Makinde ṣàbẹ̀wò sí Fresh FM iléeṣẹ́ rédíò Ayefele tó jóná, ó ṣèlérí ìrànwọ́

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti ṣabẹwo si Fresh FM Ibadan, ileeṣẹ redio gbajugbaja akọrin ẹmi, Yinka Ayefele, to jona lalẹ ọjọ Ẹti to kọja.
Lasiko abẹwo rẹ ni Makinde ti ṣeleri lati ṣe iranwọ fun ileeṣẹ redio naa ki wọn le maa tẹsiwaju igbohunsafẹfẹ wọn.
Gomina ipinlẹ Oyo ni ileeṣẹ redio Fresh FM n ko ipa pataki nipa gbigbe iroyin gidi jade fun araalu.
''Emi funra mi ati ijọba ipinlẹ Oyo yoo ṣe iranwọ fun ileeṣẹ redio Fresh FM.
Mo fi dá wọn loju pe, a ko ni jẹ ki wọn kuro lori afẹfẹ fun igba pipẹ rara,'' Makinde lo sọ bẹẹ.
Makinde kẹdun pẹlu Ayefele lori dukia ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu to ṣofo nibi ijamba ọhun.
Itaniji ni iṣẹlẹ ijamba Fresh FM jẹ fun ipinlẹ Oyo - Makinde
Gomina ipinlẹ Oyo sọ pe itaniji ni iṣẹlẹ ijamba ina naa jẹ fun ipinlẹ Oyo lori ọna ati wa ojutuu si iṣẹlẹ pajawiri papaa julọ ijamba ina.
Makinde ni oun yoo sọ asọyepọ pẹlu awọn adari ileeṣẹ panapana ipinlẹ Oyo lori ati ro wọn lagbara lati le maa pa iru ina to jo ileeṣẹ redio Fresh FM lọjọ iwaju.
Gomina ipinlẹ Oyo ko ṣai fi idunnu rẹ han pe ẹni kankan ko ba iṣẹlẹ naa lọ.
Gomin ani ''ka ni pe awọn panapana ni irinṣẹ to to ni, wọn o ba lagbara lati pa ina yii.
Ara awọn nnkan ti mo ti ri pe a ni lati ṣiṣẹ lori rẹ niyẹn.
Si awọn alaṣẹ ati atawọn oṣiṣẹ Fresh FM, mo fẹ ki ẹ dupẹ lọwọ Eledua wi pe ko si ẹni to ba iṣẹlẹ naa lọ.''
Ninu ọrọ rẹ, Ayefele dupẹ lọwọ gomina fun abẹwo to ṣe si ileeṣẹ redio rẹ to jona ati ileri iranwọ to ṣe pẹlu.
Bakan naa tun ni gbajugbaja akọrin ẹmi ati pedepede naa tun dupẹ lọwọ gbogbo awọn ololufẹ Fresh FM fun atilẹyin wọn.
Ṣaaju ni agbẹnusọ ileeṣẹ redio Fesh FM, Samson Akindele, fidi rẹ mulẹ pe yara igbohunsafẹfẹ Fresh FM ati ti Blast FM 98.3 jona gan an.
O fikun ọrọ rẹ pe irinṣẹ igbohunsafẹfẹ, yara t'awọn akọroyin ti maa n ṣiṣẹ at'awọn irinṣẹ mere-mere mii naa jona rau rau.
Fresh FM iléeṣẹ́ rédíò Ayefele padà sórí afẹ́fẹ́ lẹ́yìn ìjàmbá iná tó ba dúkìá ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù jẹ́

