Mọ̀ nípa àǹfààní mọ́kànlá tó wà nínú jíjẹ èso Watermelon

Aworan eso Watermelon

Oríṣun àwòrán, Gettyimages

Àkọlé àwòrán, Ọ̀pọ̀ èso Watermelon tí wọn tò silẹ àti kékeré kan tí wọn gé èyí tó pọn pupọ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lawujọ wa lonii, ọkan lara awọn eso to gbajumọ to si wọpọ ni eso ti a mọ si Watermelon.

Awọn kan maa n pe watermelon ni elégédé oyinbo ledee Yoruba.

Eso kan to kun fun omi ni watermelon, bẹẹ lo si dun daadaa lẹnu.

Koda, kari aye ni watermelon wa, awọn mi-in si mọ ọn si eso to le tan orungbẹ bi ko ba si omi nitosi.

Yatọ si eyi, eso yii tun ni oore pupọ to n ṣe lagọ ara eeyan ti a ba n jẹ ẹ, iwadii si fi han pe ida mejilelaadọrun-un (92%) watermelon lo jẹ omi.

Oore tí Watermelon lè ṣe ara èèyàn

  • O maa n jẹ ki ifunpa giga wa silẹ

Dokita Sa'adatu Sulaiman, onimọ nipa ounjẹ nipinlẹ Kano, ṣalaye pe watermelon daa pupọ lati kapa ifunpa to ba n ga.

"Kinni funfun kan wa lara rẹ, oun lo maa n ṣiṣẹ fun ki ẹjẹ to ba n ru, lọ silẹ"

Bẹẹ ni dokita nipa ounjẹ naa ṣalaye.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O fi kun un pe kinni funfun ọhun maa n pese eroja kan ti a mọ si arginine, eyi to maa n jẹ ki ẹjẹ rin kiri ara bo ṣe yẹ.

  • O maa n da aabo bo ara

Dokita Jawahira Muhammad, lati ileewosan Murtala, nipinlẹ Kano, ṣalaye pe watermelon kun fun ọpọ omi, eyi to le da aabo bo ara eeyan, ti yoo si mu ilera wa pé.

O fi kun un pe eroja calory inu watermelon lo kere ju ninu awọn eso, eyi ti ko ni I jé ki eeyan sanra asanju.

  • *Ìdèna àrun ìtọ̀ ṣúgà

Gẹgẹ bi Dokita Sa'adatu Sulaiman ṣe wi, bi ẹnikẹni ba fẹẹ dena arun itọ ṣuga, tabi to fẹẹ din bo ṣe n daamu rẹ ku, ki ẹni bẹẹ maa jẹ watermelon deede.

Bi o ba n jẹ watermelon, yoo din bi ṣuga ṣe n ga lara kú, gẹgẹ bi dokita naa ṣe sọ.

  • Fífọ kindinrin àti ẹ̀dọ̀

Dokita Jawahira sọ ninu ọrọ rẹ pe watermelon maa n ṣe afọmọ kindinrin ati ẹdọ eeyan.

"Eyi lo fi je pe bi eeyan kan ba ni aisan kindinrin, to ba de ọsibitu, wọn yoo ni ko maa jẹ ọpọlopọ watermelon."

  • Ilera oju

"Watermelon kun fun ọpọ fitamin bii vitaminA, B, vitamin C, vitamins B1 ati B6."

Dokita Jawahira lo ṣalaye bẹẹ.

O ni Vitamin A to wa ninu rẹ dara fun ilera oju.

"Vitamin C to wa nibẹ n jẹ ki egbo tete san, o si maa n din irora ku lara. "

  • Kí oúnjẹ tètè dà nínú

Watermelon tun ni eroja fiber to maa n jẹ ki ounjẹ tete da ninu.

Yatọ si omi to pọ ninu rẹ, Dokita Jawahira ṣalaye pe bi a yọ omi kuro lara eso yii tan, fiber aṣaraloore lo ku.

  • Ó dára fún iṣẹ́ ọkàn àti ọpọlọ

Fitamin B1 ati B6 to wa ninu watermelon maa n ṣiṣẹ to daa fun irori ati ọkan eeyan.

Dokita sọ pe awọn eroja to le dena aisan ọkan wa ninu watermelon.

Aworan eso watermelon to n hu nilẹẹlẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • Ó máa ń jẹ́ kí ibi tó bá wù lára tètè fà nítori èròjá citrulline tó wà nínú rẹ̀.
  • Watermelon ń koju ewu àpọ̀jù ọ̀rá ara:

Alaye ti Dokita Jawahira ṣe nipa eyi ni pe watermelon funra rẹ ni ọra ti a mọ si cholesterol ninu, eyi naa lo si fi n koju ọra to ba fẹẹ wa ninu awọn iṣan ara kan.

"Bi ọra ba pọju ninu ẹjẹ, o le fa awọn iṣoro mi-in sinu ara, ṣugbọn bi eeyan ba n jẹ Watermelon, yoo to ọra to wa ninu ọra sipo to yẹ, yoo si bọ si rẹgi bo ṣe yẹ ko ri ninu ara." Bẹẹ ni Dokita wi.

  • Ó dára fún ìtọ́jú ara ríro

"Bi ara ba n ro ọ lẹyin iṣẹ oojọ tabi iṣẹ agbara kan ti o ṣe, bi o ba jẹ watermelon, yoo jẹ ki ara tu ọ, nitori eroja citrulline to wa ninu rẹ.

Bakan naa ni Dokiya fi kun un pe bi o ko ba fẹ ki ara maa dun ọ lẹyin ere idaraya, ki o too bẹrẹ ere naa rara, mu o kere tan, ife watermelon meji ti o ti fún omi inu rẹ jade.

  • Ó dára fún níní àwọ̀ ara to jí pepe

Vitamin A ati C to wa ninu watermelon maa n mu awo ara jọlọ.

Eroja ti a mọ si collagen ni Vitamin C maa n mu wa, eyi to maa n jẹ ki awọ ara dan, ti irun ori paapaa yoo si maa gun si i , gẹgẹ bi alaye Dokita Sa'adatu.

"Bakan naa ni Vitamin A paapaa maa n mu awọ ara jọlọ, o si maa n pese ohun ti yoo jẹ ki egbo tete san bi eeyan ba farapa. "

Ṣugbọn o, awọn dokita kilọ, pe awọn to ba ni aisan itọ ṣuga lati yago fun ohun to n ba n dun.

Aworan watermelon pẹlu kóró rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Èso Watermelon tí wọn ti gé sí wẹ́wẹ́, tó sì pọn fún jíjẹ

Ṣé a lè jẹ kóró watermelon?

Awọn onimọ nipa ilera sọ ọ di mimọ, pe kóró watermelon ko ni ṣuga pupọ ninu, o si ni fiber to pọ ju eso watermelon funra rẹ lọ.

Wọn tun sọ pe kóró naa ni eroja citrulline to ni kẹmika ninu.

Bakan naa ni wọn lo tun ni magnesium ati folate, eyi ti ki i jẹ ki kokoro mú ni lara.

Kóró watermelon tun ni awọn kẹmika kan to maa n ṣeranlọwọ lati dena aisan ọkan ati rọparọsẹ

Iwadii ijilẹ ti fi han, pe watermelon ati kóró inu rẹ dara pupọ fun alaafia awa ẹda eeyan, wọn si ṣee jẹ.