Wo àwọn nǹkan ìyanu mẹ́wàá táwọn èèyàn ń pín lóde ówàńbẹ̀ lásìkò yìí

Oríṣun àwòrán, X/@uzoart
Lati ayebaye ni awọn eeyan ti maa n ṣe ayẹyẹ ati ajọyọ, ọpọ eeyan maa n pe e ni 'party', ṣugbọn Owanbẹ lawọn eeyan mi-in tun maa n pe e lode iwoyi.
Nibi apeje owanbẹ, bawọn eeyan ba jẹun tan, ti wọn jo tan pẹlu gbogbo àrà ti wọn ba fẹẹ da lode ọhun, awọn to n ṣe ayẹyẹ yoo tun ha ẹbun fun wọn nigba mi-in lati mu lọ sile.
Latijọ, awọn nnkan bii ike iṣanwọ, abọ ijẹun, ikolẹ, aṣọ inuju, iwe pélebé ati ohun to jọ mọ bẹẹ ni wọn maa n pin lode ariya wọnyi, eyi ti awọn eeyan yoo maa ri lo lọ ti wọn yoo si maa fi ranti ayẹyẹ lagbaja ti wọn lọ.
Ṣugbọn lasiko yii, awọn nnkan ijọniloju ti eeyan ko tiẹ le ronu pe wọn le pin lode ti wọ ode ariya bayii, awọn mi-in si ti sọ ọ di fọrifọri, ka-ri-mi ati igberaga fun ẹlẹgbẹ wọn to ba fẹẹ ṣe pati ti ko si lagbara owo nla bii tiwọn.

Oríṣun àwòrán, Others/ Getty images
Wọ́nyí ni díẹ̀ nínú àwọn nǹkan ìyanu tí wọ́n ń pín lóde àríyá lásìkò yìí
Adiẹ ààyè: Igbeyawo kan waye laipẹ yii niluu Eko, iyalẹnu lo si jẹ nigba ti iya ọkọ bẹrẹ si i pin adiẹ ààyè fun awọn alejo to wa nijoko, ti gbogbo wọn si n fi ayọ gba a, ti wọn n fẹyin kẹẹ.
Eyi kọ ni igba akọkọ ti wọn yoo pin adiẹ ooye bẹẹ lode ariya, ni 2022, iru rẹ waye pẹlu, lasiko ti ọkunrin onitiata kan n ṣe ayẹyẹ igbeyawo.
Epo bẹntíròòlù: Asiko kan ti epo bẹntiroolu wọn gogo lọdun 2022, obinrin olowo nla kan n ṣe iwuye, nigba naa lo si bẹrẹ si i pin epo bẹntiroolu ti wọn rọ sinu kẹẹgi gẹgẹ bii ẹbun.
Ko sẹni to wa lode naa ti eyi ko jọ loju, koda, gbajumọ olorin Fuji to kọrin paapaa beere tiẹ. Bẹẹ ni wọn n kan saara si olowo obinrin naa.
Bo tilẹ jẹ pe iya olowo pada jẹjọ lori eyi, ti wọn si ti gbọngan ti ayẹyẹ naa ti waye pa labẹ ofin Eko, sibẹ, awọn aye sọ pe iyi lo fi epo to pin naa gba, nitori ẹni nla lo n ṣehun nla.
Foonu: Foonu ko ṣee binu ra, bo ti wu ko kere to, ẹgbẹrun mẹwaa soke ni awọn towo wọn kere jọjọ.
Lode iwoyi, awọn kan ti n pin foonu ni pati.
Ki i ṣe foonu olowo kekere ni wọn n pin pẹlu, awọn ibinu foonu ọlọpọ ẹgbẹrun ti wọn n pe ni iPhone ni. Ode awọn olowo gidi leyi ti wọpọ, awọn ti aṣiri wọn si n bo diẹ naa maa n dan an wo nigba mi-in, ko kan ni i jẹ foonu olowo gọbọi ni wọn yoo pin ni.
Dildo: Ohun elo ibaraẹnilopọ ti wọn ṣe bii nnkan ọkunrin leyi.
