Ẹ gbé àwọn Ahmed Idiris àti àwọn yòókù rẹ̀ lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje- Adajọ Adeyemi Ajayi

Ahmed Idiris ni ile ẹjọ

Ilé ẹjọ́ gíga tó wà ní nílùú Abuja, federal capital territory (FCT) lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà ti pàsẹ pé kí wọn gbé adari ilẹ isẹ́ ijọba apapọ to n sakoso eto ìsirò lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà, tẹlẹri Ahmed Idris lọ si ọgbà ẹ̀wọ̀n, Kuje tó wà nílùú Abuja.

Wọ́n mú Idris Ahmed ni ìpínlẹ̀ Kano lẹ́yìn tí ó kùnà láti yọjú sí àjọ tó n gbógun ti sise owó ilu kumọ -kumọ ati iwa ibajẹ miran lorilẹ ede Naijiria, iyẹn ajọ EFCC látàrí ẹ̀sùn eto iwajẹ sise owo to le ni ọgọrin bilọnu naira ilu kumọ-kumọ ti wọn fi kan an, ni eyi ti o se si kuna lati jẹ ìpè wọn.

Ẹ̀sùn yii lo faa ti adari ile-isẹ́ ijọba apapọ to n mojuto eto inawo, eto isuna ati ilana tẹ̀ẹ́kótọ̀ lorilẹ ede Naijiria ,Zainab Ahmed fi ni ki Ahmed Idris lọ rọ́kún sile naa, ki wọn lee bẹ̀rẹ̀ eto iwadii ti ajọ EFCC fi kàn án.

Ahmed Idris pẹlu akẹgbẹ rẹ Godfrey Olusegun Akindele, Mohammed Kudu Usman ati ile isẹ to n mojuto eto tita ati rira — Gezawa Commodity Market and Exchange Limited ni ajọ EFCC gbe wa sile ẹjọ fun ẹ̀sùn eto iwa ibajẹ .

Lasiko ti wọn wa nile ẹjọ , lọjọ Ẹti yii ,ni agbẹjọro fun ajọ EFCC , Rotimi Jacobs, si rọ adájọ́ pe ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn ni awọn afurasi naa hu, ni eyi ti ofin section 109 ti ACJA fidii rẹ̀ múlẹ̀ , ni eyi ti adajọ Adeyemi Ajayi si gba ẹ̀sùn ọhun wọle gẹgẹ bi ìwà ọ̀daràn .

Ahmed Idiris nile ẹjọ

Amọsa, Ahmed Idris ati awọn yooku rẹ sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun mẹ́rìnlá ti ajọ EFCC fi kan wọn.

Agbẹjọro fun Ahmed Idris ,Chris Uche, wa rọ adajọ pe , ki wọn gba béèlì awọn oníbàárà ohun, iyẹn Ahmed Idris . O sọ pe " Niwọn igbati ko si awuye-wuye lori awọn ti wọn fẹsun kan láti tako ofin lati igba ti wọn ti wa ni àhámọ́ ajọ EFCC, o yẹki adajọ gba beeli wọn " .

Olùṣirò owó àgbà fojú balé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn olè jíjà

Ahmed Idria ati awọn afurasi yoku

Olusiro owo agba tẹlẹ fun ilẹ wa, Ahmed Idris, ti foju bale ẹjọ giga tijọba apapọ to wa nilu Abuja lonii.

Saaju ni Agbẹnusọ fun ajọ EFCC, Wilson Uwujaren ti kede loju opo Facebook ajọ naa pe Adajọ Adeyemi Ajayi ni yoo maa gbọ ẹjọ naa.

Ẹsun ti wọn fi kan Olusiro owo agba tẹlẹ naa ni pe o ko owo orilẹede yii sapo ara rẹ, eyi to to billiọnu mọkandinlaadọfa o le miliọnu lọna irinwo naira (N109.4bn).

Ahmed Idris ati awọn mẹta miran si ni ajọ EFCC dijọ fi ẹsun kan pe wọn pa owo naa ni popo si apo ara wọn.

Gbogbo awọn afurasi naa si lo yọju sile ẹjọ lonii.

Orukọ awọn yoku ni Godfrey Olusegun Akindele, Mohammed Kudu Usman ati adari ileesẹ kan to n se pasipaarọ owo naira si ti ilẹ okeere, ti wọn pe orukọ rẹ ni Gezawa Commodity Market and Exchange Limited.

EFCC, nigba to n salaye ẹsun to fi n wọ awọn eeyan naa lọ sile ẹjọ sọ pe “ijọba fi dukia kan ti owo rẹ to N84,390,000,000 si ikawọ awọn eeyan naa amọ ti wọn fi ọna ẹburu da ijọba.

O ni awọn eeyan naa gba owo ọhun lori dukia naa lati ipasẹ Godfrey Olusegun Bamidele, eyi to jẹ iwa ọdalẹ sijọba.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Kẹrindinlogun osu Karun ọdun 2022 yii ni akara tu sepo, ti ajọ EFCC si kede pe oun ti mu Olusiro-Owo agba si ahamọ.

Ahmed Idris ati afurasi mii

Iroyin naa si lo ya awọn ọmọ Naijiria lẹnu pupọ, ti atẹjade kan ti EFCC fisita lẹyin naa ni se ni Idris gbe owo biliọnu lọna ọgọrin naira gba ibomiran lọ.

Idi si ree tijọba apapọ fi ni ko lọ rọọkun nile na, titi ti iwadi yoo fi pari lori awọn ẹsun tijọba fi kan-an.

Bi igbẹjọ naa ba se lọ loni, la maa mu wa fun yin.