'Ọmọ mi Tolu lọ ra nǹkan ni, àmọ́ ìròyìn ikú rẹ̀ látọ́wọ́ ọlọ́pàá ló wọlé tọ̀ mí wá'

Àkọlé fídíò, 'Ilé ni mo wà tí ọmọ mi Tolu fi lọ ra nnkan, àmọ́ ìròyìn ikú rẹ̀ látọ́wọ́ ọlọ́pàá ló wọlé tọ̀ mí wá'
'Ọmọ mi Tolu lọ ra nǹkan ni, àmọ́ ìròyìn ikú rẹ̀ látọ́wọ́ ọlọ́pàá ló wọlé tọ̀ mí wá'

Laipẹ yii ni rogbodiyan kan ṣẹlẹ niluu Ifon, nipinlẹ Ondo, ninu eyi ti awọn araalu ti dana sun agọ ọlọpaa.

Eyi waye lẹyin ti awọn araalu fi ẹsun kan pe, awọn ọlọpaa niluu naa lu ọdọmọkunrin meji pa lai nidii.

Ọkan lara awọn aṣoju ilu Ifon, Ọgbẹni Olaniyi Eni-Olotu, sọ fun BBC pe, ọkọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2024, ni awọn ọlọpaa lọ ọ fi ofin ko awọn ọdọ kan niluu naa nitori ija to waye laarin wọn.

"Nibi ti wọn ti mu wọn, ni awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ti sọ pe, wọn ti lu awọn ọdọ naa ni ilukulu.

"Ọkan lara wọn to pada di oloogbe, Tolu Bobade, lọ ọ ki ọrẹ rẹ ni lasiko to ko sọwọ ọlọpaa."

O ni gbogbo alaye ti ọmọ naa ṣe pe, oun ko mọ nkankan, ni ko wọ awọn ọlọpaa leti.

Baba Tolu, ati ọmọ rẹ to di oloogbe

Baba oloogbe Tolu, Ọgbẹni Tubọsun Bbade, ṣalaye pe, ọmọ oun jẹ ẹni ti ko le ṣe nnkan to l'agbara, nitori pe o ṣẹṣẹ bọ lọwọ aisan kan to sọ ọ di eero ileewosan fun oṣu mẹjọ.

"Ile ni mo wa nigba to (Tolu) sọ fun mi pe, oun fẹ ẹ lọ ra nnkan. Lẹyin rẹ ni mo gbọ pe wọn mu l si agọ ọlọpaa, o ni ki oun to le gbe igbesẹ kankan, ni oun tun gbọ pe ọmọ naa ti dakẹ sọwọ ọlọpaa loju ọna ileewosan.

Ọgbẹni Eni-Olotu tun ṣalaye pe, awọn ọlọpaa gbe ọmọ naa lọ si mọṣuari, lai sọ fun awọn obi rẹ.

Iroyin iku ọmọ ọdun mẹtadinlogun naa lo fa a ti awọn araalu fi ṣe iwọde, ti wọn si dana sun agọ ọlọpaa.

Bakan naa ninu ọrọ rẹ lo ti sọ pe, ni ọjọ keji, to jẹ ọjọ kẹẹdoun, oṣu Keji, ni awọn ọlọpaa tun yinbọn pa ẹnikan lara awọn ọdọ to n ṣe iwọde, Ojo Orisamolade.

Iya oloogbe, Arabinrin Bunmi Orisamolade sọ pe "niṣe ni awọn ọlọpaa ja ilẹkun yaara ọmọ mi wọle, wọn kjo ṣẹkẹ-ṣẹkẹ si lọwọ, ti wọn si bẹrẹ si ni fi awọn igi ti a fi n dana naa an.

Ọgbẹni Olaniyi Eni-Olotu, aṣoju ilu Ifon, sọ pe iwadii otitọ ti ko lọwọ ileeṣẹ ọlpaa, ati araalu ninu, ni awọn n fẹ lati mọ iru iku to pa awọn ọmọ mejeeji.

"Agọ ọlọpaa ṣe e tun kọ, amọ ẹmi awọn ọmọ mejeeji, Tolu Bobade ati Ojo Orisamolade, ko ṣe e da pada.

Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ naa?

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo sọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin pe, awọn rọ awọn araalu lati ma gbẹsan ohun to ṣẹlẹ lati ọwọ ara wọn.

Wọn ni awọn ṣi n ṣe iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.