Èyí lohun tí a mọ̀ nípa Tọkọ-taya tó pa ara wọn l'Ekiti àti ìdí abájọ

Oríṣun àwòrán, Caleb Leramo/ Facebook.
Bi oṣupa alẹ ni iroyin iku oro ti ọlọpaa kan, ASP Caleb Leramo ati iyawo rẹ, Taiwo Leramo, ku, ṣe n tan kalẹ kaakiri agbegbe Igirigiri, Odo-Ado, niluu Ado Ekiti, ipinlẹ Ekiti lẹkun iwọ oorun Gusu Naijiria.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji ọdun 2025 yii ni awọn eeyan ṣadeede ri oku tọkọ-taya Leramo ninu ile wọn.
Iroyin sọ pe awọn tọkọ-tiyawo naa pa ara wọn ni.
Ija nla kan ni wọn lo bẹ silẹ laaarin awọn ololufẹ mejeeji laaarọ ọjọ naa, ko too ja si iku oro, ti nnkan ọmọkunrin ọkọ ko si lara oku rẹ mọ, bẹẹ ni apa ibi ti wọn ti ṣa iyawo ladaa lori wa lori obinrin naa.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn olugbe agbegbe naa ti na papa bora nitori ibẹru ti iṣẹlẹ ọun mu bawọn.
Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ .
O ni inu agbara ẹjẹ ni awọn ọlọpaa ba tọkọ-taya Leramo nigba ti wọn de ile wọn lẹyin ti olobo iṣẹlẹ ọhun ta wọn.
Alukoro sọ pe wọn yoo ṣewadii iru iku to pa ọkọ ti nnkan ọkunrin rẹ ko fi si nibẹ mọ, ati bi ada ṣe bu iyawo lori yankan-yankan.
- Ẹ má wò mí níran, ìfúnpá mi ti wọ 157, nǹkan ti yí wọ́ fún mi – Òṣèré Tíátà Hamima Abubakar pariwo síta
- Mi ò dọfẹ, bí mo ṣe móríbọ́ lọ́wọ́ àwọn agbébọn tó pa ọba méjì ní Ekiti rèé
- Àwọn jàndùkú kọlu ilé ìwòsàn l’Ekiti, wọ́n bá dúkìá jẹ́, jí òkú gbé
- Ẹ̀mí àìrí àti èkúté wo ló yọ ojú àti ahọ́n òkú ọmọ kí ilẹ̀ tó mọ́ ní Ado-Ekiti?
Alága àdúgbò náà bá BBC sọ̀rọ̀

Oloye Babalola Samuel, to jẹ alaga adugbo ti iṣẹlẹ yii ti waye, ba BBC Yoruba sọrọ.
Babalola ṣalaye pe ọkan lara awon ara adugbo naa lo sunkun waa pe oun lati waa wo awọn oku naa.
O ni ọlọpaa ni Caleb Leramo, Lanlọọdu si ni ladugbo naa.
"Nigba ti mo debẹ, iwaju ita ni mo duro si, ki n too pe igbakeji mi toun naa jẹ ọlọpaa, a si lọ si agọ ọlọpaa to wa ni agbegbe Odo-Ado lati fi iṣẹlẹ naa to wọn leti"
"Awọn ọlọpaa bii mẹrin tẹle wa pada sibi iṣẹlẹ naa".
"Ọkan lara awọn ọmọ bibi inu awọn oloogbe to jẹ okunrin lo tẹle awọn agbofinro wọnu yara lati fi ohun to ṣẹlẹ han wọn, won si ṣakiyesi pe ẹmi iyawo naa ko ti i bọ.
"Wọn gbe e lọ sile iwosan, ṣugbọn o pada ku lẹyin o reyin. "

Babalola tọ ka si i pe wọn ti ge nnkan ọmọkunrin ọkọ iyawo naa jabọ silẹ, bakan naa ni wọn ti ṣa obinrin naa ni ada lori.
O ṣapejuwe Oloogbe ASP Caleb Leramo bi eeyan jẹjẹ ladugbo.
Babalola ṣalaye pe awọn tọkọ-taya naa maa n ja lẹẹkọọkan, ṣugbọn ko sẹni to lero pe wọn le pa ara wọn bẹẹ.














