Lẹ́yìn-ò-rẹyìn, ebí Bunmi Akinnaanu 'Omije Ojumi' kéde ọjọ́ tuntun fún ìsìnkú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Sammy Daodu/Bunmi Akinnaanu Adeoye
Lẹyin ti wọn ti kọkọ wọgile ilana etoisinku gbajumọ akọrin ẹmi Bunmi Akinnaanu ti ọpọ mọ si Omije Ojumi, awọn mọlẹbi rẹ ti kede ilana isinku tuntun fun un.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹtala, oṣu Kinni, ọdun 2026 ni iroyin gbode pe Bunmi Akinnaanu Adeoye ti ọpọ mọ si omije ojumi ti jade laye.
Bawo ni ilana isinku Omije Ojumi yoo ṣe lọ?
Eto aṣalẹ orin onigbagbọ ni yoo ṣaaju lọjọru ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kinni ọdun 2026 gẹgẹbi atẹjade ti ẹbi fi sita.
Lẹyin eyi ni eto aṣaalẹ idaro ti wọn n pe ni 'Candle night' yoo waye laarin agogo mẹfa irọlẹ si mẹjọ alẹ.
Bakannaa, lasiko yii naa lawọn akọrin atawọn ọrẹ yoo tun korajọpọ lati ṣe aṣaalẹ ẹyẹ fun un lọjjọru yii kan naa.
Ni Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn ni wọn yoo sin oku rẹ.
Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?

Oríṣun àwòrán, Bunmi Akinnaanu Adeoye
Ṣaaju ni obinrin naa ti kọkọ dubulẹ aisan fun ọjọ pipẹ ti awọn akẹgbẹ rẹ nidi iṣẹ orin ẹmi si n fi adura ran an lọwọ.
Lọdun to kọja ni fidio kan jade, nibi ti olorin ẹmi ọhun ti joko sori aga kan ti ẹsẹ rẹ mejeji si wu ti wolii kan si n gbadura fun iwosan rẹ.
Lẹyin naa ni awọn ololufẹ rẹ ko gbọ nnkankan mọ titi di asiko ti iroyin iku rẹ gba igboro kan yii.
Ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ, ololufẹ ati ọrẹ rẹ lo ti ṣedaro rẹ lori ayelujara, koda awọn kan
gan an tilẹ tẹsiwaju pẹlu eto idagbere ti wọn lati yẹ oloogbe naa si ni ilu Ilọrin













