Àlàyé rèé lórí bí wọ́n ṣe mú Muslim Yusuff, ọmọ olórí tó dá Boko Haram sílẹ̀ ní Nàíjíríà

Oríṣun àwòrán, Zagazola Makama/X
Ẹkunrẹrẹ iroyin ree nipa bi ọwọ awọn ẹsọ alabo Chad ṣe tẹ Muslim Muhammad Yusuf, ọmọ olori ikọ agbebọn Jama'atu Ahlis-Sunna Lidda'Awati Wal-Jihad ti ọpọ mọ si Boko Haram ni Naijiria.
Ọwọ tẹ Muslim Yusuf pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ mẹrin miiran, ti wọn fura si pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ naa, gẹgẹ bii Zagazola Makama, oluwadii lori awọn iṣẹ Boko Haram ni adagun Chad ṣe sọ.
Makama sọ pe awọn alaṣẹ orilẹ-ede Chad ti mu Muslim Mohammed Yusuf lai mọ idanimọ otitọ rẹ, ṣaaju ki ileeṣẹ ologun alajumọse ni Naijiria Nigerian (MNJTF) to koju Boko Haram to kan si wọn.
Iwadii fihan pe Muslim - ẹniti o jẹ aburo si oludari ISWAP Habib Yusuf, ti ọpọ tun mọ si Abu Mus'ab Al-Barnawi - jẹ oludari awọn onija ẹsin ni Chad, ti o ti n ṣe ikọlu ni orilẹ-ede naa fun igba diẹ.
'Muslim kere nigba ti Boko Haram n se ikọlu'
Ẹri fihan pe Muslim Mohammed Yusuf jẹ ọdọmọkunrin nigba ti awọn ologun Naijiria ṣekupa baba rẹ lẹyin ti ọwọ tẹ nibi to ṣa pamọ si.
Amofin Audu Bulama Bukarti to jẹ onimọ nipa eto aabo ni awon orile-ede Afirika sọ pe nigba ti Boko Haram n dide, Muslim je omodekunrin ti ko mo nkankan.
O fi kun un pe orukọ rẹ kii ṣe orukọ ti ọpọ mọ daradara, bo tilẹ jẹ pe iyẹn ko ni ibatan si lilo apeso kan, Bukarti sọ.
"Ti o ba wo orukọ ti wọn mu pẹlu, orukọ kan ti o dabi ọmọ Chad, ati pe ko ṣe iyalẹnu pe o ṣe lati tan awọn eniyan jẹ," o sọ.
Onimọ nipa eto aabo naa tesiwaju pe eleyii je ki oruko oun jẹ nnkan ti ọpọ ko mọ ninu egbe Boko Haram.
"Nigba ti Boko Haram bẹrẹ ija ni ọdun 2009, fidio Mohammed Yusuf kan ti n kaakiri pẹlu ọmọdekunrin kan ti ko dagba ju ọdun marun-un - ninu eyi ti wọn gbọ pe o n waasu ni ede Larubawa ti o nfi awọn eniyan ni alaigbagbọ - ko jẹ iyalenu pe ọmọdekunrin naa niyi," Bukarti sọ.
Bukarti sọ pe Mohammed Yusuf ni ọpọlọpọ awọn ọm, ati pe ọpọlọpọ ninu wọn jẹ ọkunrin.
"Ọpọlọpọ awọn ọmọ rẹ ọkunrin, paapaa akọbi, Habib, inagijẹ Abu Mus'ab Al-Barnawi, ko ipa pataki ninu awọn iṣẹ ti ẹgbẹ Boko Haram."
Abu Mus'ab Al-Barnawi ni iyato nipa erongba pelu olori egbe Boko Haram, Abubakar Shekau, koda o ti kuro ninu egbe naa, lọ darapọ pẹlu ẹgbẹ musulumi mii.
Lẹyin to darapọ ni wọn fi jẹ olori ni Iwọ oorun Afrika.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ipo wo ni Muslim di mu ninu ẹgbẹ ISWAP?
Amofin Audu Bulama Bukarti sọ pe alaye tọka si pe Muslim Muhammad Yusuf ni olori ISWAP ni Chad.
Onimọ nipa eto aabo sọ pe bo tilẹ jẹ pe wọn ko mọ orukọ rẹ gaan, gẹgẹ bi olori ISWAP ni Chad, wọn le sọ pe o lọwọ ninu awọn ikọlu ti ẹgbẹ naa ṣe ni orilẹ-ede naa.
Ki ni o tumọ si ninu gbigbe ogun tako ISWAP?
Amofin Bukarti sọ pe bi ọwọ ṣe tẹ Muslim jẹ iṣẹgun nla fun awọn ologun ti agbegbe Lake Chad ti wọn koju ikọ agbebọn ISWAP ati Boko Haram.
O tun sọ pe eyi fihan pe awọn ologun aabo Naijiria ati Chadi ti bẹrẹ lilo awọn ilana akojọpọ oye.
"Ti e ba wo itan Boko Haram, yato si Muhammad Yusuf, ko si olori pataki kan ti won ti mu laaye."
"Nitori naa lonii, ti wọn ba sọ pe wọn ti mu ebi Muhammad Yusuf laaye, ati ni Naijiria, awọn aṣaaju Ansaru meji ni wọn laaarin ọjọ repeteipẹ, o yẹ ka gbe oriyin fun awọn agbofinro, ka gba pe wọn ti bẹrẹ lilo oye," Bukarti sọ.
Onimọ nipa eto aabo tun so wi pe bi wọn ṣe mu Muslim yoo mu irẹwẹsi ọkan ba awọn yooku.
"Ti wọn ba ri ọkan ninu awọn olori ti o ga ju mu, wọn le bẹru, tiiberu yoo wọ inu ọkan wọn.," ni amoye aabo sọ.
O fi kun pe bi wọn ṣe mu yii tun le da ẹgbẹ naa ru, paapaa ti o ba jẹ fun igba diẹ.
"Nitori pe awọn ija olori wa nigba ti wọn ba mu ọkan ninu awọn aṣaaju tabi pa, ati nigba miiran iyẹn yoo jẹ ki awọn miiran ṣubu, eyiti yoo jẹ ki ẹgbẹ naa padanu itọsọna," o sọ.















