Mo kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹ́gbọ́n mi Serubawon lásìkò tí mò ń tẹ́le e kiri láì mọ̀ pé èmi ló kàn - Adeleke
Màá kọ́kọ́ sanwó òṣù tó ti pẹ́ sẹ́yìn tí ìjọba Osun jẹ òṣìṣẹ́ tí mo bá ṣe dórí àléèfà – Adeleke
Gomina tuntun ti ilu ṣẹ̀ṣẹ̀ dibo yan nipinlẹ Osun, Sẹnetọ Ademola Adeleke tí fi ọwọ soya pe oun ko ni ja awọn oludibo kulẹ.
Adeleke fi ọwọ idaniloju bẹẹ sọya lasiko to ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀.
Ifọrọwanilẹnuwo naa lo waye lẹyin ti Adeleke gba iwe mo yege ibo tan lọdọ àjọ eleto idibo nilu Osogbo.
Àwọn ohun ti maa kọkọ mojuto ree ti mo ba gba ọ̀pá àṣẹ:
Nigba to ń salaye àwọn igbesẹ ti yoo kọ́kọ́ gbe to bá ti gori aleefa, Adeleke ni owo ti ijọba to ń lọ jẹ àwọn osisẹ ni oun yoo kọ́kọ́ wa bi oun yoo ṣe san.
"Aanu awọn osisẹ maa n ṣe mi pupọ, mo si maa n ki wọn ku irọju ni gbogbo igba, mo maa wa bi maa se sanwo wọn fun wọn."
Adeleke sọ eyi bi o tilẹ jẹ pe ọpọ igba ni gomina to wa lori aleefa, Adegboyega Oyetola ti maa n tẹnumọ pe, oun ko jẹ osisẹ kankan ni owo osu nipinlẹ Osun.
Bakan naa, ní gomina tuntun naa ni ko si oju ọna to ye kooro mọ ni Osun, oun yoo sì wa bi oun yoo ti ṣe ọna.
Ìjọba mi ko jẹ owo osisẹ kankan - Oyetola
Bi gomina tuntun ni Osun se n seleri lati san awọn ajẹsilẹ owo osu awọn osisẹ tijọba ipinlẹ naa jẹ, gomina to wa lori aleefa, Adegboyega Oyetola ti wa ni oun ko jẹ owo osisẹ kankan sọrun.
Bẹẹ ba gbagbe, gominaOyetola lo ti kọkọ salaye nibi ipade ita gbangba ti BBC Yoruba se nilu Osogbo pe ko si gbese owo osu osisẹ aknkan lọrun oun.
Oyetola fesi bẹẹ nigba to n dahun si ọrọ Adeleke pe ojoojumọ ni oun maa n sọkun atipe iya to n jẹ awọn osisẹ nipinlẹ naa ti pọju, ti ijọba si jẹ wọn lowo.
"Ọrọ kiki awọn ara Osun ku irọju kọ ni eleyi, emi ko jẹ wọn ni owo osu ati ajẹmọnu kankan.
Gbogbo osu wọn ni mo ti san perepere fun wọn."
Bakan naa ni Oyetola fikun pe oun ko jẹ ajẹsilẹ owo idakọmu awọn osisẹfẹyinti eyiun Pension kankan sọrun.
"Yatọ si pe n ko jẹ owo osu osisẹ ati owo idakọmu awọn osisẹfẹyinti sọrun, mo tun n tiraka bi agbara mi se mọ laarin owo tasọrẹ to n wọle sapo ijọba Osun ati gbese rẹpẹtẹ ti mo jogun bii gomina, lati san awọn ajẹsilẹ gbese naa."
Ń ko ni doju tí gbogbo ọmọ Osun, maa mu ileri ìpolongo ibo ti mo ṣe ṣẹ:
Adeleke tun sọ siwaju ninu ifọrọwerọ naa pe ni gbogbo awọn ọmọ Osun ni òun ti seleri fún, tí òun kò sì ní doju ti wọn.
Ó jí gbogbo ileri tí oun ṣe wọn lasiko ìpolongo ibo ni oun yoo ṣe amusẹ rẹ.
"Mo ti lọ kaakiri ilu oyinbo, mo si mọ èèyàn, koda ọpọ wọn ti n pe mi pe awọn n bọ wa da ileesẹ aje silẹ ni Osun"
Davido ati ọmọ mi to n kọrin gan ti jẹjẹ lati ibudo igbafẹ kan silẹ, ti àwọn eeyan yoo ti maa ṣeré.
Eyi gan-an maa mu owo wọle fun ìjọba gẹgẹ bo ti n waye ni Amẹrika.
Mo fẹ́ràn ẹ̀gbọ́n mi Isiaka Adeleke nigba to wa laye:
Nigba to ń sọ̀rọ̀ nipa ẹgbọn rẹ to ti di oloogbe, Eyiun Sẹnetọ Isiaka Adeleke, Gomina tuntun ni oun nifẹ rẹ pupọ nigba to wa laye.
"Kódà, níbi ti mo feran wọn de, lati igba ti wọn ti jẹ gomina àkọ́kọ́, ni mo ti maa n ba ẹgbọn mi de iru fila wọn ti mo de yii.
Ibi ti mo feran wọn de, mo maa n tẹle wọn kaakiri ni lai mọ pe emi naa yoo di gomina."
Adeleke ni oun kọ ẹ̀kọ́ pupọ lara ẹgbọn òun, to si kọ oun lati maa saanu fun àwọn alaini.
Ó ní nigba tí ẹgbọn oun ku tan, gbogbo iriri ti oun kọ lara rẹ wa wulo fun oun lati lo ninu oselu.
Ń ko mọ boya ara awọn ọmọlẹ́yìn Aregbesola wa lara awọn ọmọ ẹgbẹ́ APC to wa darapọ mọ wá:
Adeleke, lasiko to n sọ̀rọ̀ lori boya awọn alátilẹ́yìn Rauf Aregbesola ṣíṣẹ fun láti bori ibo, salaye pe awọn ọmọ ẹgbẹ́ APC kan wa darapọ awọn saaju idibo àmọ́ oun ko mọ boya awọn alátilẹ́yìn Aregbesola wa lara wọn.
Ó ní àwọn èèyàn kan nínú APC ni àwọn ko ni kúrò ninu ẹgbẹ́ naa àmọ́ àwọn yoo sisẹ fun àṣeyọrí oun.
Bákan náà, lo sọ pe àwọn èèyàn kan lara wa ninu PDP to n fi apa janu, naa lọ darapọ mọ APC lati sisẹ fun wọn, bí ile aye ṣe ri nìyẹn.
Mo dupẹ lọwọ awọn eeyan Osun pe wọn yan mi ni Gomina:
Gomina tuntun naa wa dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Osun pe wọn dibo yan oun sipo, to si leri leka pe oun ko ni ja wọn kulẹ.
Ó tún fi dá wọn lójú pé ìyá ko ni jẹ wọn lasiko ti oun ba wa lori aleefa bii gomina.













