Israel yin àdó ikú mọ́ ikọ Hamas tó wà ní Doha, èèyàn mẹ́fà pàdánù ẹ̀mí
- Author, Luis Barrucho
- Role, BBC Global Journalism
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Ado oloro Israel to bu gbamu pẹlu erongba lati ṣekupa awọn olori Hamas ni Doha lorilẹede Qatar, ti di tọrọfankale.
Awọn amoye sọ fun BBC pe igbesẹ naa le ṣe akoba nla fun idaduro ogun ni Gaza, ko si tun ba ajọsepọ to wa ni awọn orilẹede ni apa Middle East ati orilẹede Amẹrika jẹ.
Israel ṣapejuwe ikọlu ọhun, to waye ni ile itaja kan ni aarin gbogbo Doha, nibi ti awọn sọrọsọrọ Hamas ti n jiroro, gẹgẹ bii ọna lati gbẹsan.
Gẹgẹ bii Olootu ijọba Israel, Benjamin Netayahu ṣe ṣalaye, o ni ikọlu naa jẹ igbesẹ lati gbẹsan ikọlu to waye ṣaaju ni Jerusalam.
Eeyan mẹfa ti wọn jẹ ọmọ Israel lo padanu ẹmi wọn ninu ikọlu Jerusalem naa, to si tun ni eikọlu naa tun wa lati gbẹsan ipa ti Hamas ko ninu ikọlu Ọjọ keje Oṣu Kẹwaa ọdun 2023.

Oríṣun àwòrán, Jacqueline Penney/AFPTV/AFP via Getty Images
Ikọ ologun Palestine Hamas ti ni eeyan marun un padanu ẹmi wọn lasiko ti Israel ju ado oloro si Doha, to jẹ olu ilu fun orilẹede Qatar ṣugbọn gbogbo erongba lati ṣekupa awọn sọrọsọrọ wọn forisanpọn.
Hamas ni ikọ sọrọsọrọ wọn n ṣe ipade lọwọ lori ohun ti orilẹede Amẹrika gbe wa pe ki wọn ju ọwọ ogun silẹ ni ile kan ni Doha nigba ado oloro bu gbamu.
Olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu ni ikọlu naa ṣe koko nitori o fẹ gba emi awọn olori ogun Hamas to lewaju ikọlu to waye ni ọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2023, eyi ti wọn ti kọlu Israel, to ṣokunfa ogun Gaza.
Qatar bu ẹnu atẹlu ikọlu naa, to si ṣapejuwe ikọlu gẹgẹ bii ti ojo, to si tun tako ofin agbaye.

Ileeṣẹ ijọba Amẹrika ni Aarẹ orilẹede naa, Donald Trump gbagbọ pe ikọlu naa ba ni lọkan jẹ ṣugbọn fifi opin si Hamas jẹ ohun ti wọn n le bayii.
Qatar jẹ alabaṣepọ US, to si ti n gba alejo awọn oloṣelu Hamas lati ọdun 2012.
Awọn oṣojumikoro ni Doha ni awọn gbọ iro ado oloro ni igba mẹjọ ọtọọtọ ni ọsan ọjọ Isẹgun, ti eefin si gba gbogbo ofurufu ni ariwa Katara.
Ikọlu yii kọlu ọpọ ile ni agbegbe naa paapa ile ti ọpọ awọn oṣelu Hamas n wa, gẹgẹ bii awọn alaṣẹ Qatar ṣe ṣalaye.
Israel fi atẹjade sita lẹyin ibugbamu ọhun

