Àwọn ọ̀dọ́ lé aṣòfin sáré, sọ ‘Pure water’ lú torí kò ṣe àmúṣẹ ìlérí rẹ̀

Osei Kyei Mensah-Bonsu

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn ọdọ kan ni Ghana ti fi ibinu le aṣofin kan kuro lagbegbe wọn lẹyin ti wọn ni o kuna lati mu awọn ileri to ṣe fun awọn ṣẹ.

Bi wọn ṣe n sọ omi inu ọra lu aṣofin Osei Kyei Mensah-Bonsu, naa ni wọn n bu ni mẹsan an mẹwaa lagbegbe Suame, to wa ni Asante, lọjọ Aje.

Iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti aṣofin ọhun ṣabẹwo sagbegbe naa lati ni gbolohun pẹlu awọn ọdọ.

Bi awọn kan ṣe n ke ibosi le lori, lawọn mii n ju oriṣiriṣi nnkan bii omi inu ọra lu u.

Lẹyin naa lawọn ọlọpaa tete gbe kuro laarin wọn lọna ati doola ẹmi rẹ.

A ko fẹ ri ọ laarin wa mọ lawọn araalu n pariwo

Ọjọ Ẹti, to jẹ ọjọ karundinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022 yii lawọn ọdọ agbegbe ti Mensah-Bonsu n sọju kọkọ di oju ọna nitori ipo ti oju ọna ọhun wa.

Eyii lo mu ki aṣofin naa ṣabẹwo sagbegbe naa lati foju ara rẹ ri bi ọna ọhun ṣe ri.

Ni kete ti awọn eeyan gbọ pe aṣofin ọhun n bọ nibẹ ni wọn ko ara wọn jọ lati le danu.

Orin a ko fẹ ri ọ laarin wa mọ lo gba ẹnu wọn titi ti wọn fi le lọ si agbegbe Tarkwa Maakro Ghana Commercial Bank.

Asiko ti wọn n kọ orin naa ni wọn ri obinrin kan to n ta omi inu ọra, ti wọn si bẹrẹ si n ju omi naa lu.

Awọn eeyan agbegbe naa sọ fun BBC pe o ṣeeṣe ki awọn ọdọ ọhun ṣe ijamba fun aṣofin naa, ti kii ba ṣe awọn ọlọpaa to wa doola rẹ.

Awọn ọdọ naa sọ pe bo tilẹ jẹ pe aṣofin ọhun lo n ṣoju awọn, awọn ko ri ipa rẹ rara, yatọ si awọn ileri lasan to maa n ṣe ni gbogbo igba.

Iṣẹlẹ naa ko jọ mi loju - Aṣofin

Olori awọn aṣofin lagbegbe Suame ti awọn ọdọ ti le asofin Mensah-Bonsulere, ni iṣẹlẹ ọhun ko jọ oun loju.

O ni kii ṣe aṣofin naa nikan lawọn ọdọ le wu irufẹ bẹẹ si, wọn le ṣe bẹẹ si ẹnikẹni to ba n ṣoju ijọba, ti ko ba mu ileri rẹ fun awọn araalu ṣẹ.

Wayi o, ọpọ awọn ọdọ ni Ghana lo ti sọ pe awọn yoo bẹrẹ si n gbena woju awọn adari awọn ti ko ba mu awọn ileri rẹ ṣe lati asiko yii lọ.