Bí o ṣe lè máa ka ìròyìn BBC Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin ayọ!
Ni bayii, ẹ le ri iroyin yajoyajo, iroyin lori nnkan to n lọ ni Naijiria ati awujọ agbaye atawọn iroyin mii ti BBC Yoruba n gbe e jade, ka lori Whatsapp yin.
Eyi ko yọ awọn fidio to joju ni gbese silẹ - gbogbo rẹ lẹ o maa ri lori ikanni WhatsApp wa.
Ikanni WhatsApp Channel ti BBC Yoruba ṣe ifilọlẹ rẹ lọdun 2025 maa n fawọn eeyan lanfaani lati ka iroyin atigbadegba ti wọn ba nifẹ si.
Ọdun 2023 ni BBC bẹrẹ lori Whatsapp, o si ti ni eeyan to ju miliọnu mẹẹdogun lọ bayii ni bii orilẹede to le ni igba.
Wo bi o ti le ka iroyin BBC Yoruba lori aapu WhatsApp rẹ

Oríṣun àwòrán, PA Media
- Ni akọkọ, ẹ lọ sori aapu WhatsApp to wa lori foonu tabi lori kọmputa yin
- Ti o ba jẹ wi pe ẹrọ kọmputa ni ẹ n lo, ẹ tẹ koodi QR, lọwọ kan ni yoo gbe yin lọ sori aapu WhatsApp wa.
- Lori foonu, ẹ ṣi aapu Whatsapp yin.
- Lẹyin naa, ẹ tẹ bọtinni 'Updates'.
- Tẹ ẹ ba ti de 'Updates', nibẹ ni 'Status' ati 'Channels' wa
- Ẹ tẹ 'Channels'
- Nibẹ si ni ki ẹ ti wa BBC News Yorùbá lati darapọ mọ wa.
- Ti ẹ ba ti wọle si inu 'Whatsapp Channel' wa, ẹ tẹ bọtinni 'Follow' to wa ni oke foonu rẹ.
- Ẹ o tun ri aago kekere kan ni apa ọtun loke foonu yin. Ẹ tẹ aago naa ki ẹ le maa mọ ni oju-ẹsẹ ti iroyin tuntun ba jade sori 'Channel' BBC News Yoruba.
Ẹ le lo awọn ami aworan lati sọrọ lori awọn iroyin wa, bakan naa ni ẹ tun le pin awọn iroyin yii pẹlu awọn ọrẹ yii lori awọn awujọ ori WhatsApp ti ẹ ba wa.
Ileeṣẹ Meta to ni Facebook, Instagram ati WhatsApp ti sọ pe ẹnikẹni ko le mọ nnkankan pẹlu orukọ yii, fọto tabi nọmba foonu yii.
Ẹ si le ka si nipa awọn ofin to daabo bo awọn nnkan ti ẹ ko fẹ kawọn eeyan mọ lori ikanni WhatsApp.












