Wo iye ìgbà tí Portable ti kó sí wàhálà òfin

Aworan Portable

Oríṣun àwòrán, Portable/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bi ẹnu ko ṣe ki n sin lara afọkeemu ni aroye ati awuyewuye ṣe maa n fi ọpọ igba waye nipa Habeeb Okikola; Portable, to n pe ara ẹ ni Were olorin.

Laipẹ yii ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun kede olorin taka-sufee naa pe awọn n wa a fun iwa janduku ti wọn lo hu si awọn aṣoju ijọba mẹta niluu Ota, ipinlẹ Ogun.

Ṣugbọn eyi kọ ni igba akọkọ tabi ikeji ti Ọmọ Olalomi ti ko si panpẹ ọlọpaa nipa ọrọ ẹnu ati iṣesi rẹ.

O ti tori awọn awuyewuye to n waye yii padanu awọn ode ere, ṣugbọn ariwo ko tori ẹ tan lẹyin ariwo.

Eyi ni awọn igba ti Portable ti wọ gbaga aroye lọdọ ijọba.

Oṣu Keje, 2022: Portable kéde ara ẹ̀ bíi olórí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn

Iwọfa Alaba, ẹnu rẹ ni o pa ọ ni ohun to ṣẹlẹ si Portable loṣu Keje ọdun 2022.

Portable lo wo ṣunṣun to bọ si ori ayelujara to si kede pe oun ni olori ẹgbẹ okunkun'1 million boys.'

Ẹgbẹ okunkun yii ni awọn eeyan mọ bii ẹgbẹ to n da awọn eeyan laamu lawọn agbegbe kan nipinlẹ Eko.

Wọn mọ awọn ọmọ 1 Million boys bii adigunjale, apaayan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣugbọn Portable jade sori afẹfẹ ninu fidio kan, o si ni oun loun da ẹgbẹ onijagidijagan naa silẹ.

Ohun to sọ yii lo jẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa Eko ranṣẹ pe e lati waa sọ tẹnu rẹ, ṣugbọn Were olorin pada sọ pe oun ko sọ bẹẹ mọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oṣu Kẹta, 2023: Wọ́n mú Portable lẹ́yìn tó tàpá sí ìpè ọlọ́pàá

Lọjọ kẹtalelọgbọn, oṣu Kẹta ọdun 2023, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun nawọ gan Portable, lẹyin to kọ lati jọwọ ara rẹ fun wọn fun lẹyin ọjọ mẹta ti wọn fun un lati fi fa ara rẹ kalẹ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa Ogun.

Wọn ko deede pe Portable si teṣan, ẹni kan ni wọn ni olorin yii fiya jẹ nile ọti rẹ to wa l''Ota.

Ọrọ naa di ariwo to bẹẹ ti ọlọpaa gbe Were olorin ti wọn si ti i mọle.

O lo opin ọsẹ ni atimọle, wọn pada gbe e lọ si kootu, wọn si fi aaye beeli silẹ fun un.

Ṣugbọn nigba ti asiko to fun un lati yọju pada lori ẹsun naa, Portable ko yọju si awọn ọlọpaa mọ, wọn si kede nigba naa pe:

" A ti fiwe pe e, ki i ṣe ẹẹkan, ki i ṣe ẹẹmeji, bẹẹ ni ki i ṣe ẹẹmẹta, ṣugbọn o kọ lati jẹ ipe wa. Nigba to kọ lati da wa lohun, a ran awọn ọlọpaa jade lati lọọ mu un wa, ṣugbọn nigba ti wọn debẹ, niṣe lo tun n ba awọn ọlọpaa naa ja.

"Ṣugbọn lonii, a ti mu un, o wa lọdọ wa."

Bẹẹ ni awọn ọlọpaa Ogun kede nigba naa.

Oṣu Karùn-ún, 2024 – Wọ́n mú Portable nítori gbèsè mọ́tò G-Wagon

Lọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un ọdun 2024 ni orukọ Were olorin tun bẹrẹ si i ja lori ayelujara.

Eyi waye nigba ti iroyin sọ pe ọlọpaa ti mu Portable nitori gbese to jẹ lẹyin to ra ọkọ bọginni oni miliọnu mẹtadinlọgbọn ( ₦27 million) ti a mọ si G-Wagon .

Iroyin sọ pe Portable ko sanwo ọkọ naa tan, ati pe o yẹ adehun pẹlu ẹni to ta mọto naa fun un.

Fidio ṣafihan bawọn ọlọpaa ṣe n ka ẹsun si i lẹsẹ ati bo ṣe sare gba ibi geeti kan sa lọ.

Fidio mi-in tun ṣafihan ibi ti ọlọpaa ti fẹẹ mu Were olorin ṣugbọn to n ba wọn lo agidi, ki wọn too fipa gbe e lọ sidii ọkọ awọn agbofimro naa

Oṣu Keji, 2025 – Iléṣẹ́ ọlọ́pàá Ogun kéde pé àwọn ń wá Portable fún pé o bá àwọn aṣoju ìjọba jà

Loṣu Keji ọdun 2025, ileeṣẹ ọlọpaa Ogun kede pe awọn n wa Habeeb Okikiola; Portable, nitori awọn oṣiṣẹ aṣoju ọba mẹta ti wọn lo fiya jẹ nile ọti rẹ to wa l'Ota.

Ẹsun eyi lo n lọ lọwọ, to si ṣee ṣe ko ti bẹrẹ igbẹjọ ni kootu, lẹyin to pada fa ara ẹ kalẹ fun awọn ọlọpaa Eko, ti awọn iyẹn si taari ẹ si wọn l'Ogun ti wọn ti n wa a.