Ìjọba fowó kún epo bẹntiróòlù láti N165 sí N179

Àwòrán ibi tí wọ́n ti ń ta epo bẹntiróòlù

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ó ṣeéṣe kí iye tí wọ́n ń ta epo bẹntiróòlù ti gbówó lórí.

Láti bí ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn ni ọ̀wọ́n gógó epo bẹntiróòlù ti ń wà káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí iye tí àwọn alágbàtà epo sì ń tàá ń yàtọ̀ síra.

Bákan náà ni àwọn ènìyàn lórí ayélujára ti ń kùn yùmùyùmù lórí iye tí wọ́n ń ta epo ní àwọn àdúgbò wọn.

Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn bèèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn lórí ìkànnì Facebook lórí iye tí wọ́n ń ra epo bẹntiróòlù ní agbègbè wọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ṣo wí pé iye owó náà kọjá náírà mẹ́tàdínláàdọ́sàn-án, N167 tí ìjọba ní kí wọ́n máa ta epo.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó kàn sí BBC News Yorùbá láti ìpínlẹ̀ Oyo ní ọgọ́sàn-án náírà, N180 sí òkòlénígba náírà, N210 ni àwọn ń ra epo bẹntiróòlù.

“Ní Saki, ìpínlẹ̀ Oyo #210, #200, #205 ni à ń ra epo bẹntiróòlù lọ́dọ̀ wa.”

Bákan náà ni ọmọ ṣe ṣorí ní ìpínlẹ̀ Eko ati káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Èsì àwọn ènìyàn lórí ìbéèrè BBC
Èsì àwọn ènìyàn lórí ìbéèrè BBC

Ǹjẹ́ èyí kò ti máa fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé ìjọba àpapọ̀ ti fowó lé owó epo bẹntiróòlù báyìí?

Ìròyìn tó ń lọ ni pé àjọ NNPC ti fi lẹ́tà kan ṣọwọ́ sí àwọn alágbàtà epo bẹntiróòlù láti mú àlékún bá owó orí epo.

Iye owó bẹntiróòlù tuntun

Oríṣun àwòrán, WhatsApp

Àjọ tó ń rí sí epo bẹntiróòlù ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, NNPC ti buwọ́lu mímú àlékún bá owó bẹntiróòlù láti náírà mẹ́tàdínláàdọ́sàn-án, N167 sí náírà mọ́kàndínlọ́gọ́sàn-án, N179 lítà kan.

Lónìí, ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Keje ni àmúṣẹ àlékún náà yóò bẹ̀rẹ̀.

Àjọ NNPC nínú ìwé àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí àwọn alágbàtà epo ní kí wọ́n mú àyípadà bá owó tí wọ́n ń ta epo.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí ọ̀wọ́n gógó epo bẹntiróòlù ń wáyé káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí àwọn alágbàtà èpò sì ń ta epo ní iye tó wù wọ́n.

Ní ìpínlẹ̀ Eko oríṣiríṣi iye tó wu àwọn alágbàtà epo bẹntiróòlù ni wọ́n ń tà á.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé epo ló ti mú àlékún bá owó epo wọn ṣaájú àkókò yìí.