Àwọn obìnrìn Kenya ní àwọn kò bímọ mọ́, níṣe ni wọ́n ń so ilé ọmọ wọn pa - Ìdí rèé

Aworan Nelly Naisula Sironka to so ile ọmọ rẹ pa.

Oríṣun àwòrán, Nelly Naisula Sironka

Àkọlé àwòrán, Aworan Nelly Naisula Sironka to so ile ọmọ rẹ pa.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ni ilẹ Adulawọ, ẹbun pataki lọmọ bibi, to bẹẹ ti awọn eeeyan ma n wo obinrin ti ko ba bimọ, pe ko ti i pe laaarin ẹgbẹ rẹ.

Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe orilẹede Kenya to jẹ ilẹ eeyan dudu ti n fi oju mii wo ero yii.

Idi ni pe awọn obinrin Kenya ti n kọyin si ọmọ bibi bayii, wọn n so ile ọmọ wọn pa ki wọn ma baa loyun.

Ọkan ninu awọn obinrin Kenya, Nelly Naisula Sironka, sọ pe oun ko figba kankan ronu lati bimọ ri.

Loṣu Kẹwaa, ọdun 2024, obinrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), naa gbe igbesẹ kan.

Nelly ṣiṣẹ abẹ ti wọn fi so ile ọmọ rẹ pa titi lai, ti ko fi ni i le bimọ mọ laye.

" Ara mi ya gaga, o jẹ ki n wa lominira."

Nelly Naisula lo sọ bẹẹ fun BBC, o ni ọjọ iwaju oun ti wa fun oun nikan ṣoṣo.

Iṣẹ abẹ to ṣe yii maa n di oju opo ti atọ ọkunrin yoo gba wọ ile ẹyin ọmọ ninu obinrin, ti oyun yoo fi de, eyi ni wọn n pe ni siso apo ile ọmọ pa (tubal litigation).

Laaarin ọdun 2020 si 2023, o kere tan, ẹgbẹrun mẹrindinlogun (16,000) obinrin ni Ila-Oorun Africa ni wọn ṣiṣẹ abẹ yii, gẹgẹ bi ileeṣẹ eleto ilera Kenya ṣe sọ.

Ohun ti wọn ko kan sọ fun wa ni iye awọn ti ko ti i bimọ ri ki wọn to o so ile ọmọ wọn pa.

''Ọna pọ̀ tí obínrin fi lè dá sí ìlọsíwájú ayé, kí í ṣe nípa ọmọ bíbí nìkan''

Muthoni Gitau.

Oríṣun àwòrán, Muthoni Gitau.

Àkọlé àwòrán, Muthoni Gitau toun naa so ile ọmọ rẹ pa
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Yatọ si Nelly Naisula Sironka, obinrin mii to tun ni oun ki i ronu ọmọ ni Muthoni Gitau.

Lori ẹka ayelujara YouTube lo ti ṣalaye nipa iṣẹ abẹ to so ile ọmọ rẹ pa, eyi to ṣe l'oṣu Kẹta ọdun 2024, bo tilẹ jẹ pe ko ti i bimọ ri.

" Nigba ti mo wa lọmọ ọdun mẹwaa ni mo ti kọkọ ronu pe mi o ni i bimọ laye mi."

Muthoni lo sọ bẹẹ fun BBC.

" Ninu gbogbo ohun ti mo n ronu ẹ laye mi, ko si ọmọ bibi nibẹ.

"Dokita ti mo kọkọ lọọ ba pe mo fẹẹ so ile ọmọ mi pa ko ṣe e fun mi. Mo wa lẹni ọdun mẹtalelogun nigba naa.

"Niṣe lo n parọwa fun mi pe ki n ma ṣe e, o ni ẹbun pataki lọmọ jẹ lati ọdọ Ọlọrun.

"Dokita sọ fun mi pe ti mo ba pade ọkunrin to fẹ ẹ bimọ lọjọ iwaju nkọ.

Ẹni ti mi o ti i ri, ti ko daju boya mo maa ba pade lo jẹ dokita naa logun ju emi ti mo jokoo siwaju rẹ lati so ile ọmọ mi pa lọ''

O ni bi dokita naa ko ṣe ṣe oun ti oun fẹ ba oun lọkan jẹ pupọ.

Gitau ni oun gba ileewosan miran lọ lẹyin ọdun mẹwaa, wọn si ṣe iṣẹ abẹ naa fun oun.

O ni ọmọ bibi nikan kọ ni obinrin fi le da si ilọsiwaju ile aye, ọna pọ ti obinrin fi le ran aye lọwọ ju ki wọn maa bimọ lọ gẹgẹ bo ṣe sọ.

Sironka paapaa sọ pe ibi ọmọ bibi kọ laye pari si, o ni bi oun ṣe wa lati ẹbi ọlọmọ pupọ to, ọmọ bibi ki i ṣe fun oun.

''Nnkàn ti yàtọ̀, àwọn ọlọ́mọ yọyọ àtijọ́ kọ́ ló ń so ilé ọmọ wọn pa mọ́''

Tẹlẹ ri, awọn obinrin to ti bimọ pupọ ti wọn ko si fẹẹ bimọ mọ ni wọn maa n ṣiṣẹ abẹ si ile ọmọ wọn ni Kenya, gẹgẹ bi Dokita Nelly Bosire, ṣe sọ.

Dokita to kẹkọọ nipa itọju obinrin to si fi Kenya ṣebugbe naa ṣalaye fun BBC

" Tẹlẹ, awọn obinrin to ti bimọ rẹpẹtẹ ni wọn maa n ṣiṣẹ abẹ to n so ile ọmọ pa yii, ṣugbọn ni bayii, a n ri awọn obinrin ti wọn ko ti i bimọ pupọ ti wọn n so ile ọmọ wọn pa"

Awọn obinrin ti wọn ti pinnu pe awọn ko ni i bimọ mọ ni wọn maa n so apo ile ọmọ wọn pa.

Dokita Nelly Bosire naa sọ pe awọn ki i sabaa gba awọn obinrin niyanju lati so ile ọmọ wọn pa, nitori ko daju pe wọn le ri i tu pada mọ bi wọn ba fi le so o.

Dokita sọ pe gbére ni!

''Ó ṣòro láti yí ọkàn àwọn dókítà mí-ìn padà lórí ọ̀rọ̀ yìí''

Ninu ọrọ Dokita Bosire, o ni iṣoro tawọn n koju bayii ni pe o ṣoro lati yi ọkan awọn dokita kan pada ni Kenya lori igbesẹ yii.

Dokita Bosire sọ pe o yẹ kawọn dokita naa yi irori wọn pada, ki wọn si gba pe ẹni to fẹẹ yi nnkan pada lara rẹ mọ ohun to n ṣe.

O ni ẹni to fẹẹ gbe igbesẹ nipa ilera rẹ lẹtọọ lati ṣe bẹẹ.

"Aṣa ilẹ wa lo mu kawọn eeyan maa ro pe ko daa ki obinrin so ile ọmọ rẹ pa"

Dokita obinrin mi-in, Kireki Omanwa, sọ pe ọrọ naa ko ti i di itẹwọgba. O ni ariyanjiyan ṣi n lọ nipa rẹ gan-an ni.