'Mo má n tọrọ oúnjẹ láti bọ́ àwọn ọmọ mi kí kẹ̀ẹ̀kẹ́ Marwa tó gbọ̀nyà nù lára mi'

Àkọlé fídíò,
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹgbẹ awọn obinrin to n wa kẹkẹ Marwa nipinlẹ Ondo, paapaa niluu Akure, ti sọ nnkan to gbe wọn de idi iṣẹ naa, ati awọn ipenija ti wọn n dojukọ.

Ọkan lara wọn, Arabinrin Oluwayemisi Oki, sọ pe ọpọ eeyan lo bu oun pe, iya to n jẹ oun lo mu ki oun di ẹni to n wa Marwa. O ni awọn miran ti ẹ ma n wo oun bii ẹni pe, igbọnsẹ ni oun gbe dani.

"Wọn fi aye su mi. Orisirisi ọrọ kobakungbe ati ifiyajẹni ni mo dojukọ lọdọ awọn akẹẹgbẹ mi l'ọkunrin.

O ni nnkan to dun mọ oun ninu ni pe loot ni oun jiya pupọ gẹgẹ bi obinrin to kọkọ wa kẹkẹ Marwa niluu Akurẹ, ọpọ obinrin naa ti n ṣe iṣẹ naa bayii.

Olanrewaju Kemi

Ẹlomiran to tun ba BBC sọrọ, Arabinrin Omodogbe Olufunke sọ pe ọja ni oun n ta tẹlẹ, amọ bi oun ṣe ma n ri awọn obinrin to n wa kẹẹkẹ kọja, lo mu ko wu oun naa.

"Iṣẹ naa ni mo fi n bọ awọn ọmọ mi lati ọdun 2019 ti baba wọn ti ku."

Ẹlomiran, Olanrewaju Kemi, ti oun naa jẹ opo sọ pe, ṣaaju ko to o bẹrẹ si ni wa kẹẹkẹ, oun ma n tọrọ ounjẹ lati fi bọ awọn ọmọ ni.

Awọn obinrin naa sọ pe awokọṣe ni ẹgbẹ awọn jẹ fun ọpọ obinrin to ba ni ipenija ọrọ-aje, lati ma ṣe nnkan ti ko tọ ọ fi wa owo.

Ẹgbẹ awọn obinrin to n wa kẹẹkẹ