Ó nira láti bá ìjọba tó wà lóde báyìí ní Naijiria sọ òtítọ́ - Makinde

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/X
Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti sọ pe o nira lati sọ otitọ fun ijọba wa lode bayii lorilẹede Naijiria.
Nigba to n sọrọ lopin ọsẹ to kọja niluu Ibadan, Makinde sọ pe ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari si leti to fi n gbọrọ ju ijọba Aarẹ Bola Tinubu to wa lode yii lọ.
Makinde fidi ọrọ yii mulẹ nibi akanṣe eto kan eyi ti oniruuru alẹnulọrọ lagbo oṣelu to fi mọ Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo, wa nibẹ.
Gomina ipinlẹ Oyo ni ''eeyan o le ba ijọba to wa lode yii sọ otitọ.
Lori ọrọ ofin owo ori, a sọ fun wọn pe ki wọn gbe e wa ki a jọ wo o daadaa, amọ, wọn kọ eti ikun.
Wọn ni ko si nnkan to le da ofin owo ori tuntun naa duro.
Nnkan abuku lo jẹ pe awọn gomina ko mọ nnkan to wa ninu ofin owo ori tuntun ti ile aṣofin fọntẹ lu.
A o mọ nnkan ti ofin owo ori tuntun ọhun da le lori, a o mọ nnkan ti aarẹ buwọlu.
A n ṣafẹri Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ Yemi Osinbajo - Makinde
Gomina Seyi Makinde tun sọ pe oun n ṣafẹri Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo papaa julọ lori idari rẹ nipa ọrọ aje.
Makinde ni Igbakeji Aarẹ tẹlẹ lo gba pẹlu oun lori igbesẹ ijọba ipinlẹ Oyo lati ma kede ofin konle o gbe lasiko ajakalẹ arun Covid-19.
Ti ẹ o ba gbagbe, Osinbajo ni alaga ajọ NEC to n ri si ọrọ aje Naijiria lasiko ti ajakalẹ arun covid-19 bẹ silẹ.
'Ko tii ju oṣu meje ti mo de ipo gomina lọ ti ajakalẹ arun covid-19 bẹ silẹ ni Naijiria.
Ajọ NEC ti ijọba apapọ gbe kalẹ lati ṣiṣẹ lori ọrọ aje ṣe ipade to lamilaaka eyi ti alaga ajọ naa, Ọjọgbọn Osinbajo, emi atawọn gomina mii wa nibẹ.
Nibi ipade yii ni a ti fẹnu ko pe kawọn gomina lọ kede konle o gbele lawọn ipinlẹ wọn tori ajakalẹ arun covid-19.
Emi ni n ko jẹ ki ofin konle o gbele wa nipinlẹ Oyo nigba naa tori igbesẹ ti mo gbe, eyi ti Igbakeji Aarẹ tẹlẹ gba pẹlu mi.
Emi gẹgẹ bi ẹnikan n ṣe afẹri Ọjọgbọn papaa julọ pẹlu ipa ti wọn ko ninu igbimọ NEC to n ri si ọrọ aje Naijiria,'' Makinde lo sọ bẹẹ.