Oríṣun àwòrán, Menahem Kahana/AFP via Getty Images
Laarin isẹju diẹ, orilẹede Israel kede pe awọn ni awọn wa lẹyin ikọlu naa.
Ileeṣẹ ologun ati Shin Bet ninu atẹjade ti wọn jọ buwọlu fi sita fidi rẹ mulẹ pe wọn ju ado oloro naa lati ṣekupa awọn olori ikọ ogun Hamas.
Nigba to ya, Netanyahu ati minisita ologun Israel Katz ni awọn ti gbe aṣẹ kalẹ fun ileeṣẹ ologun lọjọ Aje pe ki wọn gbaradi fun ikọlu "lẹyin ọpọ ikọlu ni Jerusalem ati Gaza"- iṣekupa ọmọ Israel mẹfa lati ọwọ awọn agbebọn Palestine meji ni Jerusalem ati iṣekupa awọn ologun Israel mẹrin ni ibudo awọn ologun ni Gaza.
"Olootu ijọba ati minisita ologun gbagbọ pe igbesẹ wọn lati ṣe ikọlu naa ṣe koko pẹlu bii o ti jẹ pe awọn olori Hamas lori gbe ero kalẹ lati kọlu Israel lọjọ keje oṣu Kẹwaa, nibi ti ọpọ eeyan ti padanu ẹmi wọn, ti wọn ko si dẹkun sisọ ado oloro si orilẹede Israel ati agbegbe rẹ," wọn ṣalaye.
Oṣiṣẹ Israel kan sọ pe awọn olori ogun Hamas ti Israel fẹ ṣekupa ni Khalil al-Hayya, olori alarinna ati olori Gaza ti wọn le kuro ati Zaher Jabarin, olori ilu West Bank ti wọn le kuro.
Hamas ni apa ọta ko le ka wọn
Ninu atẹjade ti Hamas fi sita lẹyin ikọlu naa ṣapejuwe ikọlu Israel gẹgẹ bii eyi ti ko ba ofin agbegbe mu rara.
"A le fi da yin loju pe apa ọta ko ka wa nigba ti wọn fẹ ṣekupa awọn eeyan wa lasiko ijiroro," wọn sọ eyi lai pese ẹri kankan lati fi ti lẹyin
Ikọ agbebọn naa darukọ awọn eeyan marun un ti wọn padanu ẹmi wọn lasiko ikọlu naa, Ọmọ Khalil al-Hayya, Humam, ati olori Jihad Labad, oludari ọfisi Hayya.
Awọn olori lagbaye sọrọ lori ikọlu naa
Akọwe agba fun ajọ agbaye, UN, António Guterres bu ẹnu atẹlu ikọlu, to si ṣalaye pe ohun to tako ofin agbaye ni orilẹede Israel gunle pẹlu ikọlu si Qatar.
O ni orilẹede Qatar n gbe igbesẹ nla lati ri pe idaduro ogun waye ni, ki wọn sit u gbogbo awọn ẹlẹwọn silẹ.
O fikun, "gbogbo awọn ti ọrọ kan gbọdọ sisẹ lati fopin si ogun yii, ko ṣe pe ki wọn tun da ru."
Aarẹ orilẹede France, Emmanuel Macron ni ikọlu ọhun ko lẹ jẹ itẹwọgba rara, nigba ti Olootu ijọba UK, Sir Keir Starmer ṣe kilọ pe ikọlu yii tun le ọpọ rogbodiyan ni agbegbe wọn, ti oun naa si pe fun idadaduro ogun ati itusilẹ awọn ẹlẹwọn.
Pope Leo XIV sọ fun awọn akọroyin pe "ọrọ yii n lagbara si".
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
O kere tan, eeyan mẹfa lo ti jade laye, nigba ti awọn mẹfa mii tun farapa yanayana lẹyin ti awọn agbebọn ọmọ Palestinian kan kọlu awọn eeyan ni Jerusalem.
Ileeṣẹ ọlọpaa Israel sọ pe "Awọn agbesunmọmi meji wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ" wọn si bẹrẹ si n ṣina ibọn fun ọkọ akero.
Amọ ṣa, ọmọ ogun kan ati araalu kan da ina ibọn mii pada fun awọn agbebọn naa ti wọn si gbẹmi wọn.
Ileeṣẹ adoola ẹmi Magen David Adom ni Israel sọ pe lọwọ yii, eeyan mẹjọ lo n gba itọju lọwọ lẹyin ti ibọn ba wọn.
Bo tilẹ jẹ pe ko si ẹgbẹ kankan to tii kede pe oun lo wa nidi ikọlu naa, ẹgbẹ Hamas ti kan sara si ikọku ọhun.
Nigba ti olootu ijọba, Benjamin Netanyahu ṣabẹwo sibi ikọlu naa, o ni oniruru ọna lawọn ọta Israel fi n gbogun ti orilẹede oun.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọmọ ogun Israel ni gbogbo agbegbe to yẹ lawọn n ṣọ loju mejeji lati ri daju pe awọn agbesunmọmi ko ṣe akọlu si awọn eeyan nibẹ.
Ikọlu ọjọ Aje yii waye lasiko ti awọn eeyan n lọ si ibiṣẹ oojọ wọn ti ọpọ eeyan si n gbiyanju lati wọ ọkọ.
















