Ìdí tí mo fi parọ́ pé àwọn ajínigbé jí mi gbé - Òṣìṣẹ́ Báǹkì ṣàlàyé l'Ogun

Àkọlé fídíò, Ìdí tí mo fi parọ́ pé àwọn ajínigbé jí mi gbé - Òṣìṣẹ́ Báǹkì ṣàlàyé l'Ogun
Ìdí tí mo fi parọ́ pé àwọn ajínigbé jí mi gbé - Òṣìṣẹ́ Báǹkì ṣàlàyé l'Ogun
Aworan Olumide

Ọrọ ijinigbe jẹ ọkan lara ipenija abo eyi to ti di gbọnmọgbọnmọ lorilẹede Naijiria lasiko yii. Amọṣa ohun to ya ọpọ lẹnu ninu ọrọ Ọgbẹni Ọpẹnaike Francis Olumide lati ipinlẹ Ogun ni bi eeyan ṣe n ji ara rẹ gbe to si tun n beere owo itusilẹ lọwọ awọn mọlẹbi pẹlu.

O ṣe ẹyin naa ni kayeefi!

Akọṣẹmọṣẹ ni ileeṣẹ ifowopamọ si kan ni Ọgbẹni Ọpẹnaike Francis Olumide ti o si n ṣe daradara ki gbese to de baa.

Ọgbun gbese to ko si yii lo mu ki o pinnu lati ji ara rẹ gbe beere owo gẹgẹbi ọna lati san gbese ọrun rẹ.

Ọgbẹni Olumide sa kuro nile lọjọ ọjọkan lo ba daa bi ọgbọn pe ọwọ awọn ajinigbe loun ko si.

“Iṣẹ kan ti mo gba, nitori pe mo kọ iṣẹ ọwọ nigba ti mo wa ni fasiti; iṣẹ kan ti mo gba ni mo ti jẹ gbese bii miliọnu mẹrin naira ni bi ọdun meji sẹyin. Lati igba yẹn ni mo ti n fi ori rọ.”

O ni iṣoro airi awọn gbese yii san lo mu ki oun pinnu lati lọ ṣe iṣẹ laabi naa.