Ìjọba àpapọ̀ kéde iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tuntun fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti Pri 1 sí SS3

Akẹkọọ obinrin to n kọwe ninu kilaasi pẹlu olukọ rẹ lẹyin rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn koko ