Facebook at 20: Wo ọ̀nà mẹ́rin tí Facebook gbà mú àyípadà bá ayé

Mark Zuckerberg nígbà tó ń ṣe ìfilọ́lẹ̀ Facebook

Oríṣun àwòrán, Niall Kennedy

Tí ẹ bá wo àwòrán tó wà lókè yìí, bí Facebook tàbí The Facebook bí wọ́n ṣe ń pè é nígbà náà ṣe rí rèé nígbà tí Mark Zuckerberg àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe fi lọ́lẹ̀ ní ogún ọdún sẹ́yìn.

Láti ìgbà náà ni àyípadà ọ̀tun ti ń bá ààyè ayélujára yìí, tó gbajúmọ̀ jùlọ ní àgbáyé, ti ń gbòòrò si.

Àmọ́ ìdí tí wọ́n ṣe gbe Facebook kalẹ̀ kò yípadà: láti so àwọn èèyàn pọ̀ káàkiri àgbáyé àti láti pa owó látara ìpolówó ọjà.

Bí Facebook ṣe pé ogún ọdún lónìí, àwọn ọ̀nà mẹ́rin tí Facebook ti gbà mú àyípadà bá ayé nìyí.

1. Facebook mú àyípadà bá ṣíṣe àmúlò ayélujára

Àwọn ààyè ayélujára bí i MySpace ti wà ṣaájú ìdásílẹ̀ Facebook àmọ́ Mark Zuckerberg gba ìgboro mọ́ ọn lọ́wọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ lọ́dún 2004. Èyí ṣàfihàn bí ààyè ayélujára ṣe le yára tàn kó sì dàgbà.

MySpace Tom

Oríṣun àwòrán, MySpace

Àkọlé àwòrán, Tom ni ọ̀rọ́ àkọ́kọ́ gbogbo èèyan lórí MySpace, èyí tí Tom Anderson dá sílẹ̀ ṣáájú ọdún kan tí wọ́n dá Facebook sílẹ̀

Kí ọdún kan tó pé, Facebook ti ní èèyàn mílíọ̀nù kan tó ń ṣàmúlò rẹ̀, nígbà tó sì fi máa tó ọdún mẹ́rin, ó ti ní àwọn èèyàn tó ń ṣàmúlò rẹ̀ tó ju ti MySpace lọ - èyí wáyé látara àwọn ohun èlò ọ̀tun tí Facebook ń ṣàmúlò.

Lára àwọn ohun ọ̀tun bẹ́ẹ̀ ni bí èèyàn ṣe lè táàgì ẹlòmíràn sí àwòrán rẹ̀ – ohun tí àwọn àwọn ọ̀dọ́ ayé ìgbà náà fẹ́ràn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bákan náà ni bí àyípadà ṣe ń bá bí wọ́n ṣe ǹ ṣàmúlò rẹ̀ jẹ́ ohun tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn.

Nígbà tó fi máa di ọdún 2012, Facebook ti ní bílíọ̀nù kan èèyàn tó ń ṣe àmúlò rẹ̀ ní oṣooṣù, láti ìgbà náà sì ni àwọn èèyàn tó ń ṣàmúlò rẹ̀ ti ń lékún.

Ọdún 2021 ni àwọn èèyàn tó ń ṣàmúlò Facebook dínkù fún ìgbà àkọ́kọ́ sí bílíọ̀nù méjì dín díẹ̀.

Bí Facebook ṣe ń gbòòrò si wọ àwọn orílẹ̀ èdè tí ayélujára wọn kò ì tíì gbèrú, láti ri dájú pé àwọn tọ ń ṣàmúlò rẹ̀ ń pọ̀ si. Nígbà tó fi máa di ìparí ọdún 2023, Facebook kéde pé àwọn èèyàn tó ń ṣàmúlò rẹ̀ ti lé ní bílíọ̀nù méjì èèyàn káàkiri àgbáyé.

Lóòótọ́, Facebook kò fi bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ mọ́ bíi ti ayé ìgbà kan, síbẹ̀ ó wà lára àwọn ààyè ayélujára tó gbajúmọ̀ ní àgbáyé, tó sì mú ìgbà ọ̀tun bá ṣíṣe àmúl]o ayélujára.

Àwọn kan rí Facebook àtàwọn ààyè ayélujára míì jẹ́ ohun èlò tí àwọn èèyàn ń lò gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ìkànsíra ẹni, àwọn míì ri gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ìdàlúrú.

2. Facebook jẹ́ kí àwọn ohun ìní wa jẹ́ ìmọrírì

Facebook ti ṣàfihàn pé ṣíṣe àkójọ àwọn nǹkan tí a fẹ́ràn àti àwọn tí a kò fẹ́ràn jẹ́ ohun tó dára gidi tó sì lè máa pawó wọlé.

likes and other reactions

Oríṣun àwòrán, Facebook

Lóde òní, iléeṣẹ́ tó ni Facebook, Meta jẹ́ iléeṣẹ́ tó ń rí sí ìpolówó ọjá, gẹ́gẹ́ bí Google, ń rí owó gọbọi látara ìpolówó ọjà.

Ìròyìn ní Meta pa owó tó tó bílíọ̀nù mẹ́rinlélọ́gbọ̀n dọ́là ní oṣù mẹ́ta tó kẹ́yìn nínú ọdún 2023 nípa ṣíṣe ìpolówó ọjà.

