Wọ́n tẹ èèyàn méje pa lásìkò tí wọn fẹ́ gba nǹkan ààwẹ̀

Aworan to n ṣafihan ibi ti ọpọ eeyan ti wa ṣaaju pẹlu idọti to kun ilẹ ibẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bauchi ti fidi ẹ mulẹ lọjọ Aje, ọjọ kẹta, oṣu Kẹta ọdun 2025, pe eeyan meje lo ti padanu ẹmi wọn nibi ti wọn ti n tẹ ara wọn lasiko ti wọn n gba nnkan aawẹ lọjọ Aiku.

Gẹgẹ bi alaye ti Alukoro ọlọpaa Bauchi, SP Ahmed Wakil, ṣe, o ni ileeṣẹ kan to wa loju ọna Jos lo n pin nnkan aawẹ bii ohun jijẹ fun awọn eeyan ti ko ni.

Ọdọọdun ni ileeṣẹ ọhun si maa n pin nnkan aawẹ naa gẹgẹ bo ṣe sọ.

Nibi ti wọn ti n gba tọdun yii lọjọ keji aawẹ Ramadan ni awọn ero to pọ naa ti bẹrẹ si i ti ara wọn gẹgẹ bo ṣe wi, nibẹ si ni eeyan mẹrin ti kọkọ dagbere faye.

"Ọpọ eeyan lo farapa nibi eto pinpin nnkan aawẹ, titi kan awọn ọmọde ati awọn obinrin"

SP Ahmed Wakil sọ pe awọn obinrin mẹta mi-in tun ti ku latari bi wọn ṣe tẹ wọn mọlẹ nibi ti wọn ti n gba ọrẹ aanu naa, yatọ si awọn mẹrin ti wọn ti kọkọ ku lọjọ Aiku ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

O ni nnkan bii aago mẹwaa kọja ogun iṣẹju laaarọ ni iṣẹlẹ ọhun waye.

Dokita agba lọsibitu ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo, Abubakar Tafawa Balewa University Teaching Hospital (ATBUTH) , naa ṣalaye pe awọn obinrin meji tun ku ninu awọn ti wọn gbe wa fun itọju lati ibudo nnkan aawẹ gbigba naa.

O ni awọn yoo maa fi to araalu leti bi onka naa ba ṣe n lọ si.

Obinrin kan ti iṣẹlẹ yii ṣoju rẹ, Laraba Saleh, sọ pe yatọ si awọn to di oloogbe, ọpọ eeyan lo tun farapa nibi eto naa, titi kan awọn ọmọde ati awọn obinrin.