America padà láwọn ṣetán láti tà bàlúù ọmọogun fún Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, NAF
Ijọba orileede America ti gba lati ta awọn nkan ija ologun fun Naijiria ki wọn baa le fi koju awọn janduku agbebọn ati ikọ Boko Haram.
Ọdun 2022 ni wọn bẹrẹ idunadura lori nkan ija ologun yi ṣugbọn idiwọ wa lati ọdọ awọn ọmọ ile aṣofin America kan to ni o yẹ ki Naijiria kaju oṣunwọn kọọkan ti wọn la kalẹ ki eyi to le waye.
Boti lẹ jẹ wi pe Naijiria ti gbe iṣẹ agbaṣe rira nkan ija ologun mii sita ṣaaju asiko yi, eleyi ni o pọ julọ ninu akọsilẹ idowopọ Naijiria ati America lori ọrọ nkan ija ologun.
Iye nkan ija ologun ti wọn fẹ ta fun Naijiria lasiko yi la gbọ pe o jẹ biliọnu dọla kan.
Ninu awọn nkan ija ologun yi la ti ri awọn baalu abasibiowu taa mọ si ẹlikọpta AH-1Z mejila ati awọn ẹrọ kọmputa mejilelegbọn lati ọdọ Northrop Grumman.
Atẹjade to fidi ọrọ yi mulẹ ṣalaye pe igbesẹ yi jẹ ọna kan gbogi lati tunbọ fagbara fun Naijiria nipa kikoju awọn ipenija aabo.
Ipenija aabo Naijiria taa n wi yi ti sọ aimọye miliọnu eeyan di alainilelori ti o si tunmọ si pe rira awọn ẹlikọpta yi ni oṣu Kẹfa ọdun 2024 yoo ko ipa ribiribi ba agbega irinṣẹ nkan ija ogun Naijiria.
Ki lawọn onimọ sọ nipa baalu ologun yii?
Ọgagun Sadiq Garba to ti fẹyinti nidi iṣẹ ologun ni Naijiria jẹ eeyan kan to ti n fọkan tẹle idunadura nkan ija ologun yi lati ọdun 2022.
O ni ''baalu abasibiowu yi lawọn ologun ti n lo lati igba ogun Vietnam.Wọn maa n gbe tẹle awọn ọmọ ogun oriilẹ ti a si maa ṣaaju la ọna ki awọn ọmọ ogun oriilẹ to bẹrẹ iṣẹ.''
O tẹsiwaju pe baalu yi lagbara ''lati gbe ibọn ẹlẹnu mẹta to le yin ọta de kilomita meji ti a si maa ko ọta ibọn 750 si ikapa rẹ lẹẹkan ṣoṣo.O tun le gbe awọn ado oloro bẹẹ si ni wn le fi ṣiṣẹ lalẹ''
O fikun pe awọn baalu yi a tun maa gbe ẹrọ kọmputa kan sara ti yoo jẹ ki wọn le da aabo bo awọn araalu.
Eyi ṣe pataki lati dena awọn iṣẹlẹ to waye sẹyin nibi ti wọn ti ṣeṣi pa awọn araalu pẹlu nkan ija ologun.
Ọgagun Sadiq sọ pe latẹhinwa America n ṣọra lati ta nkan ija oloro fun Naijiria tori pe wọn a maa fi irufẹ rẹ ṣeku pa awọn araalu.
O ni bayii America yoo ṣe idanilẹ fun awọn ti yoo ba wa baalu yi
''Ẹrọ kọmputa inu baalu yi yoo jẹ ki awakọ baalu ri nkan to fẹ yinbọn lu. Yoo le sọ fun boya awọn araalu tabi awọn janduku lo fẹ yinbọn lu.Ireti wa wi pe taa ba ni iru nkan ija ologun yi, ko ni si iru aṣiṣe to waye ti awọn araalu n farakasa lọwọ ikọ ologun''














