Kí ni àgbékalẹ̀ ibùdó 'E1 Settlement' tí Israel fẹ́ ṣe ní agbègbè West Bank wà fún, èyí tí wọn ló le dúnkokò mọ́ ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Palestine?

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn ero fun iṣẹ akanṣe ipinnu ariyanjiyan eyi ti Minisita eto isuna Israeli, Bezalel Smotrich sọ pe yoo "fopin si ero nipa ilu Palestine" ti fa ọpọ ariyanjiyan.
Eto yii ni wọn n pe ni ibudo E1, o da lori kikọ awọn ilegbe 3,401 ni West Bank - laarin Ila-oorun Jerusalemu ati ibugbe Maale Adumim - o ti di ohun agbeti fun ọdun mẹwaa pẹlu ọpọ itako.
Pupọ awọn eeyan lagbegbe Gaza ka agbekalẹ ibugbe naa si iwa arufin labẹ ofin agbaye, bo tilẹ jẹ pe Israeli jiyan tako eyi.
Minisita feto isuna Israel, Bezalel Smotrich ọrọ nibi ipade kan lori ọrọ West Bank ni Ọjọru.
Smotrich ṣe atilẹyin ero yii, pe ipinnu naa ni "aṣeyọri itan-akọsilẹ".
Ile-iṣẹ to n risi ọrọ oke okun fun ilẹ Palestine ti pe erongba naa ni "afikun iwa ọdaran mọ ipaniyan" - awọn ẹsun Israeli ti kọ fun igba pipẹ.
UN, EU ati awọn orilẹ-ede oriṣiriṣi, bii UK ati Turkey, naa ti bu ẹnu atẹlu erogba fun agbekalẹ ibudo E1, ti wọn si pe fun idaduro lori rẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ki ni ero E1 settlement plan?
Awọn ibugbe jẹ ọkan ninu awọn ohun to n fa ariyanjiyan julọ laarin Israeli ati Palestine.
E1 settilement yii, ni wọn kọkọ dabaa labẹ iṣejọba Yitzhak Rabin ni 1990s, bẹrẹ pẹlu awọn ero akọkọ fun awọn ile 2,500.
Ni ọdun 2004 o gbooro si pẹlu 2,000 pẹlu awọn ohun eto iṣowo ati irin-ajo mii.
Laarin ọdun 2009 ati 2020 awọn ipele tuntun ni wọn sita, pẹlu awọn ohun to n sọ aye dẹrọ ati ọna sise.
Ṣugbọn awọn ero ni ko ki n jẹ sise nitori idunkoko lati ilẹ okeere.

Ki lo de to fi n fa wahala?
Idagbasoke agbegbe E1 ni ọpọ ri gẹgẹ bii idasilẹ ati imunadoko ti ilu Palestine .
Eyi jẹ nitori ipo ati aaye ti E1 wa: o jẹ ohun to ya awọn agbegbe guusu ti Jerusalemu lati ariwa rẹ ati pe yoo ṣe idiwọ bi agbegbe ilu Palestine yoo jasi Ramallah, Ila-oorun Jerusalemu ati Betlehemu.
Gẹgẹ bii ẹgbẹ Israeli Peace Now, eyi ti o ṣe amojuto iṣẹ ṣiṣe ni West Bank ti wi, awọn ile tuntun lo jẹ aṣoju ida 33% idagbasoke ni ibugbe Maale Adumim, eyiti o ni olugbe to jẹ 38,000, ti wọn n gbe ibẹ lọwọlọwọ.
Ki lo wa ni West Bank?

Oríṣun àwòrán, Reuters
West Bank jẹ ilẹ kan to wa laaarin Israel ati odo River Jordan ati ile fun o le ni milọnu mẹta ọmọ ilẹ Palestine.
O wa pẹlu ila oorun Jerusalem ati Gaza, abala kan ibi ni wọn mọ si aaye awọn ọmọ ilẹ Palestine.
O le ni 160 ibugbe to jẹ Israel to wa ni ibẹ, to tun jẹ ile fun 700,000 Jews ni West Bank ati Ila oorun Jerusalem.
Awọn ọmọ ilẹ Palestine ma tako bi Israel se wa ni awọn agbegbe yii. Israel si ni agbara gbogbo agbegbe West Bank, ṣugbọn lati ọdun 1990s, ijọba Palestine kan, ti wọn n pe ni Palestinian Authority- kọlu ọpọ ninu awọn ilu ati agbegbe naa.
Lati igba ikọlu Hamas ni Ọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2023, ikọlu Israel si awọn agbegbe West Bank to jẹ ti Palestine ti di lemọlemọ.
Ni Oṣu kẹfa, ajọ UN ṣe akọsilẹ ifarapa awọn ọmọ ilẹ Palestine to pọju laarin ọpọ ọdun.
Orilẹede Palestine ati ajọ ajafẹtọ ọmọniyan ti fẹsun kan Israel pe wọn kuna lati da bobo awọn eeyan, ti wọn si tun ṣe ọpọ ijamba.
Awọn ọmọ ilẹ Palestine fẹ ki Israel ko ni gbogbo ibugbe naa nitori wọn ri West Bank ati Palestine gẹgẹ orilẹede ominran laipẹ.
Ẹwẹ, ijọba Israel ni ko ri ẹtọ ni Palestine ni lati le da wa, ti wọn tẹnu mọ pe ara Israel ni West Bank jẹ.
Ni ọsu keje ọdun 2024, ile ẹjọ UN, ICJ ni bi Israel se wa ni agbegbe West Bank lo jẹ ohun to lodi si ofin, pe ki wọn si kuro ni agbegbe naa kiakia.
Olootu ijọba Israel fesi pada pe idajọ ile ẹjọ kun fun ọpọ irọ.
"Awọn ara Jew ko lo ni ilẹ, ki se ni olu ilu Jerusalem, tabi ni Judea ati Samaria [to jẹ West Bank]", Netanyahu sọ ninu atẹjade kan.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ki ni ero agbaye lori E1?
Lẹyin ikede rẹ lori ero naa, Smotrich dupẹ lọwọ Aarẹ US, Donald Trump ati Ambassador Mike Huckabee fun atilẹyin wọn, o fi idi rẹ mulẹ pe, ni oju rẹ, West Bank jẹ " ilẹ ileri Ọlọrun ti ko ṣe gba lọwọ Israel".
O tun sọ pe Olootu Ijọba Israel, Benjamin Netanyahu ṣe atilẹyin awọn ero rẹ lati mu awọn olugbe titun ti wọn jẹ miliọnu kan wa si West Bank.
Ileeṣẹ to n risi ọrọ oke okun ni Palestine bu ẹnu atẹlu ero E1, to si pe ikọlu si isọkan ile Palestine ati idunkoko si idasilẹ ilẹ ominira ilẹ Palestine.








