Àlàyé rèé lórí bí Mudasiru Obasa ṣe padà di olórí ilé aṣòfin Eko

Oríṣun àwòrán, Mudashiru Obasa/ Instagram
Lẹyin awuyewuye to ṣuyọ nipa ẹni ti yoo maa dari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko laaarin Mudashiru Obasa ti wọn yọ nipo naa ati Igbakeji rẹ tẹlẹ, Mojisola Meranda to gba ipo naa mọ ọ lọwọ, ile naa ti gbe igbesẹ tuntun.
Lọjọ Aje, ọjọ Kẹta oṣu Keji ọdun 2025 yii ni nnkan yipada, Obasa de pada sile igbimọ aṣofin Eko, awọn asọfin to yọ ọ nipo tẹlẹ si tun dibo fun un lati maa ṣe olori ile lọ.
Ọnarebu Noheem Adams to n ṣoju ẹkùn Eti-Osa lo fa Obasa kalẹ pe ki wọn dibo fun un, Ọnarebu Nureni Akinsanya lati Mushin si ṣe ikeji aba naa.
Lẹyin eyi ni awọn ọmọ ile igbimọ to ku naa kin wọn lẹyin, wọn ni ki Mudashiru Obasa maa ba iṣẹ rẹ lọ gẹgẹ bii olori ile igbimọ aṣofin Eko.
Lọjọ Aje naa ni Mojisola Meranda to ti n dipo naa mu latigba ti wọn ti yọ Obasa kuro nipo ọhun.
Tẹ o ba gbagbe, oṣu kin-in-ni ọdun yii ni idaamu Obasa bẹrẹ, nigba ti awọn asọfin mẹtalelọgbọn yọ ọ nipo lasiko to wa nilẹ okeere.
Awọn ẹsun to ni i ṣe pẹlu ajẹbanu, ai ka ijokoo ile kun, jijẹ gaba lori awọn eeyan rẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn fi kan an nigba naa.
Ìpadabọ Obasa: Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ọ Bisi Akande, Segun Osoba
Ninu fidio kan to wa lori ayelujara, eyi ti Mudashiru Obasa ṣe lẹyin to gba ipo rẹ pada lọjọ Aje naa lo ti dupẹ lọwọ awọn eeyan to ti i lẹyin lasiko wahala.
Lẹyin to dupẹ lọwọ awọn aṣofin ile fun ifẹ ati aduroti wọn, Obasa tun darukọ Oloye Bisi Akande, gomina Osun tẹlẹ, ati Arẹmọ Olusegun Osoba, gomina Ogun nigba kan.
O loun dupẹ fun idasi awọn baba naa, ati awọn agbaagba mi-in ti wọn yanju ọrọ yii.
Lẹyin naa ni wọn sun ijokoo ipade siwaju lai ni gbedeke.
Obasa padà sípò olórí ilé aṣòfin Eko bí Meranda ṣe fipò sílẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook
Àwọn aṣòfin ní ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Eko ti dìbò yan Mudashiru Obasa, tó ń ṣoú ẹkùn Agege I ní ilé aṣòfin náà gẹ́gẹ́ bí olórí ilé náà.
Ìyànsípò rẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Mojisola Meranda kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ilé lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹta, ọdún 2025.
Lẹ́yìn tí Meranda, ẹni tó ń ṣojú ẹkùn Apapa I kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ ni àwọn aṣòfin náà tún yàn-án padà sípò igbákejì olórí ilé.
Obasa ni wọ́n búra fún gẹ́gẹ́ bí olórí ilé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́fà tí wọ́n yọ ọ́ nípò lọ́jọ́ Kẹtàlá, oṣù Kìíní ọdún 2025.
Àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kà sí Obasa lọ́rùn tí wọ́n fi yọ ọ́ nípò ni pé ó ń ṣe owó ìlú kúmọkùmọ àti pé, dídarí ilé lọ́nà tí kò tọ̀nà àti ìwà àjẹbánu.
Lẹ́yìn tí wọ́n yọ Obasa ni ọ̀pọ̀ àwọn aṣòfin náà yan Meranda gẹ́gẹ́ bí olórí ilé, tí wọ́n sì búra wọlé fún-un lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ọdún 2007 ni wọ́n kọ́kọ́ dìbò yan Obasa sílé aṣòfin Eko, tó sì di olórí ilé láti ọdún 2015 kó tó di pé wọn yọ ọ́ nínú oṣù Kìíní, ọdún 2025.
Ọ̀pọ̀ àwọn aṣòfin náà ni wọ́n kan sáárá sí Meranda fún ipa rẹ̀ fún ìgbà péréte tó lò gẹ́gẹ́ bí olórí ilé àti mímú àlááfíà bá ilé aṣòfin náà.
Bákan náà ni wọ́n yìn-ín lákin fún bí ó ṣe tẹ̀lé òfin àti ìlànà ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC lórí wáhàlá tó ń wáyé ní ilé aṣòfin náà.
Meranda kọ̀wé fipò sílẹ̀ lẹ́yìn tó ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn èèkàn kan lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congresives tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Eko tó bá wọn dá sí aáwọ̀ tó ń wayé ní ilé aṣòfin Eko.
Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Obasa sọ pé bí wọ́n ṣe yọ òun nípò kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nítorí àwọn aṣòfin náà kò tẹ̀lé ìlànà àti òfin tó yẹ láti yọ òun.
Ó ní òun ṣì ni olórí ilé aṣòfin lábẹ́ òfin àti pé òun ti padà sí ilé láti máa bá iṣẹ́ òun lọ.















