Wo bí iléeṣẹ́ ìròyìn RT tí Russia ń ṣàtìlẹyìn fún ṣe ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn akọ̀ròyìn ilẹ̀ Afirika

Oríṣun àwòrán, RT Academy website
- Author, Global Disinformation Unit
- Role, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ọga agba ileeṣẹ iroyin RT ti Kremlin lati Russia n ṣatilẹyin fun fidi rẹ mulẹ nigba to n bawọn akọroyin lati ilẹ Afirika sọrọ wi pe ileeṣẹ iroyin naa jẹ ọkan ilumọọka ileeṣẹ iroyin lagbaaye nipa fifi idi otitọ mulẹ.
Akọroyin BBC kan darapọ mawọn to wa nibi idanilẹkọọ naa lati mọ ohun to da le lori gan an.
Ileeṣẹ iroyin RT ti wọn le kuro ni Yuroopu ati Amẹrika, ti wọn si kede ijiya to tọ fun wọn lori ẹsun pe wọn n gbe iroyin ofege ko bikita rara nipa sisọ oniruuru iroyin ofege fawọn to wa nibi idanilẹkọọ naa.
Oju ti ileeṣẹ iroyin RT fi ri gbogbo aye
Lẹyin ti wọn fofin de wọn ni UK, EU, Canada ati Amẹrika lori ẹsun pe Russia n lo ileeṣẹ iroyin naa lati parọ fun gbogbo aye nipa ogun to n lọ laarin Ukraine ati Russia, RT ṣe agbekalẹ idanilẹkọọ kan fawọn akọroyin lati apa Guusu Asia, China ati ilẹ Afirika.
RT ni nilẹ Afirika ni eto yii ti so eso rere julọ tori o le ni ẹgbẹrun akọroyin lati ilẹ Afirika ti wọn kopa ninu eto ọhun.
BBC ko le fidi nọmba yii mulẹ ṣugbọn ẹri wa pe eeyan to le ni ọdunrun un wa lori itakun Telegram lati kopa ninu eto ọhun.
Akọroyin BBC kan wa lara awọn eeyan naa eyi to fun un lanfaani lati kopa ninu oriṣiiriṣii eto nipa wiwo oniruuru fidio fun oṣu kan.

Oríṣun àwòrán, RT Academy website
Awọn fidio tawọn akọroyin n wo fun idanilẹkọọ to ọgbọn niye, awọn ọgalọga ninu awọn akọroyin RT si wọn n kọ wọn.
Eto yii da lori awọn nnkan tawọn to ba ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ oniroyin maa n ṣe bii ọna lati ṣe iwọfọwanilẹnuwo, bi eeyan ṣe le wa iroyin, kikọ itoyin yajoyajo, nigba ti sisọ ọrọ nipa Kremlin ko gbẹyin ninu gbogbo nnkan wọnyi.
Fun apẹẹrẹ, ọkan lara idanilẹkọọ naa da lori bi RT ṣe gbe iroyin jade lori agbegbe Mariupol nibi tawọn Ukraine ti tuuba.
Ti wọn fi pari idanilẹkọọ naa, wọn gbiyanju lati fidi rẹ mulẹ RT jẹ ileeṣẹ iroyin to yatọ sawọn eleyii tawọn eeyan ti mọ tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, RT website
Ọkan lara awọn to n ṣagbatẹru idanilẹkọọ naa sọ nipa awọn irọ ti ileeṣẹ iroyin RT maa n pa nipa Kremlin.
Ileeṣẹ iroyin RT ti wọn le kuro ni Yuroopu ati Amẹrika, ti wọn si kede ijiya to tọ fun wọn lori ẹsun pe wọn n gbe iroyin ofege ko bikita rara nipa sisọ oniruuru iroyin ofege fawọn to wa nibi idanilẹkọọ naa.
O ni: ''Russia ti kọ awọn ẹsun yii.Bẹẹ ni awọn igun Ukrain naa ko ti i sọ kulẹkulẹ ohun to fa adanu yii. Ọdun keji re ti aọju ijọba apapọ Russia ti n beere orukọ awọn ti wọn sọ pe wọn pa. ''
Ṣugbọn o foju han kedere pe wọn pa awọn ọmọ ogun Russia pa awọn araalu ni Bucha, pẹlu iwadii lati ọdọ awọn ajọ aladaani ati ajọ iṣokan to n r si ẹtọ ọmọniyan .

