Ìrọ̀rùn dé báwọn àgbẹ̀, ẹ̀rọ Díróònù tó le fọ́n irúgbìn, omi tàbí òògùn dé àrọ́wọ́tó
- Author, Busayo James-Olufade
- Role, Senior Journalist
- Reporting from, Lagos
Ajọ to wa fun agbelarugẹ ipese ounjẹ ati eto ọgbin labẹ ajọ isọkan orilẹede agba, The Food and Agriculture Organization (FAO) ti kede pe ida aadọrin si ọgọrin ninu ọgọrun awọn agbẹ to wa nilẹ Naijiria lo n se ọgbin arojẹ lasan.
Igbesẹ yii si lo ni o n se akoba fun odiwọn ipese eroja ounjẹ ti a n pese labẹle lorilẹede yii.
Idi si eyi si fi ri bẹẹ ni pe ọpọ agbẹ to w ani Naijiria ni ko ni irinsẹ ọgbin igbalode lati fi da oko, ki wọn si jẹ agbẹ alada nla sugbọn to jẹ pe iwọnba ounjẹ ti idile wọn yoo jẹ, nikan ni wọn gbajumọ.
Ki wa ni ọna abayọ si isẹlẹ yii, ọna wo ni awọn agbẹ wa yoo gba lati di alada nla gẹgẹ bo se ri lawọn orilẹede to ti goke agba?

"Ẹrọ Diroonu le fọn omi sinu oko to to ogun eeka laarin wakati meji"
Lara ọna lati wa ojutu si isoro ipese ounjẹ alada nla nilẹ Naijiria lo mu ki ọkunrin onimọ nipa ẹrọ igbalode kan Femi Adekoya gbe igbesẹ lati wa ọna abayọ.
Igbesẹ ti Adekoya gbe ni bo se pese ẹrọ diroonu to n fo eyi ti yoo mu agbega ba ipese ounjẹ ati agbẹ ọlọsin ohun abiyẹ.
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori awọn anfaani lilo ẹrọ Diroonu yii atawọn isẹ to le se, Adekoya ni ẹrọ naa le fọn omi sinu oko to to ogun eeka laarin wakati meji.
To si jẹ pe eeyan ni yoo sisẹ naa, yoo gba ọpọ eeyan ni ọjọ marun tabi ọsẹ kan lati sisẹ naa.
"Katakata le lo ọjọ kan ati abọ lati sisẹ naa amọ ẹrọ diroonu si yara ju lọ.
Ẹrọ yii tun le se ayẹwo ara ohun ọgbin wọn, o le se ayẹwo ewurẹ abi adiẹ wọn.
Ijọba si le lo ẹrọ diroonu naa lati fi dokowo pẹlu awọn agbẹ."
Bakan naa, ẹrọ Diroonu yii le tete se awari awọn Kokoro kekeke to n jẹ oko, bakan naa lo tun le fọn agbado sinu oko.

"Ẹrọ Diroonu yoo se iranwọ pupọ lati mu ẹmi awọn agbẹ gun, ti wọn ko si ni maa fin oogun apakokoro simu"
Femi Adekoya woye pe ọkan oun si lati kọ nipa isẹ ọgbin nitori isẹ ọgbin ko le rọrun lai si ẹrọ yii.
"Ohun ti awọn agbẹ n fi ọjọ kan se, laarin wakati kan, ẹrọ diroonu yii yoo se.
Yatọ si eyi, ẹrọ diroonu yii tun le sisẹ lawọn agbegbe oko to wa lori apata tabi yangi.
Tun wẹ, ẹrọ diroonu yii tun le sisẹ ni our dudu tabi lasiko ti oju ọjọ ko ba dara."
Nipari, Adekoya ni ẹrọ Diroonu igbalode naa yoo se iranwọ pupọ lati mu ẹmi awọn agbẹ gun, ti wọn ko si ni tete di arugbo tori isẹ oko ti wọn n se.
Idi ni pe ẹrọ Diroonu naa yoo ran wọn lọwọ lati yago fun awọn oogun ti wọn le fin si imu ti wọn ba lo ilana abalaye lati fin oko wọn.






