Ìwọ́de bẹ́ sílẹ̀ ní Minna nítorí ọ̀wọ́ngógó tó gbòde ní Nàìjíríà

Awọn oluwọde naa

Oríṣun àwòrán, Nurudeen Daza

Awọn olugbe ilu Minna to jẹ olu ilu ipinlẹ Niger ti fọn si igboro lati fi ẹhonu han lori ọwọngogo ohun jijẹ ati lilo lorilẹede Naijiria bayii.

Awọn oluwọde naa di gbogbo opopona to ṣe pataki ni ilu naa lasiko ifẹhonu han ọhun.

Awọn oluwọde naa

Oríṣun àwòrán, Nurudeen Daza

Awọn obinrin ati ọdọ pọ lara awọn oluwọde naa ti wọn si n kọ orin ẹhonu lọlọkan o jọkan lori bi nnkan ṣe gbe owo lori ni Naijiria.

Lara awọn oluwọde naa to ba BBC News sọr ṣalaye pebi ọwọngogo ṣe jọba lori eto ọrọ aje ni Naijiria ti ko si da bi ẹni pe ijọba apapọ orilẹede Naijiria n ṣe ohun to to loju awọn lati wagbo dẹkun si i.

Awọn oluwọde naa

Oríṣun àwòrán, Nurudeen Daza

Igbakeji gomina ipinlẹ Niger, Yakubu Garba to ba awọn oluwọde naa sọrọ ṣalaye pe ijọba ko ṣai ri bi nnkan ṣe le koko fun araalu bayii.

O ni bẹẹ si ni ijọba lẹkajẹka gbogbo n ṣiṣẹ lati din irora ọgbẹ ọrọ aje to dagun naa lori araalu paapaa lẹyin ti yiyọ owo iranwọ ori epo tun mu ki inira ba araalu sii.

Awọn oluwọde naa

Oríṣun àwòrán, Nurudeen Daza