Iléeṣẹ́ ológun ti mú sọ́jà tó sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Sanwo-Olu torí ọmogun tó gba 'one way' l'Eko

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X
Olori ọmogun oriilẹ ni Naijiria, Ọgagun Taoreed Lagbaja ti sọ pe ọwọ ti tẹ ọkan lara awọn sọja to sọ oko ọrọ si Gomina Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko nitori pe o fọwọ ofin mu akẹgbẹ wọn to gba "one way" niluu Eko.
Laipẹ yii ni fidio kan lu ori ayelujara pa ninu eyi ti Sanwo-Olu ti pàṣẹ fawọn agbofinro to kọwọọ rin pẹlu rẹ wi pe ki wọn mu sọja kan at'awọn mẹta mii ti wọn gun ọkada gba 'one way.'
Bi gomina ipinlẹ Eko ti n sọrọ ninu fidio ọhun ni soja naa fesi pe sọja loun.
Lẹyin naa ni gomina sọ pe nitori pe o jẹ sọja to si n ru ofin irinna gan an ni yoo fi dero atimọle.
Lẹyin ti fidio yii lu ori ayelujara pa l'awọn eeyan kan to wọ asọ sọja bẹrẹ si ni bu Sanwo-Olu ninu awọn fidio kan ti wọn gbe si ori ayelujara.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ọkan ninu awọn sọja pe Sanwo-Olu ni oriṣiriṣi orukọ, bẹẹ ni o tun sọ pe Sanwo-Olu gan an fun ra rẹ maa n gba 'one way.'
Ọkunrin to wọ aṣọ sọja naa ni soja ti Sanwo-Olu mu ti gba ọta ibọn si ara, wi pe apa ọta naa si wa lara rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Amọ, Ogagun Lagbaja ti sọ pe sọja to gba "one way" yii ru ofin, ati pe ki i ṣe aṣoju rere ileeṣẹ ologun oriilẹ Naijiria.
O fikun ọrọ rẹ pe ọpọ eeyan to bu Sanwo-Olu ti wọn wọ aṣọ sọja ki i ṣe sọja ni wọn.
Ọgagun Lagbaja sọ pe ọwọ ofin ti mu eyi to jẹ sọja ninu wọn.
"Ohun ti sọja to gba 'one way' ṣe lodi si ohun ti ileeṣẹ ologun duro fun eyi ti i ṣe ikoraẹni nijanu, ati ibọwọ fun ofin Naijiria ati ti ipinlẹ Eko.
A koro oju si iru ihuwasi yii ni ileeṣẹ ologun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ileeṣẹ ologun ti ṣe iwadii, a si ti rii pe ẹnikan pere ni sọja ninu gbogbo awọn to n bọọku ẹnu gomina ipinlẹ Eko.
Nipa iwọ aṣọ wọn gan an ni ẹ o fi mọ pe wọn ko si lara ọmogun Naijiria.
Bakan naa, ti ẹ ba gbọ ọrọ ẹnu wọn, ọrọ òṣèlú ni wọn n sọ kii ṣe ọrọ ileeṣẹ ologun.
Ohun ti ileeṣẹ ologun oriilẹ wa fun ni lati rii pe ofin f'ẹsẹ mulẹ," Ogagun Lagbaja ṣalaye.