Bẹ́ẹ̀ náà ni Facebook tún ti fi hàn pé àwọn èèyàn lè mú dátà èèyàn láì gba àṣẹ lọ́wọ́ ẹni tí ó ni ín.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn èèyàn ti pe Meta lẹ́jọ́ lórí bí kò ṣe sí ààbò tó péye fún dátà èèyàn lọrí ìkànnì náà.

Ní ọdún 2014 ni wọ́n san owó ìtanràn $725m fún Cambridge Analytical látara pé dátà wọn lu síta fún àwọn èèyàn látorí Facebook.

Ní ọdún 2022 ni wọ́n tún san owó €265m fún EU látàrí bí àwọn kan ṣe rí dátà kan mú tí kò yẹ kó lu síta lórí ìkànnì náà.

3. Facebook sọ orí ayélujára di ààyè ìpolongo òṣèlú

Pẹ̀lú bí ìpolówó ọjà àti ìpolongo ṣe jẹ́ ohun tí Facebook ń ṣe, káàkiri àgbáyé ni wọ́n ti ń lò ó láti fi polongo òṣèlú.

Trump lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, Reuters

Bí àpẹẹrẹ, Iléeṣẹ́ ìwádìí Statista fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé láàárín oṣù márùn-ún sí àsìkò tí ètò ìdìbò sípò ààrẹ Amẹ́ríkà fi wáyé ní ọdún 2020, Donald Trump ná owó tó lé ní ogójì mílíọ̀nù dọ́là fún ìpolongo lórí Facebook.facebook tún lágbára láti mú àyípadà bá ètò òṣèlú ní ẹsẹ̀ kùkú ní bí ó ṣe lè fi ààyè gba ikọ̀ àwọn èèyàn láti kóra wọn jọ, ṣe ìpolongo lórí ayélujára.

Facebook àti Twitter ni ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n lọ́wọ́ nínú àwọn ènìyàn ṣe fẹ̀hónúhàn lórí Arab Spring, tí wọ́n sì ń polongo bí nǹkan ṣe ń lọ lásìkò náà.

Àmọ́ lílo Facebook fún ìpolongo òṣèlú yìí ni àwọn kan ti bu ẹnu àtẹ́ lù pé ó máa ń lẹ́yìn lójú ayé pàápàá lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.

Ní ọdún 2028, Facebook faramọ́ ìjábọ̀ àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé kan níbi tí wọ́n ti fẹ̀sùn kan Facebook pé kò lágbára láti ṣèdádúró àwọn èèyàn láti bẹ̀rẹ̀ ìwà ipá lójú ayé sí àwọn èèyàn Rohingya ní Myanmar.

4. Facebook ló bẹ̀rẹ̀ bí Meta ṣe gba gbogbo àwọn ayélujára mìíràn

Mark Zuckerberg ṣe ìdásílẹ̀ ààyè ayélujára àti ìmọ̀ ẹ̀rọ tó lágbára, tí kò sí irú rẹ̀ nípa iye àwọn èèyàn tó ń lò ó àti agbára tó ní.

Mark Zuckerberg

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ààyè ayélujára tó dìde lẹ́yìn Facebook bíi Instagram, WhatsApp àti Oculus ni wọ́n rà tí wọ́n sì kó sábẹ́ iléeṣẹ́ tó ni Facebook, èyí tó pa orúkọ rẹ̀ dà sí Meta lọ́dún 2021.

Meta ní kò dín ní bílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn tó ń lo àwọn ohun èlò rẹ̀ lójúmọ́ káàkiri àgbáyé.

Nígbà tí Meta kò bá sì rí àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣe irú nǹkan tó ń ṣe rà, àwọn èeèyàn ní ó máa ń ṣe irú nǹkan tí àwọn iléeṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ń ṣe láti ri pé ó wà lókè téńté.

Ní ọdún 2022, Meta ta iléeṣẹ́ rẹ̀ Giphy – èyí tó máa ń pèsè àwọn àwòrán GIF ní iye tí kò pójú owó lẹ́yìn tí orílẹ̀ èdè UK kọ̀ láti jẹ́ kó ni iléeṣẹ́ náà pé kó má gba gbogbo ààyè ayélujára.

Ogún ọdún tó ń bọ̀?

Bí Facebook ṣe bẹ̀rẹ̀, tó sì ń tẹ̀síwájú títí di òní jẹ́ àfihàn ipa Mark Zuckerberg láti ri pé iléeṣẹ́ náà kò relẹ̀.

Àmọ́ ó ṣeéṣe kí ó ní ìpèníjà iléeṣẹ́ ayélujára ẹyọ̀kan tí yóò gba gbogbo ayé nígbà tó bá máa fi tó ogún ọdún sí àsìkò yìí.

Meta ti ń gbèrò láti gbé ọjà rẹ̀ lé Metaverse látàrí bí ìmọ̀ ẹ̀rọ ṣe ń tẹ̀síwájú pàápàá pẹ̀lú Apple.

Ìmọ̀ ẹ̀rọ AI náà jẹ́ ohun pàtàkì fún Mẹ́ta.

Fún ìdí èyí, bí iléeṣẹ́ Meta ṣe ń tẹ̀síwájú kúrò ní Facebook, àwọn èèyàn ń wòye láti mọ ohun tí iléeṣẹ́ náà ní fún ọjọ́ iwájú.

Iman Mohammed náà fi kún iṣẹ́ yìí

Àwòrán: Niall Kennedy