"Ọlọ́pàá ti ilẹ̀kùn ọọ́físì àjọ elétò ìdìbò Osun, fi ṣìkùn òfin mú òṣìṣẹ́ rẹ̀"

OSSIEC
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Alaga ajọ to n ri si eto idibo nipinlẹ Osun, OSSIEC, Hashim Abioye, ti kede pe awọn ọlọpaa ti fi ṣikun ofun mu awọn oṣiṣẹ ajọ naa to n ṣiṣẹ eto idibo ijọba ibilẹ lọjọ Satide.

Abioye lo ọsọ naa ninu atẹjade kan ti fi lede loju opo X ajọ ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe o kan sara sawọn eeyan ipinlẹ ọhun fun bi wọn ṣe jade lati dibo, o ni ki wọn jeburẹ fun bi awọn ohun elo idibo koṣe pọ to.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọọfisi ti awọn ohun elo idibo naa wa ni awọn ọlọpaa gbe agadagodo si.

Abioye sọ siwaju si pe ọlọpaa to n mu awọn oṣiṣẹ ajọ naa ni ko jẹ ki awọn ohun elo idibo tete de awọn ojuko idibo kan.

O ni "Awọn ọlọpaa ti fi panpẹ ofin mu awọn oṣiṣẹ ajọ wa to n ṣiṣẹ eto idibo.

"Fun awọn agbegbe ti wọn ko tete ri awọn ohun elo idibo, ko ṣeyin bi awọn ọlọpaa ṣe n mu awọn oṣiṣẹ ohun elo naa lo si ojuko idibo."

Wayi o, eto idibo naa ti pari kaakiri ipinlẹ ọhun gẹgẹ bi ohun ti ajọ naa sọ, wọn si ti n reti esi.

Ìbò ìjọba ìbílẹ̀ bẹ̀rẹ̀ l' Osun, Gómìnà Adeleke dìbò rẹ, àwọn ibùdó ìdìbò dá páropáro

Aworan

Eto idibo ijọba ibilẹ ti bẹrẹ bayii nipinlẹ Osun.

Gẹgẹbi ohun ti BBC le ṣalaye jijade awọn oludibo fun idibo naa mẹhẹ pupọ.

Lawọn agbegbe idibo ti BBC de ni owurọ ọjọ Abamẹta, paroparo lawọn ibudo idibo da, bẹẹni awọn oṣiṣẹ ajọ idibo ko tii de ọpọlọpọ awọn Ibudo idibo titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ.

Gomina Adeleke dibo

Aworan Gomina Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Amọṣa Gomina ipinlẹ Ọsun, Ademọla Adeleke ṣalaye pe igbagbọ oun ni pe awọn oludibo yoo jade dibo laisi wahala nitori pe oun ti ba wọn sọrọ pẹlu idaniloju pe idibo naa yoo tẹsiwaju, ko si ni si wahala kankan.

to si jẹ ohun iyalẹnu fun ọpọ awọn eeyan ẹku ijọba ibilẹ ariwa Ede nigba ti Gomina Ademola Adeleke dibo rẹ saaju aago mẹjọ owurọ ọjọ Satide

Gomina Ademola Adeleke nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni o ti han gbangba bayii pe alaafia wa ni ipinlẹ Osun.

"Eto Idibo wa n lọ pẹlu alaafia, mo ba awọn eeyan ipinlẹ Osun sọrọ pe eto idibo yii gbọdọ waye pẹlu alaafia nitori ipinlẹ alaafia ni ipinlẹ Osun."

Bakan naa ni Gomina rọ awọn araalu pe ki wọn jade pẹlu alaafia lati wa dibo, ki wọn si pada si ile wọn pẹlu alaafia.

"Mi o fẹ rogbodiyan rara, a fẹ fun awọn eeyan lọrọsọ pe wahala wa ni ibi kan."

Botilẹ jẹ pe digbi ni ọpọ awọn ẹsọ alabo wa bayii nipinlẹ Osun lonii ti eto idibo ijọba ibilẹ yoo waye kaakiri ijọba ibilẹ to wa ni ipinlẹ Osun.

Bẹẹ ba gbagbe, ana ni Gomina Ademola Adeleke kede pe mimi kan o mi wiwaye eto idibo ijọba ibilẹ naa nipinlẹ Osun lonii.

Saaju ni Ileeṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe eeyan mẹfa lo padanu ẹmi wọn ninu rogbodiyan oṣelu to waye lọjọ Aje l'Osun.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Ijọba ati ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Osun tako ara wọn lori ọrọ aabo fun ibo naa

Ninu atẹjade kan lọjọ Iṣẹgun, alukoro ileeṣẹ ọhun, Yemisi Opalola ba awọn to padanu ẹmi wọn atawọn ti dukia wọn ba iṣẹlẹ ọhun lọ kẹdun.

Opalola ni kọmiṣọna ọlọpaa, Mohammed Abba ti fi da awọn araalu loju pe iwadii ni kikun yoo waye lori ohun to ṣokunfa rogbodiyan naa.

O ṣalaye pe Abba fi idaniloju lede pe gbogbo awọn to lọwọ ninu idarudapọ naa ni yoo foju wina ofin.

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Osun ti wọgile amọran ti ileeṣẹ ọlọpaa gba wọn lori eto idibo ti yoo waye naa.

Ninu atẹjade kan ti kọmisana fun eto iroyin, Oluomo Kolapo Alimi gbe sita ni ijọba wọgile amọran naa nitori ko ba ofin mu.

Alimi ni ileeṣẹ ọlọpaa kọ lati tẹlẹ idajọ ile ẹjọ, to si fẹ da bi pe awọn agbofinro n sisẹ papọ pẹlu awọn miiran.

"Ti ileeṣẹ ọlọpaa ba kuna lati tẹle ofin ile ẹjọ, ijọba ipinlẹ Osun ko gbe igbesẹ tako ofin ilẹ wa, fun idi eyi, igbesẹ ijọba ipinlẹ ni lati se atilẹyin ajọ eleto idibo lati ri pe eto idibo waye ni ilana to yẹ.

"A dupẹ lọwọ wọn fun amọran naa, a si fi tọwọtọwọ wọgile amọran naa.

"A rọ awọn araalu lati tu sita dibo, ki wọn si se ẹtọ wọn gẹgẹ bii araalu."

Aworan lati ibi eto idibo ijọba ibilẹ l'Osun

Oríṣun àwòrán, Others