iwa toun hu, wọnyi ni atupalẹ ibẹrẹ ati opin June 12 titi doni, ti Babangida n jẹwọ ẹṣẹ rẹ lojude.

Bí Babangida ṣe dìtẹ̀ gbàjọba lọ́wọ́ọ Buhari ni 1985

Aworan Oloogbe MKO Abiola ati Ibrahim Badamosi Babangida

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ ọdun 1985 ni Ọgagun Ibrahim Badamosi Babangida di olori Naijiria lẹyin iditẹgbajọba to fi le Ọgagun Muhammadu Buhari lori aleefa.

Loṣu kin-in-ni ọdun 1986, Babangida ati awọn ikọ rẹ; Armed Forces Ruling Council, (AFRC) gbe igbimọ ti yoo mu ki ijọba Dẹmokresi pada wa, kalẹ.

Babangida sọ nigba naa pe ọdun 1990 loun yoo kuro lori aleefa, kawọn ijọba alagbada si wọle ni pẹrẹwu.

Lẹyin eyi lo tun sun ọjọ ti yoo lọ siwaju, o ni o di 1992. IBB sọ pe o ṣe pataki koun ṣe bẹẹ fun alaafia ijọba awarawa to n bọ.

Awọn iwa yii lo fa inagije ti araalu fun un nigba naa, eyi ti i ṣe Maradona.

Wọn fi IBB we agbabọọlu ọmọ ile Argentina to mọ bi wọn ṣe n ge ede lorii papa, Oloogbe Diego Maradona.

Nipasẹ ofin Decree 25 ọdun 1987, Babangida gbe òté le awọn oṣelu alagbada to wa nigba naa, o ni wọn ko le kopa pẹlu awọn ti oṣelu kẹta (Third republic).

Loṣu karun-un ọdun 1989 lo gbe ote naa kuro.

Ijọba Babangida gbegidina iditẹgbajọba meji , akọkọ ni eyi ti Ọgagun Mamman Vatsa lewaju ẹ ni 1985, ikeji si ni ti ọdun 1990 ti Ọgagun Gideon Orkar lewaju ẹ.

Ìbò abẹ́le wáyé pẹ̀lú iforukọsilẹ ṣaaju ibo June 12

Ọpọ ẹgbẹ oṣelu lo forukọ silẹ lati dupo lẹyin ti Babangida gbe ote kuro lori wọn.

Ṣugbọn mẹfa ni ajọ eleto idibo igba naa, NEC, gba wọle.

IBB kọ awọn ẹgbẹ naa pẹlu alaye pe ẹgbẹ ẹlẹyamẹya ni wọn.

Loṣu Kejila ọdun 1989, Babangida da ẹgbẹ oṣelu National Republican Convention, NRC ati Social Democratic Party, SDP, silẹ.

Ijọba rẹ lo kọkọ n gbọ bukaata awọn ẹgbẹ yii, wọn kọ ọfiisi fun wọn ko too di pe wọn ni ki ẹgbẹ maa gbọ bukaata ara rẹ lọ.

Wọn dibo ijọba ibilẹ ni 1987 ati 1991, wọn di ti awọn gomina ati tile igbimọ aṣofin ni 1991 ati 1992.

Ibo abẹle fun ipo aarẹ waye ninu ẹgbẹ mejeeji loṣu kẹjọ ati ikẹsan-an ọdun 1992, ṣugbọn Bababngida fagile esi naa, o ni wọn ṣe magomago ninu ibo ọhun.

Koda, o fi ofin de awọn oludije to kopa nibẹ pe wọn ko gbọdọ dije mọ, lara wọn ni Oloogbe Shehu Yar' Adua ati Adamu Ciroma.

Lẹyin naa ni IBB ṣe atunto igbimọ ologun rẹ, o tu AFRC ka, o sọ ọ di National Defence and Security Council. Eyi da bii igbimọ oloṣelu, o si fi Oloogbe Ernest Shonekan ṣe oori ẹgbẹ naa.

Nigba ti wọn pari eto gbogbo, Oloogbe Bashir Tofa, oniṣowo nla lati Kano, lo jade bii ondupo aarẹ fun ẹgbẹ NRC, MKO Abiola toun naa jẹ olowo nla ati oniṣowo si jade fun ipo aarẹ ninu SDP.

Ilana ibo ti a mọ si Option A4, ti wọn ti n dibo lojukoroju ni wọn lo, ko ruju rara.

Abiola yan Baba Gana Kingibe ni igbakeji rẹ, Tofa si yan Sylvester Ugoh bii igbakeji.

June 12 ku ọjọ̀ meji, Nzeribe ni ìbò ààrẹ kò gbọdọ wáyé

Lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa ọdun 2012, nigba ti ibo aarẹ ku ọjọ meji, ẹgbẹ kan to n fọnrere ijọba Babangida, 'Association for a better Nigeria', ti Arthur Nzeribe n dari, kede pe idibo naa ko gbọdọ waye.

