Àgbà ọba ni Alaafin àti Ooni, àwọn oníròyìn ló ń gba ọ̀rọ̀ yìí bíi ẹni gba igbá ọtí- Olugbon

Aworan Oba Abimbola Owoade, Alaafin ti Ilu Oyo ni asọ funfun ati Oba Adeyeye Ogunwusi, Ooni ti ile Ife, ti oun naa wọ aṣọ funfun.

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Olugbọn ti ile Igbọn ni ipinlẹ Osun, Oba (Ọmọwe) Francis Olushola Alao ni pupọ ohun to fa rogbodiyan to bẹ silẹ laarin Alaafin ti ilu Oyo ati Ooni ti ilu ile ife lo jẹ pe o wa lati ọwọ awọn oniroyin.

Oba Olushola Alao lasiko to n ba BBC sọrọ jẹ ko di mimọ pe oun sunmọ awọn Ọba alade mejeeji yii, to si jẹ pe awọn mejeeji n da abo bo agbegbe ati itẹ wọn ni.

"Awọn oniroyin lo n gba a bi igba ọti. Onikaluku fẹ da abo bo itẹ wọn ni. Emi ju eyi lọ to n waye lo jẹ aifagbafagba ni ko jẹ ki aye gun."

Olugbon ni nnkan pato ti oun fẹ ko di mimọ ni pe agba ni awọn ọba alade mejeeji, to si pe fun suuru lasiko yii.

"Ati Ooni, ati Alaafin, ki onikaluku ni suuru, nnkan ti mo le sọ niyen."

Oba Olushola Alao ni suuru lo ṣe koko lasiko yii laarin awọn ọba mejeeji.

"To ba to akoko, awọn agbagba yoo da si ṣugbọn bayii, ẹ sinmi ariwo."

Agbẹnusọ Alaafin lo fẹ da wahala silẹ – Amofin Oladotun Hassan

Aarẹ igbimọ apapọ Yoruba lagbaye, Amofin Ọladọtun Hassan ni pupọ ohun to fa rogbodiyan to bẹ silẹ laaarin Alaafin ti ilu Oyo, Oba Abimbola Owoade ati Ooni ti ilu Ile Ifẹ, Oba Adeyeye Ogunwusi lo wa lati ọwọ agbẹnusọ Alaafin, Bode Durojaye to gbe atẹjade sita.

Haasan fẹsun kan agbẹnusọ fun Alaafin naa pe ẹta inu rẹ gẹgẹ bii ẹni to ti ṣe iṣẹ tẹlẹ fun Alaafin ana, Oba Lamidi Adeyemi lo gbe sita, ki ṣe ero Alaafin ti ilu Oyo.

O ni gbogbo agbaye lo mọ pe Ile Ife ni orisun, to si jẹ pe Ooni lo ni ilẹ.

"Agbẹnusọ Alaafin, Bode Durojaye, ti wọn ran ni iṣẹ ẹru ti ko fi ti ọmọ jẹ, to si jẹ gẹgẹ bii ẹni ti ko bọwọ fun agba.

"Gẹgẹ bi ẹni to ti ṣiṣẹ pẹlu Alaafin ana, Baba Adeyemi, to si tẹsiwaju pẹlu Ọba Ọwọade, Pẹlu iriri Bode Durojaye, ko yẹ ko gbe irufẹ ọrọ yii sita.

"Ilana ti awọn Ọba ma fi n paroko si ara wọn wa, ti ko yẹ ko jẹ ọrọ ita gbangba, ṣugbọn agbẹnusọ ba ọrọ jẹ.

"Olori Ọba alade ni Ooni ti ilu ile ife. Ipo olori ni Ooni jẹ. Ooni ki n ṣe Ọba ti a n tabuku si ni ita gbangba. Emi a fi abuku yii kan Bode Durojaye nitori ko fi imọ ati eto ilẹ Yoruba gbe ọrọ sita.

