Gómìnà Adeleke kìlọ̀ fún àwọn alága káńsù tuntun láti má yọjú sí ọ́fíísì báyìí

Aworan awọn alaga tuntun ni ipinlẹ Osun

Oríṣun àwòrán, Osun State Government

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun ti paṣẹ fun awọn alaga tuntun ati kansẹlọ pe ki wọn jina si ọfisi wọn ni ijọba ibilẹ ẹnikọọkan wọn bayii.

Gomina sọ eyi lasiko to n se iburawọle fun awọn alaga tuntun ti wọn jẹ ọgbọn niye ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji, ọdun 2025 ni ile ijọba to wa niluu Osogbo.

Eto naa waye lẹyin wakati diẹ ti idibo ijọba ibilẹ pari nipinlẹ ọhun.

Gomina Adeleke ni igbeṣẹ naa se koko lati ma le fi aaye silẹ fun titako ofin ilẹ Naijiria.

Bakan ni gomina tun rọ awọn alaga naa pe ki wọn ri i daju pe, gbogbo ileri ti wọn se fun araalu ni wọn musẹ lasiko ti wọn wa ni ijọba.

Nigba ti ileeṣẹ BBC kan si agbẹnusọ fun gomina nipinlẹ Osun, Olawale Rasheed, o ṣalaye idi ti Gomina Adeleke fi gbe igbesẹ, eyi to ṣapejuwe gẹgẹ bi nini ifẹ araalu.

Rasheed ni gomina ko fẹ rogbodiyan kankan mọ, eyi to tun le ṣokunfa ki awọn eeyan padanu ẹmi wọn.

"Gomina gbe igbesẹ naa nitori rogbodiyan to waye ati bi awọn kan ṣe ja wọle sinu awọn ọfisi ijọba ibilẹ.

"Eyi ni gomina fi paṣẹ fun wọn pe ki wọn ma ti i lọ si ọfisi ijọba ibilẹ.

"Idi keji ni pe awọn osisẹ ijọba n se iyansẹlodi lọwọ bayii, ti ko si ẹnikẹni ni ọfisi."

Ninu ẹgbẹ oselu mejidinlogun to kopa ninu eto idibo naa, ẹgbẹ oṣelu PDP nikan lo jawe olubori ni gbogbo ijọba ibilẹ ọgbọn gẹgẹ bii alaga ijọba Ibilẹ.

Bakan naa, ẹgbẹ oselu PDP lo tun jawe olubori nibi ibo awọn kanselọ naa.

Ti gbogbo kanselọ naa si jẹ 332.

Alaga ajọ eleto idibo, Hashim Abioye, rọ gbogbo wọn, ki wọn maa ṣe gbagbe gbogbo ileri ti wọn ṣe ni akoko ipolongo idibo wọn fun awọn ara iluu.

Ki lo sẹlẹ saaju?

Awuyewuye lori idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lori ọrọ ijọba ibilẹ ba ibomiran yọ lẹyin ti ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP meji ni ijọba ibilẹ Boripe niluu Iragbiji ku, nigba ti alaga APC kan naa dero ọrun ni ijọba ibilẹ Ayedire lọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlogun, ọdun 2025, nipinlẹ Osun.

Lọsẹ to kọja lawọn alaga ijọba Ibilẹ lati inu ẹgbẹ APC ti ile ẹjọ kotẹmilọrun da lare gba awọn ofiisi awọn ìjọba ibilẹ lọ eyi to mu kawọn ọmọ ẹgbẹ PDP tako wọn ti aawọ si bẹ silẹ kaakiri ipinlẹ Osun.

Ohun ti a ri nigba ti a ṣe abẹwo si ijọba ibilẹ Boripe niluu Iragbiji ni wi pe, ẹgbẹ oselu APC lo gba gbogbo agbegbe naa ti wọn si le awọn ẹgbẹ oselu PDP kuro ni agbegbe ijọba ibilẹ ọhun.