Ajínigbé mẹ́rin pàdé ikú lọ́wọ́ ọlọ́pàá Ogun ní márosẹ̀ Eko sí Ibadan

Aworan to n ṣafihan ikọ ajinigbe kan

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ajinigbe mẹrin di ero ọrun logunjọ, oṣu Keji, ọdun 2025 yii, nigba tawọn ba ikọ naa wọya ija lori afara Long Bridge, to wa loju ọna marosẹ Eko s'Ibadan.

Alukoro ileeṣẹ naa nipinlẹ ọhun, CSP Omolola Odutola, to fi atẹjade iṣẹlẹ naa sita, ṣalaye pe yatọ si awọn to di oloogbe, awọn ajinigbe kan naa fara gba ọta ibọn, wọn si gbe ọta ibọn sa lọ.

Odutola ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ naa ni awọn kan dena de ọkọ bọọsi akero funfun ti nọmba ẹ jẹ BDG 753 YH, awakọ to wa mọto naa lo pe ni Ọgbẹni Morufu Adedeji.

Alukoro sọ pe apa kan ọna naa to da paro ni awọn ajinigbe ọhun ti kọlu mọto naa pẹlu ero to ko.

O ni wọn yọ ibọn si dẹrẹba, wọn si bẹrẹ si i gba nnkan ini awọn ero ọkọ loju ibọn.

Lasiko ti wọn n ṣọṣẹ naa lọwọ ni awọn ero ọkọ kan dọgbọn gba ibi ilẹkun ẹyin ti dẹrẹba ṣi silẹ sa lọ.

Eyi bi awọn ajinigbe ninu, wọn si fibinu bẹrẹ si i lu dẹrẹba naa titi to fi daku lọ gbari bi Alukoro Odutola ṣe sọ.

Awọn awakọ yooku lojuu popo naa ni wọn ke gbajare, to fi di pe ikọ to n gbogun ti ijinigbe ninu ọlọpaa Ogun gbọ lasiko ti wọn wa lagbegbe naa, ti wọn si dide iranlọwọ.

Awọn ajinigbe ṣina bolẹ fun ọlọpaa, awọn agbofinro naa da a pada, nigba naa ni mẹrin ninu awọn ẹruuku naa ku, ti awọn yooku si sa wọgbo lọ bi alaye ọlọpaa.

wọn ohun tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ajínigbé

Nigba to n kede awọn nnkan ti won gba lọwọ awọn ajinigbe naa, CSP Odutola ka:

*Ibọn ilewọ ibilẹ kan pẹlu ọta ibọn meji

•Ọbẹ meji

•Ẹgbẹrun lọna ogun naira

•Foonu Android kan

Ẹrọ to n ro foonu lagbara, to n lo oorun (solar power bank)

Ina USB mẹta (Awon ọlọpaa ni awon fura pe ẹru ole ni)

Oku awon ajinigbe mẹrin naa ti wa nile igbookusi to wa ninu ọgba ileewosan ijọba ipinlẹ Ogun, eyi to wa n'Ijaye, l'Abeokuta.

Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, Lanre Ogunlowo, ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa ma jinna si agbegbe naa, kawọn araalu si ri i daju pe wọn n ta ọlọpaa lolobo bi wọn ba ri ẹnikẹni to n wa itọju ọta ibọn kiri.