Ta ló ń ro ikú ro Olubadan tí ariwo ikú rẹ̀ fi gbalẹ̀ kan?

Aworan Olubadan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ariwo sọ kaakiri ilu Ibadan, ipinlẹ Oyo ati ori itakun ayelujara lanaa ọjọ Aje ọjọ kẹta oṣu Kẹta ọdun nigba ti iroyin sọ pe Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Olakulehin ti waja.

Iroyin naa sọ pe lẹni ọdun mọkandinlaadọrun ni kabiyesi papoda.

Idi ree ti BBC Yoruba fi kan si ọmọ kan ninu awọn ọmọ Olubadan lati fidi iroyin yii mulẹ.

Nigba to n ba wa sọrọ, ọmọ Olubadan naa ni ko si iku loju baba oun, koda, o n rẹju lọwọ, ti oun si wa ni ẹgbẹ ibusun rẹ lasiko ti a n ba oun sọrọ.

O fikun pe ko ko ko ni ara baba oun le, to si wa ni aaye pẹlu.

Bakan naa, ijọba ipinlẹ Oyo ti kede pe irọ to jina si ootọ ni iroyin naa.

Kọmiṣọnna fun aṣa ati irinajo igbafẹ nipinlẹ Oyo, Wasiu Olatubosun ti fidi rẹ mulẹ pe iroyin ofege ni iroyin naa, o ni koko lara Olubadan le bi ọta.

Kọmiṣọnna ni oun ba Ọmọba Olaseke Olakulehin to jẹ ọkan lara ọmọ ori ade naa sọrọ, ẹni to fidi rẹ múlẹ pe ṣaka lara baba da.

BBC Yoruba naa kan si aafin Olubadan ati ijọba ipinlẹ nigba ti a gbọ irin naa, ṣugbọn a ko le fi idi rẹ mulẹ.

"Olubadan ṣẹṣẹ jẹ amala tan ni lasiko t'awọn kan n gbe iroyin iku rẹ kiri"

Bakan naa ni akọwe iroyin Olubadan, Gbenga Ayoade, sọ pe ko si ohun to ṣe kabiyesi.

Ninu ọrọ rẹ, Ayoade sọ pe ko si iyọnu pẹlu baba nigba ti oun fi aafin silẹ lalẹ ọjọ Aiku.

O ni oun ko si tun gbọ nkan laburu kankan nigba ti oun tun pe aafin pada.

Ọgbẹni Ayoade ni Olubadan ṣẹṣẹ jẹ amala tan ni lasiko t'awọn kan n gbe iroyin iku rẹ kiri.

Akọwe iroyin Olubadan sọ pe ko si òtítọ ninu iroyin kan to tun sọ pe wọn ti gbe Kabiyesi kuro ni Ibadan lọ si ilu mii fun itọju.

O ni baba si wa niluu Ibadan, ko si nnkankan to ṣe Kabiyesi.

Ọba Olakukehin ti Gomina Seyi Makinde gbe ọpa aṣẹ fun lọjọ kejila oṣu Keje ọdun 2024 yoo pe aadọrun ọdun lọjọ karun un oṣu Keje ọdun yii.