Nzeribe sọ pe oun ti gba iwe kootu giga to n paṣẹ pe idibo ko gbọdọ waye.

O ni kootu woye pe awọn magomago kan yoo ṣẹlẹ ninu ibo naa.

Humphrey Nwosu, alaga ajọ eleto idibo igba naa lo fagile iwe Nzeribe, o ni ile-ẹjọ ko laṣẹ lori ọrọ ibo ti ko ti i waye rara.

Ibo pada waye lọjọ kejila, oṣu Kẹfa ọdun 1993 (June 12, 1993), awọn awoye ibo nilẹ yii ati loke okun si sọ pe ibo naa lọ ni irọwọrọsẹ kiri Naijiria.

Èsì ìdìbò dé

Lọjọ kẹta ibo, NEC bẹrẹ si i kede esi.

Abiola ti gbegba oroke nipinlẹ mọkandinlogun (19) ninu ipinlẹ ọgbọn (30) ti Naijiria ni nigba naa, o si ti bori l'Abuja ti i ṣe olu ilu Naijiria pẹlu.

MKO wọle ibo ni gbogbo ipinlẹ ilẹ Yoruba, o wọle nipinlẹ mẹta ninu meje to wa ni Guusu Ila-Oorun Naijiria.

O borI ibo nipinlẹ marun-un ninu mẹsan-an to wa l'Oke-ọya nigba naa, titi kan Kano ti i ṣe ilu ti Tofa ti wa, bẹẹ lo si gbegba oroke nipinlẹ mẹrin ninu meje to wa laaarin gbungbun Naijiria.

Ninu apapọ ibo 6.6 million ti wọn kede, Abiola ti ni 4.3million, Tofa si ni 2.3million.

To ba ṣe pe wọn gbe ipo aarẹ naa fun MKO nigba yẹn ni, ọkunrin naa ni ko ba jẹ Yoruba akọkọ to di aarẹ Naijiria pẹlu ibo kaakiri origun ilẹ yii, ti ẹnikẹni ko fi ti ẹya ṣe ki wọn too fi fun un.

IBB fagile èsì ìdìbò June 12, wàhálà bẹ́ sílẹ̀ ní Naijiria

Aworan Ibrahim Babangida

Oríṣun àwòrán, Presidency

Àkọlé àwòrán, IBB

Bi esi idibo ṣe n jade lawọn araalu ti n dunnu, wọn ti n fo fun ayọ ayipada ijọba awarawa to n bọ, ati ti pe Abiola ti wọn mọ si ẹlẹyinju aanu ni yoo maa ṣe aarẹ awọn lọ.

Ṣugbọn ibi ti wọn foju si, ọna kọ ko gbabẹ, Badamosi Babangida ko jẹ.

Aarẹ Ibrahim Badamosi Babangida fagile idibo ti ko ni wahala kankan ninu naa, June 12 ko si pada ri bawọn eeyan ṣe ro pe yoo ri.

Ireti araalu to dofo yii lo fa a ti wọn fi bẹrẹ si i fi ẹhonu han.

Ọpọ iwọde lo waye loṣu Keje ọdun 1993, o le ni eeyan ọgọrun -un ti akọsilẹ sọ pe awọn agbofinro pa.

Awọn ẹya Igbo naa filu Eko silẹ, wọn sa pada siluu wọn nigba ti rogbodiyan bẹ silẹ.

Rogbodiyan yii fa dana sunle, dana sun mọto, dana sun dukia, awọn ẹlomi-in rin pade rogbodiyan, wọn o rile pada si mọ titi doni, wọn ba wahala June 12 lọ.

Awọn orilẹede agbaye koro oju si iwa ijọba Naijiria, UK, America, Ajọ Iṣọkan ilẹ Europe ati Commonwealth bu ẹnu atẹ lu bi IBB ṣe fagile ibo June 12.

Bi wọn ṣe n bu ẹnu atẹ lu ijọba IBB loun naa n dahun pe ohun ti ko kan wọn ni wọn da si .

Nigba naa si ni Olusegun Obasanjo, Muhammadu Buhari ati awọn ọga ologun kan dide ija, wọn pe fun iyọkuro IBB nipo aarẹ.

Babangida naa ko dakẹ, o bẹrẹ si i gbẹsẹ le awọn ileeṣẹ iroyin to ba n kede June 12, ọpọ akọroyin ni wọn mu ju si atimọle, bẹẹ ni ijọba bẹrẹ awọn ofin ti ko ni i faaye gba gbigbọ ẹjọ esi ibo naa ni kootu.

Lati ja fun ẹtọ rẹ, Abiola lọ si London ati Washington lati beere atilẹyin wọn, iyẹn loṣu Kẹjọ 1993.

O pada de loṣu Kẹsan-an.

