Mi ò dọfẹ, bí mo ṣe móríbọ́ lọ́wọ́ àwọn agbébọn tó pa ọba méjì ní Ekiti rèé

Oríṣun àwòrán, Awikonko
Alara ti Ara Ekiti, Oba Adebayo Fatoba tó móríbọ́ níbi ìkọlù tí wọ́n ti ṣekúpa àwọn ọba méjì kan ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní ọdún 2024 ti ṣàlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí níbi ìkọlù ọ̀hún.
Alara àti àwọn ọba méjì mìíràn - Onimojo ti Imojo Ekiti Ọba Olatunde Samuel Olushola àti Elesun ti Esun Ekiti, Oba Babatunde Ogunsakin ni wọ́n jọ ń lọ kí àwọn agbébọn tó dá wọn lọ́nà.
Àwọn Ọba méjì náà pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àwọn agbébọn náà àmọ́ Alara móríbọ́ lọ́wọ́ wọn.
Nígbà tó ń ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé fún iléeṣẹ́ ìròyìn Awikonko, Oba Fatoba ní òun kò pòórá lásìkò ìkọlù náà bí àwọn ṣe ń gbe kiri.
Ọba náà ṣàlàyé pé níbi ìpàdé ètò ààbò kan tí àwọn máa ń ṣe ni àwọn ti ń bọ̀ kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé.
Ó ní nǹkan ọdún mẹ́ta sí mẹ́rin sẹ́yìn ni àwọn lọ gba àṣẹ lọ́wọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti láti gbé ìgbìmọ̀ kan dìde tí yóò máa ran àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ lórí ètò ààbò ní ìjọba ìbílẹ̀ Ikole àti ìpínlẹ̀ Ekiti lápapọ̀.
Ó ṣàlàyé pé nígbà tí àwọn darandaran tí wọ́n ń dá ẹran bẹ̀rẹ̀ sí ní hu àwọn ìwà kò tọ́ ni àwọn gbé ìgbìmọ̀ náà dìde kí àláfíà lè jọba ní agbègbè àwọn.
Ó fi kun pé òun ni wọ́n fi jẹ alága ìgbìmọ̀ náà, tí Onimojo tí àwọn agbébọn náà pa sì jẹ́ igbákejì òun, tí àwọn sì máa ń lọ káàkiri ìlú kọ̀ọ̀kan ní ìjọba ìbílẹ̀ àwọn láti ri pé ààbò tó péye wà.
Ó tẹ̀síwájú pé igbákejì òun ló pè lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù kìíní pé àwọn kan tún ti ṣọṣẹ́ láàárín ìlú Aiyebode sí ìlú Ayedun tí wọ́n sì pa ènìyàn kan níbẹ̀.
"Èyí ló jẹ́ kí èmi náà sọ fún pé mò ń bọ̀ wá sí ibẹ̀ lọ́jọ́ Ajé láti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀."
"Láti ibẹ̀ ni a ti ń bọ̀, mò ń tẹ fóònù mi lọ́wọ́ ni mò ṣàdédé ri tí awakọ̀ mi tẹ ìjánu ọkọ̀ lójijì."
"Bí mo ṣe gbójú sókè ni mo ri tí àwọn agbébọn mẹ́ta tí wọ́n na onírúurú ohun ìjà sí wa, ìbọn, àdá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
"Ìbọn tí wọ́n ń yìn kò bàmí, àmọ́ gbogbo apá ojú ọgbẹ́ ṣì wà lára mi àti pé ilẹ̀kùn ọkọ̀ ni mo fi ti ẹni tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ mi dànù."

Oríṣun àwòrán, Awikonko
Ọba Fatoba tẹ̀síwájú pé lòdì sí ìròyìn tí àwọn kan ń gbé kiri pé òun àti awakọ̀ òun dọfẹ kúrò níbi ìkọlù náà, ó ní ẹsẹ̀ ni òun fi sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn agbébọn náà.
Ó ní bí òun ṣe ń lọ ni òun ń gbọ́ ìró ìbọn lẹ́yìn òun tí òun sì sáré lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́dẹ tó wà nítòsí ibẹ̀.
Bákan náà ló ṣàlàyé pé nígbà tí awakọ̀ òun ti paná ọkọ̀ ni àwọn agbébọn náà kò dá si mọ́ nítorí òun kọ́ ni wọ́n wá wá àti pé èyí ló jẹ́ kí awakọ̀ òun náà le sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀.
"Nígbà tí mo dé ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́dẹ, mo ní kí wọ́n yìnbọn sókè láti fi dẹ́rùba àwọn agbébọn náà àmọ́ ìbọn wọn kò dáhùn.
"Àwọn ọlọ́dẹ kò lè sún mọ́ àwọn agbébọn náà nítorí ìbẹ̀rù àti pé ta ló lè dúró níwájú ìbọn."
Kábíèsí náà fi kun pé òun kò lè sọ pé báyìí ni wọ́n ṣe pa àwọn akẹgbẹ́ òun nítorí ìbẹ̀rù kò jẹ́ kí òun lè mọ ohunkóhun.
Ó tún ṣàlàyé pé ẹnì kan nínú àwọn ọlọ́dẹ náà ló pe ọba tó wà nítòsí ibẹ̀ nítorí òun ti pàdánù fóònù òun, tí wọ́n sì pe àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò.
Ẹ̀wẹ̀, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ekiti ni àwọn ti nawọ́ gán àwọn afurasí kan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.















