Ìjọba Eko ní kí Peller, gbajúmọ̀ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ lórí ayélujára, san owó orí ₦36m, ariwo sọ

Habeeb Hamzat, ti ọpọ eeyan mọ si Peller wọ asọ funfun ati buluu, o si fi ẹsọ palaba si ọrun rẹ, bakan naa lo ta irun rẹ ni koko

Oríṣun àwòrán, Peller/Instagram

Àkọlé àwòrán, Habeeb Hamzat, ti ọpọ eeyan mọ si Peller
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbajugbaja ọdọmọkunrin sọrọsọrọ ori Tiktok, Habeeb Hamzat tawọn eeyan mọ si Peller ni ọrọ rẹ tun gba ori ayelujara kan bayii, lẹyin ti ijọba ipinlẹ Eko ni ki o san owo ori toto milọnu mẹrindinlogoji naira. (36m)

Ọrọ yii lo ti fa ọpọ ariyanjiyan lori ayelujara ati akiyesi fun awọn sọrọsọrọ ori ayelujara lori owo lorilẹede Naijiria.

Peller, ninu fọnran kan to gbe sori ayelujara ni eyi jẹ ohun iyanlẹnu gbaa fun oun, to si tẹnu mọ pe oun ko ni ileeṣẹ , oun ko si ri ro pe o yẹ ki oun san owo ori kankan.

O tẹnumọ pe oun n pawo sapo lati ori ayelujara Tiktok, ti ki ṣe ileeṣẹ Naijiria, fun idi eyi oun ko ro pe oun yoo san owo ori.

Ṣugbọn akọsẹmọsẹ lori owo ori ṣalaye pe ohun ti Peller sọ fihan gbangba pe ko ni imọ nipa owo ori lorilẹede Naijiria.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

"Fun ijọba ipinlẹ Eko lati ni kí Peller san ₦36m owo ori, o fi han pe Peller ti pa owo to to ₦152m wọle laarin igba ti wọn se ayẹwo rẹ"

Onimọ nipa owo ori naa ni ati eyi wọpọ laaarin awọn ọdọ to n lo ayelujara lati fi pa owo nla sapo.

Alaye nipa owo ori tuntun ti ijọba gbe kalẹ tii yoo gberasọ ni ọdun 2026, ṣugbọn o ti bẹrẹ nipinlẹ Eko, fihan pe ẹnikẹni to n pa owo toto N800,000 tabi ju bẹlọ lọdun ni lati san owo ori Personal Income Tax.

Owo ori naa si bẹrẹ lati ida mẹẹdogun si ida mẹẹdọgbọn.

Amoye owo ori naa ni fun ijọba ipinlẹ Eko lati ni kí Peller san owo toto ₦36m, o fi han pe Peller ti pa owo to to ₦152m wọle laarin igba ti wọn se ayẹwo rẹ.

O tẹsiwaju pe eyi fihan pe ijọba n ṣe ayẹwo bí owo ṣe n wọle jade pẹlu BVN ati NIN ko to di pe wọn ni ki Peller san #36m.

"Ko ki n ṣe pe ijọba kan ṣadede gbe owo dide. Gbogbo owo to n wọle jade ni ìjọba mọ nípa.

"Ti ijọba ba ni ki eeyan san ₦36m gẹgẹ owo orí, o tumọ si pe, wọn ti ṣe gbogbo ayẹwo lori bí owo ṣe n wọle jade.

"Pe o ko mọ nipa ofin ko ni itumọ."

Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa owó orí tuntun

Lara atunṣe to waye labẹ ofin owo ori naa bayii ni pe awọn ṣọja ko ni i maa sanwo ori mọ lati ara owo to ba n wọle fun wọn bii ajẹmọnu (Personal Income Tax).

Abala 77 ninu iwe atunṣe ofin owo ori naa ṣalaye pe:

Fun ijọba ipinlẹ, wọn yoo pin ida aadọta (50%) owo to ba wọle ni ọgbọọgba.

Ida ogun (20%), yoo wa fun bi wọn ba ṣe pọ to nipinlẹ naa, nigba ti wọn yoo gba ida ọgbọn ninu owo ori to n wọle lati ara ounjẹ ati nnkan lilo.

Wọn tẹnu mọ ọn pe ibi ti wọn ba ti n pawo wọle ju nipa ohun ti wọn n jẹ ni ijọba yoo fi pin in, ki i ṣe ibi ti wọn ti n fi owo ọhun ranṣẹ si apo ijọba.

Bakan naa lo ri fun ijọba ibilẹ ti yoo gba ida marundinlogoji (35%).

Bẹẹ ni wọn si tun fi kun iye ọjọ ti wọn yoo maa fi pese nọmba idanimọ owo ori araalu, Tax Identification Number.

Wọn sun un kuro ni ọjọ meji, o ti di marun-un bayii.

Aworan Peller to lo ibori funfun pẹlu aṣọ funfun to wọ sọrun

Oríṣun àwòrán, Official Peller and AI Jarvis

Àkọlé àwòrán, Habeeb Hamzat ti awon eeyan mọ si Peller

Ta ni Peller?

Peller yii ni orukọ abisọ rẹ n jẹ Habeeb Hamzat, ti wọn si bi ni Ọjọ kẹwaa oṣu karun un ọdun 2005.

O jẹ gbajugbaja sọrọsọrọ ori ayelujara Tiktok.

Peller di ilumọka sọrọsọrọ ni ọdun 2023, ti o si ọpọ ololufẹ to n ti lẹyin kaakiri agbaye.

Lọwọ bayii, Peller yii sọrọsọrọ akọkọ ti o ni ọpọ oju to n wo lori ayelujara .

Lọdun 2024, o gba ami ẹyẹ sọrọsọrọ to dara ju nibi ayẹyẹ Trace Awatd&Festival.