Bẹẹ ni awọn igbimọ ti Babangida ni ko maa ri si ọrọ ilu bẹrẹ si i sọ fun IBB pe ko fipo naa silẹ.

Awọn banki daṣẹ silẹ, ileeṣẹ gbogbo bẹrẹ ifẹhonuhan lati ṣatilẹyin fun Abiola.

Babangida yan Shonekan, ó ní kó máa fìdí hẹ-ẹ lórí ìjọba

Nigba ti wahala naa doju ẹ fun IBB, o kuro nipo olori Naijiria lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹjọ ọdun 1993.

Bo ṣe n lọ lo fa agbara le Ernest Shonekan, ọmọ ilu Abeokuta bii Abiola lọwọ, Sani Abacha to wa nipo ẹṣo alaabo (Defence minister) si wa nibẹ bii amugbalẹgbẹẹ rẹ.

Shonekan kede idibo mi-in, o ni yoo waye loṣu Keji ọdun 1994.

Ṣugbọn iṣakoso tiẹ ko lori-ko-nidii, nitori ariyanjiyan wa nipa pe ṣe oun naa ni olori awọn ologun.

Ile ẹjọ giga kan l'Ekoo pada sọ pe iyansipo Shonekan ko ba ofin mu, wọn ni Babangida to ti fipo silẹ lo yan an sibẹ, eyi si mu ijọba naa lodi sofin.

Ijọba Shonekan ko ri eto ọrọ aje ṣe, gbese ati ọwọngogo ọja lo ba de.

Banki agbaye tilẹ ka Naijiria mọ ọkan ninu awọn orilẹede ogún agbaye ti iya n jẹ ju nigba naa.

Sani Abacha gbajọba mọ́ Shonekan lọ́wọ́

Oloogbe Ọgagun Sani Abacha

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty images

Lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 1993, Sani Abacha, ṣoja alagbara igba naa, gbajọba mọ Ernest Shonekan lọwọ.

Abacha tu gbogbo ohun to jẹ mọ ijọba fidihẹ-ẹ ka, bẹẹ naa lo fagile awọn ijọba ipinlẹ ati ti ibilẹ, o si fi awọn ṣoja ati awọn ọlọpaa sipo.

Bakan naa lo fagile gbogbo eto awọn oloṣelu pata.

Ijọba alakatakiti, ko-gberegbe ati eyi to mu ki kaluku ṣọ ara rẹ ni Abacha ṣe lati 1994 to ti gbajọba, titi di ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa ọdun 1998 ti iku pa oju rẹ de sile ijọba, Aso-Rock, l'Abuja.

Abiola gbìyànjú láti gba ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ, ṣùgbọ́n...

Ṣaaju iku Abacha ni MKO ti n gbiyanju lati gba ipo aarẹ to tọ si i.

Nibi igbiyanju naa lo ti kede ara rẹ gẹgẹ bii aarẹ lọjọ kọkanla, oṣu Kẹfa ọdun 1994.

Epetedo nipinlẹ Eko lo ti kede naa, ijọba si kede oun naa bii ẹni ti wọn n wa, to ṣẹ si ofin ijọba Naijiria.

Lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa ọdun 1994, wọn mu MKO Abiola, wọn ti i mọ gbaga ijọba.

Iroyin sọ nigba naa, pe yatọ si Kurani ati Bibeli, Abiola ko ri iwe kankan ka, ko ka iwe iroyin, ko wo tẹlifiṣan bẹẹ ni ko gbọ redio latimọle ti Abacha fi i si.

Ninu atimọle naa lo wa ti iku fi de lọjọ keje, oṣu Keje ọdun 1998, iyẹn oṣu kan lẹyin iku Abacha.

Wàhálà wà, lẹ́yìn ikú Abiola

Iku Abiola naa ko lọ bẹẹ, o ko ipayinkeke ba araalu, ifẹhonuhan to lagbara tun bẹrẹ, kaluku n beere ohun to pa Abiola satimọle, pẹlu gbogbo igbiyanju rẹ.

Iku iyawo rẹ ti i ṣe Kudirat, pẹlu, ẹni ti iku rẹ wa lati ọwọ ikọ ologun Abacha.

Nibi ti obinrin naa ti n wa ọna bi ọkọ rẹ yoo ṣe jade lẹwọn ti yoo si di aarẹ Naijiria ni wọn ti yinbọn pa a lọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa ọdun 1996.

Gbogbo eyi fa eronu araalu, o si pada di rogbodiyan, ti wọn fi n sọ nigba naa pe; 'wahala wa, lẹyin iku Abiola.'

Lati ma ṣe gbagbe ijangbara ati iyanju Abiola fun Demokresi, Muhammadu Buhari, aarẹ ana, sọ June 12 di ọjọ isinmi lọdọọdun ni Naijiria, ni iranti Oloogbe, MKO Abiola.