Kàyééfì ńlá! Ìyàwó àṣẹ̀ṣẹ̀gbé po òògùn ekú mọ́ oúnjẹ f'ọ́kọ

Aworan ojiji ọwọ kan to fẹ mu igo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Iyawo aṣẹṣẹgbe kan ti po ogun eku mọ ounjẹ fun ọkọ rẹ eyi to ran an lọ si ọrun alakeji.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ peọwọ ti tẹ obinrin iyawo ọṣingin naa ni ilu Gauza, ni ipinlẹ Jigawa lẹkun ariwa orilẹede Naijiria.

Gẹgẹbi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ, nnkan bii agogo marun un irọlẹ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtalelogun oṣu kinni ọdun 2026.

Arabinrin naa ni bi awọn obi oun ṣe fipa mu oun lati fẹ arakunrin naa lo ṣokunfa bi oun ṣe kuku pinnu lati gbẹmi rẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Jigawa, SP Adam ṣalaye pe nigba ti wọn yoo fi gbe ọkọ iyawo tuntun naa digbadigba de ileewosan, ẹmi bọ lara rẹ lasiko ti wọn n fun un ni itọju nibẹ.

Awọn ọlọpaa ni iyawo arakunrin to doloogbe naa ṣalaye lasiko ifọrọwanilẹnuwo lagọ ọlọpaa pe "oun po ogun eku mọ ounjẹ fun ọkọ oun ni."

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye siwaju sii pe, arabinrin naa jẹwọ pe aburo oun kan loun ran lati lọ ra ogun eku naa.