Ǹjẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa Kayamayo tí àwọn ọkùnrin fi ń kojú Kayamata?
Ni bii ọdun melo kan ni ariwo sọ lori ayelujara nipa amulo Kayamata eyi to ni ọpọ itumọ si awọn eeyan.
Se ẹyin ti gbọ nipa Kayamata ri, ki ni itumọ rẹ si yin, ero wo si lo maa n wa sọkan yin, tẹ ba ti gbọ orukọ yii?
Ọna lati wa idahun sawọn ibeere yii lo mu ki BBC Yoruba bọ sigboro lati se ẹkunrẹrẹ iwadii nipa eroja Kayamata yii ati isẹ to n se.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa la tun wadi pe se lootọ ni Kayamata jẹ oogun abẹnu gọngọ to wa lati fa ọkunrin mọra, ti ko fi ni bọ kuro lọwọ obinrin to ba lo eroja naa fun.
Ninu iwadii wa, se la tun gbọ pe eroja miran tun wa ti wọn n pe ni Kayamayo eyi ti wọn ni awọn ọkunrin n lo bii adodun, gẹgẹ bii ọna abayọ si Kayamata .
Sugbọn ọna lati fi idi ododo mulẹ nipa Kayamata lo gbe wa de ọdọ obinrin Hausa kan to n ta eroja naa, Hajiya Muhammed, ẹni to fidi rẹ mulẹ pe ede Hausa ni Kayamata, to si sọ itumọ rẹ.
Bakan naa lo sọ bi wọn se n lo eroja naa ati pataki rẹ fun lọkọlaya.
Awọn ọkunrin ati obinrin naa tun ba BBC Yoruba sọrọ lori ero wọn nipa Kayamata, oju ti wọn fi lo amulo rẹ laarin takọ-tabo.
Ko tan sibẹ, a tun ba dokita onisegun oyinbo sọrọ, ẹni to salaye ohun ti Kayamata jẹ lede oyinbo, iwulo rẹ ati iwadii nipa rẹ.
Fidi yii, ọpọ ọgbọn ati iroyin awogbadun lo wa nibẹ, ẹ wo o.