"Ilu Ija ni Bode Durojaye lu, to si jẹ pe ero ọkan ti ẹ lo gbe sita."

A fun Bode Durojaye ni wakati mejidinlaadọta lati tuba fun Ooni

Aarẹ apapọ ẹgbẹ Yoruba lagbaye ni awọn ti fun agbẹnusọ Alaafin, Bode Durojaye ni wakati mejidinlaadọtaa lati tọrọ aforijin lọwọ Ooni ati gbogbo ọmọ Yoruba.

Hassan ni o tun ṣe koko ki ohun Alaafin tẹle ofin aforijin Bode Durojaye pe ko si wahala laarin wọn pẹlu Ooni ti ilu ile ife.

"Gẹgẹ bii wọn ti ṣe sọ saaju ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC pe ko si wahala laarin Alaafin pẹlu Ooni, wọn tun ni lati sọ bẹẹ lati fihan pe ko si wahala,"

Ipa wo ni irufẹ iṣẹlẹ yii le ko fun ilẹ Yoruba?

Aworan Oba Abimbola Owoade, Alaafin ti Ilu Oyo ni asọ funfun ati Oba Adeyeye Ogunwusi, Ooni ti ile Ife, ti oun naa wọ aṣọ funfun.

Oríṣun àwòrán, BBC/OONI PALACE

Oba Olushola Alao ni nnkan to n ṣẹlẹ yii ko ni fa iyapa laarin Ilẹ Yoruba.

O fidi rẹ mulẹ pe iṣẹlẹ yii yoo kọja lọ, ti alaafia yoo si tunbọ tẹsiwaju ni ilẹ Yoruba ṣugbọn lọwọ yii ki onikaluku lọ ṣe suuru.

"Isọkan wa laarin wa, eyi ko le fa iyapa laarin wa. Nnkan to n waye laarin awọn ọba meji ko le wa fa wahala laaarin wa.

"Ile Yoruba ko le tuka, isọkan wa laarin wa. Alaafin si n jọba kaakiri.

"Ile Yoruba ko le bajẹ rara. Mo ti bẹ ọtun ati osi ki wọn jẹ eburẹ."

Amofin Hassan ni irufẹ iṣẹlẹ yii ti ṣe akoba nla ṣaaju fun iran Yoruba lasiko awọn Awolowo.

Sugbọn igbimọ apapọ Yoruba lagbaye ni o ṣeeṣe koko ki irẹpo wa laarin awọn Ọba alade mejeeji.

"Ifẹ ni etutu isọkan ilẹ Yoruba. A ni lati ni ifẹ ara wa pẹkipẹki gẹgẹ bii ọmọ Yoruba."

Ki lo sẹlẹ ṣaaju?

Oye kan ni a gbọ pe Ooni Ile Ife; Ọba Adeyeye Ogunwusi, fi gbajumọ oniṣowo, Dotun Sanusi, jẹ, ti a si tun gbọ pe Alaafin Oyo, Oba Abimbola Owoade, fun Ọọni ni ọjọ meji lati gba oye naa pada.

Yatọ si pe orukọ oye ọhun n da ariyanjiyan silẹ, ti awọn kan n sọ pe Ọkanlọmọ ilẹ Yoruba ni Ọọni fi Sanusi jẹ, ti awọn mi-in si tun ni Ọkanlọmọ Oodua ni, ohun to tun n fa ẹjọ ni atẹjade kan to ti Aafin Oyo wa lori Oye naa.

Ninu atẹjade naa ti Akọwe iroyin Alaafin Owoade, Bode Durojaiye, fi sita lo ti ni afojudi lo jẹ fun Ile Ife lati da nikan fi eeyan jẹ oye to ni i ṣe pẹlu gbogbo ilẹ Yoruba, iyẹn Okanlọmọ Ilẹ Yoruba.

Atẹjade naa sọ pe Alaafin Oyo nikan lo lẹtọọ lati fi eeyan jẹ oye to ba ti kan ilẹ Yoruba lapapọ.