Ọkọ àfẹ́sọ́nà kọ̀ mí sílẹ̀ pé mo ní iṣan lápá, ọyàn mi sì ǹ rá torí iṣẹ́ ọ̀gbìn – Àgbẹ̀ Obìnrin
Lady Farmer: Eku àti aláǹgbà dà mí láàmú lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tí mo sun ilé alámọ̀ ní abúlé
- Author, Busayo James-Olufade
- Role, Broadcast Journalist
- Reporting from, Lagos
Isẹ agbẹ ni isẹ ilẹ wa, ẹni ti ko sisẹ, yoo jale nitori iwe kikọ laisi ọkọ tabi ada, ko tii pe.
Nilẹ Yoruba, awọn ọkunrin ni ọpọ Agbẹ to n da oko amọ obinrin kan ree, Bose Suberu, to yan isẹ ọgbin laayo.
Se ko si ohun ti ọkunrin n se, ti obinrin naa ko le se amọ isẹ ọgbin ti Bose yan laayo yii, mu awọn ipenija kan wa fun.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Suberu salye idi yo se yan isẹ ọgbin laayo ati awn ohun toju rẹ n ri nidi isẹ naa.
Onimọ ẹrọ Kọmputa ni mi amọ lati inu ọkan mi ni isẹ agbẹ ti wu mi:
Bose Suberu salaye pe onimọ nipa ẹrọ ayarabiasa Kọmputa ni oun, ti oun si n sisẹ naa fun ọdun diẹ lai ri iwuri kankan.
O salaye pe oun maa n jokoo fun ọpọ wakati loojọ lati sisẹ, eyi ti ko ba oun lara mu.
Agbẹ obinrin naa ni nigba to di ọdun 2015, eyiun ọdun meje sẹyin, oun pinnu lati bẹrẹ isẹ ọgbin, gẹgẹ bo se n wu oun latinu ọkan wa.
Eku ati alangba da mi laamu lọjọ ti mo kọkọ sun si ile alamọ ni abule:
Nigba to n salaye iriri rẹ nidi isẹ ọgbin to yan laayo naa, Bose Suberu royin, ilẹ kun.
O salaye o kọkọ nira fun oun lati maa gbe ni abule, nibi ti oun da oko si nitori ko da bii igboro to ti ba oun lara mu tẹlẹ.
Bose ni Eku, alangba ati orisirisi nnkan ti oun kọkọ fi oju ri ni ọjọ akọkọ ti oun de abule naa ko ba oun lara mu rara.
Amọ o ni nigba ti yoo fi to ọsẹ kan, gbogbo ipenija naa ni oun ti bori wọn, ti ara oun si balẹ lati gbe abule.
Bakan naa ni obinrin agbẹ yii mẹnuba pe ọkan lara ipenija to n koju oun nipe ki oun sanwo fun awọn ti yoo wa ba oun dako.
O ni lọpọ igba, awọn lebira oko naa ko ni sisẹ naa bo se yẹ, ati bo se tẹ oun lọrun.
Ayipada oju ọjọ, ọda omi ati isoro alagbase n da mi laamu:
Obinrin agbẹ yii tu wa mẹnuba pe lara ipenija kan gboogi to n da oun laamu gẹẹ bii agbẹ ni ayipada oju ọjọ.
O ni eyi gan ni ko jẹ ki oun ojo maa rọ sori awọn ire oko ni asiko to yẹ, ti oju ọjọ fi n gbona janjan
O fikun pe o di dandan ki oun wa omi lọ lati fi wn awọn ire oko oun, ki wọn maa baa jona mọlẹ.
Bakan naa lo ni o maa n soro lati ri awọn alagbase ti yoo wa sisẹ oko, ti wọn si tun maa n beere owo gege.
Ọkọ afẹsọna mi kọ mi silẹ, o ni mo ni isan lapa, ọyan mi n ra tori isẹ agbẹ:
Nigba to tun n salaye awọn ohun ribiribi ti isẹ ọgin tun gba lọwọ rẹ, obinrin agbẹ naa ni iriri oun pẹlu ọkọ afẹsọna oun tẹlẹ naa wa lara rẹ.
O salaye pe ọkunrin naa lo n fapa janu pe isẹ agbẹ ti oun yan laayo naa, ti n jẹ ki oun maa ni isan lapa.
Bakan lo ni o n se awawi pe ọyan oun ti n gbẹ nitori isẹ aselaagun, ti oun n se.
O ni oju ti yoo ba si ba ni kalẹ, kii ti aarọ̀ se ipin, lo mu ki oun tete yaa mu oju oun kuro lara ọkunrin naa nitori oun ko le fi isẹ agbẹ sere rara.
O sisọ loju rẹ pe ironu ba oun fa a lẹyin ti isẹlẹ ikọsilẹ naa waye amọ oun pinnu lati tẹsiwaju pẹlu isẹ ọgbin ti ọkan oun yan laayo.
Bose Suberu wa yan pe bi wọn ba gbe owo nla silẹ, pe ki oun maa ko bọ ni igboro, oun le se gbaa tabi kurop ni oko.
O ni ayafi ti oun ba ri ẹni ti yoo gbe owo kalẹ fun iranwọ isẹ oko oun, oun yoo gba lọwọ rẹ lati mu ki isẹ ọgbin oun gberu si.







