Wo bí o ṣe lè dá ayédèrú òògùn mọ̀ lórí igbá

Oríṣun àwòrán, NAFDAC/X
Laipẹ yii nia jọ NAFDAC to n ṣamojuto ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria gbe ile itaja oogun to le ni 11,000 pa, nitori pe wọn n ta ayederu oogun tipa to fi mọ awọn ibi ti wọn ko irufẹ oogun naa pamọ si.
Ajọ NAFDAC ni awọn ti gbẹsẹ le tirela mẹwaa ayederu oogun laarin ọsẹ meji pere lọja Idumota l"Eko lati igba ti awon ti bẹrẹ si ni wa ibi ti wọn ti n ta oogun ayederu kaakiri Naijiria.
NAFDAC tun gbẹsẹ le tirela meji oogun ayederu ni ọja ti wọn ti n ta oogun ni Onitsha nipinlẹ Anambra.
Ajọ naa tun ṣawari oniruuru ayederu oogun to fi mọ oogun iṣẹyun lọja Ariaria niluu Aba nipinlẹ Abia.
Eyi n ṣapejuwe bi ayederu oogun ṣe pọ kaakiri orilẹede Naijiria ti awọn eeyan to le ni igba miliọnu wa ninu rẹ.
Ẹwẹ, NAFDAC ti kede bi awọn eeyan ṣe le mọ oogun ayederu.
Wọnyii si ni bi o ṣe le mọ ayederu oogun gẹgẹ bi NAFDAC ti ṣalaye:
Ile ita oogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ NAFDAC ti rọ awọn eeyan pe ki wọn ṣọra pẹlu ibi ti wọn ti n ra oogun.
Ajọ naa rọ awọn eeyan lati maa ra oogun nile ita oogun to forukọ silẹ pẹlu NAFDAC nikan.
NAFDAC ni awọn ṣọọbu ti ko forukọ silẹ pẹlu NAFDAC lo maa n saba ta ayederu oogun yii.
Iye ti wọn n ta oogun
Awọn ibi ti wọn ti n ta oogun ni ẹdinwo le jẹ ibi ti wọn ti n ta ayederu oogun.
Ajọ naa ṣalaye pe iru awọn ibi ita oogun bayii maa n ra oogun ni ẹdinwo lọwọ awọn to n ta ayederu oogun, ẹdinwo yii lo si maa n jẹ ki ọpọ eeyan lọ síbẹ lati ra oogun.
Idi miran ti iru awọn ṣọọbu yii fi n ta oogun ni ẹdinwo ni pe wọn kii sanwo ori.
Paali oogun
NAFDAC tun rọ araalu lati maa kiyesi paali oogun ti wọn ba fẹ ra.
Ajọ naa ni lọpọ igba ayederu oogun lo maa n wa ninu paali oogun ti ko ba dun-un wo loju.
Bakan naa ni ajọ NAFDAC tun sọ pe bi wọn ṣe kọ orukọ sara paali naa maa n ṣafihan bo ya oogun ayederu lo wa ninu paali iru oogun bẹẹ.
Lọpọ igba ni aṣiṣe maa n wa ninu bi wọn ṣe kọ orukọ oogun sara paali.
Oorun oogun
Awọn araalu ni lati ṣọra pẹlu awọn oogun to ba n run bi igbo tabi ọda.
Ajọ NAFDAC ni oogun ti ko ba ti run bi oogun ṣe maa n run le jẹ ayederu oogun.
Ipa ti lilo ayederu oogun le ni ninu agọ ara rẹ
Ajọ eleto ilera lagbaaye, WHO, sọ pe ayederu oogun lewu fun ilera agọ ara eeyan.
Ajọ WHO ni lilo ayederu oogun le fa arun fun eeyan, koda, o le ṣeku pa eeyan.
Ajọ naa ni ko din ni ọmọde 280 to n ku lọdọọdun latari lilo ayederu oogun otutu aya ati aisan iba l'awọn orilẹede kan l'Afirika.
Awọn nnkan mii ti ayederu oogun le fa ni arun to le ma gboogun, o tun le fa iku, o si tun le jẹ ki eeyan padanu owo.