Awọn obinrin mi-in ti ko ni ololufẹ ti wọn si fẹẹ gbadun ara wọn maa n lo o lati fi ba ara wọn ṣere, wọn yoo si damira bii pe wọn ri ọkunrin.
Iyalẹnu lo jẹ pe wọn ti n pin dildo lode ariya bayii. Oṣere tiata Yorubu kan to jẹ ọmọ ilẹ Igbo lo kọkọ pin dildo nibi oku iya rẹ.
Niṣe lawọn obinrin to wa nibẹ si n du rọba naa bii pe kinni ọkunrin gan-an ni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àgbo jẹ́di: Atẹkanlẹ gbọngbọn, ọpa ẹyin, wọle kanlẹ ati awọn orukọ egbogi jẹdi bayii ti wa lara awọn nnkan ti wọn n pin pati bayii.
Pupọ agbo yii wa fun awọn ọkunrin lati le ṣe ojuṣe wọn lori ibusun pẹlu iyawo wọn.
Ko sẹni to n pin iru eyi lode ariya tẹlẹ, ṣugbọn ki i ṣe ajoji mọ bayii lawọn ode Owanbẹ wa.
Rọ́bà ìdáàbòbò: Kọndọọmu ni a mọ eyi si lede oyinbo, rọba idaabobo kuro lọwọ arun ibalopọ ni Yoruna n pe e.
Wọn ti n pin oun naa lode ariya bayii, ko si nilo ki wọn woju ki wọn too pin. Takọ-tabo to ba ti balaga ni wọn n pin in fun lode ayẹyẹ.
Ata: Ata wọn bii oju lasiko kan ni 2020, owo gọbọi leeyan yoo fi ra ata to fẹẹ din lasan, ka ma ti i sọ ti ọbẹ sise.
Asiko naa ni iya Iyabo Ojo onitiata ku ti wọn si fẹẹ ṣe oku rẹ. Toyin Abraham, Iya Ire si wa si pati naa pẹlu apo ata rẹpẹtẹ, o waa pin in fun awọn eeyan.
O ya ọpọ eeyan lẹnu pe wọn n pin ata ni pati, ṣugbọn gbogbo awọn to wa nibẹ ni wọn gba a tayọ-tayọ, latigba naa ni ata si ti di ohun ti wọn tun n ha fun awọn eeyan lode ariya.
Búrẹ́dì: Awọn nnkan adamọdi pinpin ni pati ko yọ burẹdi naa silẹ. Wọn n pin in daadaa loriṣiiriṣii.
Gaari ati ẹpa: Nigba ti ọwọngogo ọja bẹrẹ latari owo iranwọ epo ti Aarẹ Bola Tinubu yọ loṣu Kẹfa ọdun 2023, gbogbo ọja gbowo leri, atijẹ ko si dẹrun fun awọn eeyan ni Naijiria.
Sibẹ, awọn ti inawo kan ko le ma ṣe e, o si wu wọn lati fi ounjẹ ran awọn ti ko ni lọwọ. A o waa mọ ẹni to kọkọ ja ọgbọn gaari ati ẹpa ti wọn n di sinuu ọra, ti wọn yoo kọ orukọ ẹni to n ṣe ode si i, ti wọn si bẹrẹ si i pin in lode.
Latigba ọwọngogo naa ni ilana yii ti bẹrẹ, awọn mi-in yoo si tun fi ṣuga kun un pẹlu.
Iṣu: Iṣu maa n wọn lati ra lọja, paapaa lasiko to ba ti di ẹgbẹ ti tutu ko ti i jade.
Awọn ode kan wa to jẹ bi eeyan ba ni anfaani ati lọ sibẹ, iṣu yoo wa lara ohun ti wọn maa pin, eeyan yoo si ṣe bẹẹ riṣu ọfẹ se jẹ.
Ọpọ nnkan mi-in lo tun ṣi ku tawọn eeyan n pin, paapaa lawọn Owanbẹ ipinlẹ Eko ati awọn ilu nla mi-in ni Naijiria. Ode awọn eeyan nla ni nnkan nla si ti maa n waye bi eyi, nitori olowo maa n ṣe ohun gbogbo tan ni.














