Ìjàm̀bá okọ̀ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́rìndínlógún ní Ogun

Oko to ni ijamba

Oríṣun àwòrán, FRSC OGUN

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Kò dín ní èèyàn mẹ́rìndínlógún tó pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìjàm̀bá okọ̀ kan tó wáyé ní agbègbè Buhari Estate, òpópónà márosẹ̀ Abeokuta sí Isagamu ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Nǹkan bíi aago kan ọ̀sán ni ìjàm̀bá náà wáyé nígbà tí ọkọ̀ Mazda kan tó ní nọ́mbà KJA949YJ ṣàdédé gbiná.

Èrò mọ́kànlélógún ló wà nínú ọkọ̀ náà.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ tó ń rí sí ìrìnnà ojú pópó, FRSC fi léde, èèyàn mẹ́rìndínlógún nínú àwọn mọ́kànlélógún tó wà nínú ọkọ̀ náà ló jóná kọjá mímọ̀, tí wọ́n sì pàdánù ẹ̀mí lójú ẹsẹ̀.

Awon osise FRSC

Oríṣun àwòrán, FRSC OGUN

Oko to ni ijamba

Oríṣun àwòrán, FRSC OGUN

Ó ṣàlàyé pé àwọn mẹ́ta tó farapa ni wọ́n ti gbé lọ sí ilé ìwòsàn Federal Medical Centre, Idiaba, Abeokuta fún ìtọ́jú tó péye.

Ohun tó ṣokùnfà ìjàm̀bá náà, gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ, ni pé ọkọ̀ náà gbiná nígbà tí agolo gáàsì tó wà nínú ọkọ̀ náà búgbàmù lásìkò tí wọ́n ń bá ìrìnàjò wọn lọ.

Ọ̀gá àgbà FRSC ìpínlẹ̀ Ogun, Akinwumi Fasakin tó kó àwọn òṣìṣẹ́ FRSC sòdí láti ṣe àmójútó ìjàm̀bá náà ní ó ṣeni láàánú pé irúfẹ́ ìjàm̀bá náà wáyé.

Ó ní kò yẹ kí awakọ̀ ọkọ̀ náà gbà láti gbé agolo gáàsì tí afẹ́fẹ́ gáàsì wà nínú rẹ̀ sínú ọkọ̀ rẹ̀.

Fasakin rọ àwọn awakọ̀ láti yé kó àwọn ẹrù tó le gba iná bẹ́ẹ̀ sínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn èrò lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe ìrìnàjò.

Ó ní onírúurú ọkọ̀ ló wà fún oríṣiríṣi ẹrù àti pé àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ awakọ̀ wà fún wọn.

Ó pàrọwà sáwọn awakọ̀ àti èrò láti máa fi ààbò ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn wọn sọ́kàn tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìrìnàjò.

Bákan náà ló bá àwọn ẹbí tó pàdánù èèyàn wọn sínú ìjàm̀bá náà kẹ́dùn.