Oriyomi Hamzat tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Naira Marley lórí ìgbésẹ̀ rẹ̀ nípa ikú Mohbad

Aworan Oriyomi Hamzat to fi igo soju, pẹlu Naira Marley to ṣe irun dada sori, to si fi ẹgba ọrun nla sọrun, o kawọ rẹ mejeeji mọ igba aya rẹ.

Oríṣun àwòrán, @Oriyomi Hamzat Facebook/ Naira Marley/Facebook

Àkọlé àwòrán, Oriyomi Hamzat ati Azeez Fashola (Naira Marley)
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajumọ agbohunsafẹfẹ ni Ibadan, Oriyomi Hamzat, ti tọrọ aforiji lọwọ olorin taka-sufee nni, Azeez Fashola tawọn eeyan mọ si Naira Marley.

Aforiji ti Oriyomi tọrọ lọwọ Naira Marley ko ṣẹyin awọn ọrọ to sọ ati igbesẹ to gbe lori iku IleriOluwa Aloba, Mohbad, nigba ti Mohbad ku lojiji ni 2023.

Lasiko to n tọrọ aforiji naa lori ileeṣẹ redio rẹ niluu Ibadan lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹjọ ọdun 2025, Oriyomi fi kun un pe, oun tun ti gbẹsẹ kuro lori ofin to de lilo orin Naira Marley lori redio Agidigbo.

Tẹ o ba gbagbe, ọkan lara awọn alẹnulọrọ to koro oju si iku Mohbad, ti wọn si ṣiju le Naira Marley ti ijọba pe lẹjọ lori iku rẹ ni Oriyomi Hamzat.

Gẹgẹ bi Oriyomi ṣe wi:

"Ma binu ọrọ buruku ti mo sọ si ọ o.

Ni bayii, nileeṣẹ Redio Agidigbo, awa naa ti gbẹsẹ, a ti tẹ Esu mọlẹ o.

Lati oni lọ, a le maa lo orin Naira Marley.''

Bi Oriyomi ṣe sọrọ naa tan lo ju orin Naira Marley kan sori afẹfẹ.

O ni bi oun ko ba kọkọ lo o bẹẹ, ti oun ni ki awọn ọmọ iṣẹ oun maa lo o, yoo da bii pe oun fun wọn ni igbo didi ṣan ni."

Aworan Mohbad. O wọ aṣọ awọtẹlẹ funfun, o si de fila dudu.

Oríṣun àwòrán, MOHBAD

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Ilerioluwa Aloba (Mohbad)

Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú tí Oriyomi ṣe ní kí wọn máṣe lo orin Mohbad?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iku Mohbad to waye lọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an ọdun 2023 di ariwo, paapaa fun Naira Marley ati awọn ikọ rẹ ti wọn jọ n gbe orin jade nileeṣẹ olorin Naira Marley.

Wahala naa lo fa a ti ero rẹpẹtẹ to n tẹle Naira Marley lẹyin loju opo ayelujara fi pada.

Ọrọ yii kan naa lo fa a ti Naira Marley fi dero kootu ati ero ẹyin gbaga.

Bo si tilẹ jẹ pe kootu pada yọnda rẹ lori ẹsun naa, oju apa ko jọ oju ara fun un lagbo orin taka sufee mọ.

Lara awọn eeyan to fi ohun ti wọn ni ja fun ẹtọ Mohbad nigba naa ni Oriyomi Hamzat to gbajumọ ninu iṣẹ igbohunsafẹfẹ.

Lasiko kan ni 2024, Oriyomi paṣẹ pe wọn ko gbọdọ lo orin Naira Marley lori redio oun mọ.

Bakan naa lo si fi ohùn ẹnu rẹ kede aidunnu rẹ si Naira Marley ti gbogbo eeyan n naka aleebu si, pe o lọwọ ninu iku Mohbad.

Ṣugbọn lojiji, Oriyomi yi ohùn pada, o tọrọ aforiji lọwọ Azeez Fashola, o si tun gbe òté kuro lori orin rẹ.

Igbesẹ yii ni ọpọ eeyan ṣi n beere, pe ki ni Oriyomi Hamzat ri to fi di ọrẹ Naira Marley lojiji.