Oríṣun àwòrán, Telegram channel RTschool
Ọpọ ninu awọn akọroyin lati ilẹ Afirika ti wọn kopa ninu idanilẹkọọ naa ko bikita nipa iroyin ofege ti RT n fi lede.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, akọroyin to wa lati Ethiopia, Dereje Yiemeru, to dabi ẹni pe o nifẹ si Aarẹ Vladinir Putin Russia naa sọ nnkan ti RT n sọ nipa ipaniyan Bucha ti ileeṣẹ iroyin RT ni iroyin ofege ni.
O ni oun darapọ mọ idanilẹkọọ naa tori oun fẹ mọ nnkan ti wọn n ṣe nibẹ gan an yatọ si ohun tawọn ileeṣẹ iroyin mii n ṣe.
Lẹyin idanilẹkọọ naa ni wọn sọ fawọn akọroyin to kopa nibẹ pe ki wọn kọ iroyin kan tawọn ileeṣẹ iroyin yooku ko kọ, eyi to wa ni ibamu pẹlu alakalẹ RT.
Nigba ti BBC beere wi pe ki ni idi ti wọn fi ṣe agbekalẹ iadnilẹkọọ naa, wọn o le dahun taara.
Ohun ti wọn sọ ni pe RT maa n gbiyanju lati kọ awọn oniroyin lori ọna lati mọ iroyin gidi yatọ si ofege iroyin.
Ọrọ lori ilẹ Afirika
Ni ipari ọdun 2024, ọga agba eto iroyin ileeṣẹ RT, Margarita Simonyan sọ pe bi wọn ṣe n tako awọn ni Yuroopu ati Amẹrika lo jẹ ki ileeṣẹ doju idokowo rẹ gba ibomiran.
Awọn eto to tako imunilẹru ti Russia maa n ṣagbatẹru rẹ lo jẹ ki ilẹ Afirika ni ibasepọ pẹlu orilẹede Russia.
Ileeṣẹ iroyin Russia sọ pe RT ni ọfiisi ni bii orilẹede Afirika meje bayii, ti o si tun n lo ede ilẹ Afirika bii ọgbọn fun siṣe eto ati iroyin rẹ.
Yatọ si pe RT n ṣeto ni ede Gẹẹsi ati Arabiiki, o tun ti bẹrẹ si ni ṣeto ni ede Faranse.

Oríṣun àwòrán, RT website
Eto kan ti wọn pe ni ''Idi ti mo fi lọ si Russia'' ṣapejuwe bi awọn ọmọ orilẹede Amẹrika ṣe n ṣalaye idi ti wọn fi lọ si Russia tori pe awọn ile ẹkọ kan l'Amẹrika maa n kawọn akẹkọọ lati sọ ara di ọkunrin lati obinrin tabi lati obinrin di ọkunrin.

Oríṣun àwòrán, Telegram channel Rossotrudnichestvo
Ọna lati ṣe ifẹ Russia
Kii 'se RT nikan lo n ṣe idanilẹkọọ fawọn akọroyin nilẹ Afrika, China naa ti n ṣe iru eto yii fun bii ọdun mẹwaa.
Koda, awọn ileeṣẹ iroyin nla bii BBC naa n ṣe iru eto yii nipa ẹka ileeṣẹ wọn ti wọn n pe ni Media Action.
Philip Obaji Jr to jẹ akọroyin ọmọ Naijiria sọ pe ohun ti RT n ṣe ni lati jẹ ki awọn ọmọ Afirika maa ro daadaa nipa Russia.
O ni nnkan ti Russia n ṣe ni lati jẹ ki awọn eeyan Afirika mọ nipa ohun to n ṣẹlẹ ni Russia.