Yoruba bọ wọn ni bí ẹṣin ba dani, a a tun un gun ni, bayii gan an lọrọ ṣe rí pẹlu Fresh FM ileeṣẹ redio gbajugbaja Olorin ẹmi, Yinka Ayefele, to ti pada sori afẹfẹ bayii lẹyìn ijamba ina to sẹlẹ níbẹ.
Ina ọhun to ṣẹyọ níléeṣẹ́ redio naa ni nnkan bii ago meje abọ alẹ ana ọjọ Ẹtì jo irinṣẹ igbohunsafẹfẹ at'awọn ọpọlọpọ dukia mii rau rau níléeṣẹ́ redio Fresh FM.
Amọ, agbẹnusọ fun Yinka Ayefele àti Fresh FM ti ṣalaye loju opo Instagram ileeṣẹ redio naa wi pe awọn ti bẹrẹ igbohunsafẹfẹ pada.
"Inu wa dun lati kéde wí pé ileeṣẹ redio Fresh FM ti pada sori afẹfẹ lẹyìn ipenija ijamba ina to sẹlẹ lalẹ ana ọjọ Ẹti.
A n fi asiko yii dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ wa, awọn oṣiṣẹ iṣẹlẹ pajawiri to fi mọ awọn ololufẹ Fresh FM fun atilẹyin gbogbo yin.
Ọkan wa ti le sí i lẹyìn ilakọja ijamba ina to sẹlẹ yìí," agbẹnusọ Fresh FM lo sọ bẹẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Iná sọ ní Fresh FM iléeṣẹ́ rédíò Yinka Ayefele, irinṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ jóná ráú ráú, ọ̀pọ̀ dúkìá bàjẹ́
Ina sọ ni ileeṣẹ redio Fesh FM to jẹ ti ilumọọka olorin ẹmi, Yinka Ayefele, niluu Ibadan, o si jo ọpọ irinṣẹ igbohunsafẹfẹ at'awọn dukia mii rau ráú.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ redio Fesh FM at'awọn ileeṣẹ Yinka Ayefele, Samson Akindele, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe lalẹ ana ọjọ Ẹtì ọjọ keedogun oṣu Kẹjọ yìí ni ijamba ina ọhun ṣẹlẹ.
Ọgbẹni Akindele sọ pe "pẹlu ìbànújẹ ọkàn ni a fi n sọ fun gbogbo eeyan pe ijamba ina ṣẹlẹ ní olu ileeṣẹ redio Fresh FM lalẹ ọjọ Ẹtì niluu Ibadan.
Ina naa jo ibi ti a ti maa n gbe orin jade to jẹ ti akọrin ẹmi un ni, Yinka Ayefele, niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo.
Awọn nnkan to wa ninu ile ti ina jo yii to wa ni agbegbe Challenge n'Ibadan ni okowo Ayefele to fi mọ Merry Makers Band ti i ṣe band orin rẹ.
Nibi ile yíì naa ni ileeṣẹ redio Tiwantiwa, Blast FM ati Fresh FM wa."
Ọgbẹni Akindele ṣalaye pe ni nnkan bii ago meje abọ alẹ ni ina ọhun bẹrẹ ti o si da gbogbo eto to n lọ lọwọ lori redio duro.
Agbẹnusọ ileeṣẹ redio Fesh FM ati Yinka Ayefele ni kete ti ina ọhun bẹrẹ lawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ redio naa bẹrẹ sí ni sare kita kita kaakiri pẹlu ibẹru.
O ni bakan naa ni ibẹru-bojo gbalẹ lagbegbe Challenge ti ileeṣẹ redio naa wa.
Awọn nnkan ti ina bajẹ

Oríṣun àwòrán, YinkaAyefele/Facebook
Agbẹnusọ ileeṣẹ redio Fesh FM fidi rẹ mulẹ pe yara igbohunsafẹfẹ Fresh FM ati ti Blast FM 98.3 jona gan an.
O fikun ọrọ rẹ pe irinṣẹ igbohunsafẹfẹ, yara t'awọn akọroyin ti maa n ṣiṣẹ at'awọn irinṣẹ mere-mere mii jona rau rau
"Gbogbo igbiyanju lati pa ina ọhun k'awọn panapana to de, pabo lo jasi tori ina naa pọju.
Ni báyìí, a o tii le sọ pato iye ti dukia to jona le to, bakan naa ni a ko tii mọ ohun tó ṣokunfa ijamba ina ọhun lọwọ lọwọ," Akindele lo sọ bẹẹ.
Akindele ko ṣai dupẹ lọwọ awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria lagbegbe Challenge ti wọn ṣe iranwọ lati pa ina ọhun.
Bakan naa lo tun gboriyin fawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ipinlẹ Oyo fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati pana náà.















