Oluwo kí gómìnà tí wọ́n dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke kú oríire

Oluwo tí ìlú Iwo, Ọba Abdulrosheed Akanbi Adewale ti kí gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn ní ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke kú oríire.
Ọba Adewale nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lónìí ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Keje, ọdún 2022 ní òun gbóríyìn fún ìgboyà àti ọkàn akin tó ṣe nínú ìdìbò náà.
Ó wá gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún Adeleke ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ tí yóò fi darí ìpínlẹ̀ náà.

Oríṣun àwòrán, OLUWO/FACEBOOK

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/ADELEKE
Bákan náà ló rọ gbogbo àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Adeleke kó le gbé ìpínlẹ̀ Osun dé èbúté ògo kó sì yọ ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́ àìrajaja ètò ọrọ̀ ajé.
Àtẹ̀jáde náà tó jáde látọwọ́ agbẹnusọ rẹ̀, Alli Ibraheem pè fún àjọṣepọ̀ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ láti gbárùkù ti gómìnà tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn náà.’
Ọba Adewale ní igbé ayé Adewale gbọ́dọ̀ jẹ́ àwòkóṣe fún àwọn ọ̀dọ́ tó ń bọ̀ lẹ́yìn.
Bẹ́ẹ̀ náà ló ní ó wu òun kí ọmọ Iwo di gómìnà ní ọjọ́ kan.










