Fún ìgbà àkọ́kọ́, Naira Marley sọ̀rọ̀ lórí ikú Mohbad àti ìbáṣepọ̀ wọ́n nígbà ayé rẹ̀

Oríṣun àwòrán, NAIRA MARLEY/TWITTER, MOHBAD/INSTAGRAM
Gbajugbaja olorin takasufe, Azeez Fashola, ẹni ti ọpọ mọ si Naira Marley ti sọrọ sita lẹyin idajọ ile ẹjọ Majisireeti to da oun ati awọn mii lare pe, wọn ko mọ ohunkohun nipa iku Ilerioluwa Aloba, ẹni ti ọpọ mọ si Mohbad.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji, ni ile-ẹjọ da awọn eeyan naa lare.
Ninu ọrọ to gbe soju opo X l'ọjọru, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2025, Marley ni pẹlu bi ede-aiyede ṣe wa laarin oun ati Mohbad nidba aye rẹ, awọn ti yanju rẹ saaju ko to ku.
Bakan naa ni Naira Marley kọminu lori bi iṣẹlẹ naa se waye paapa bi wọn ko se ti i oku sin Mohbad ati awọn nnkan mii to yi iku rẹ ka.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
"N ko mọ pe didakẹ le pariwo to bayii. N ko lero pe ẹni ti mo pe ni arakunrin mi, ti mo n daabo bo, yoo fi aye silẹ, ti yoo si sọ orukọ sinu okunkun iku rẹ. Mo n gbe ẹru wuwo yii, inira ati idojutini ti ki n se ti temi rara.
"Awa Marlians ni asise ti wa, a mọ a ni lati tẹsiwaju
"Asise wa ṣugbọn okoowo ni ki se ogun. Mo ti pari ija pẹlu Mohbad. Ọrọ wa ye ara wa ju gbogbo ariwo ati ede-aiyede. Ti oun gan-an si mọ eyi.
"Nigba ti Mohbad jade laye lọwọ rẹ, o wo gbogbo eeyan, emi lo naka si. O jẹ ki wọn ya mi pẹrẹpẹrẹ. O jẹ ki wọn pe mi ni apaayan, to si mọ otitọ. Ni bayii, o wa n sọ itan?
Mo gba ẹ sinu ile mi. Mo fun ẹ ni igbagbọ mi. Ṣugbọn sibẹ, arakunrin mi ti lọ, wọn o dẹ ti sin, gbogbo eyi lo jẹ ẹbi rẹ. Ka ni pe o ti sọ otitọ lati ibẹrẹ, ko ba ti gba isinmi to yẹ bayii. Sibẹsibẹ, maa ṣi maa ṣe atilẹyin rẹ̀.
Bo tilẹ jẹ pe Naira Marley ko sọ orukọ ẹni to n fi ẹsun kan, o ni ọpọ lo ro pe oun yoo salọ tabi pe oun ko nii la akoko naa kọja lai farapa.
"Ṣugbọn mo duro ti idajọ ododo, mo lo asiko diẹ ni ẹwọn.
"Ọlọrun ri gbogbo ẹ pata. Otitọ yoo farahan, irọ yoo parẹ laipẹ.
"Mo ri ijakulẹ ṣugbọn mi o jakulẹ. Nigba ti otitọ ba jade, mo gba adura pe ki o ni ọkan lati gba a."
Ọrọ yii jade lẹnu Naira Marley lẹyin idajọ Ile-ẹjọ Majisireeti, ti ile-ẹjọ si tun ṣalaye ohun pato to ṣokufa iku oloogbe naa.
Ninu iwe ti ile-ẹjọ gbe sita fun awọn akọroyin, lo ti han pe ninu oṣu Kẹsan an, ọdun 2023, Mohbad ati ọrẹ rẹ, Adeyemo Boluwatife, ti wọn pe ni Darosha, pẹlu Wunmi, iyawo Mohbad ati Primeboy to jẹ ọrẹ oloogbe, pẹlu dẹrẹba wọn Fedelis Esandor ati awọn mii lo tẹle Mohbad lọ si agbo orin ti Sobrekon gbe kalẹ ni Ikorodu.
Nigba ti wọn fẹ kuro, Primeboy gbiyanju lati da Mohbad duro nitori awọn ọmọ ita to wa ni agbegbe naa.
Ile-ẹjọ ni ọrọ naa bi Mohbad ninu, to si nawọ ẹsẹ si Primeboy ṣugbọn Primeboy ko ba ja pada.















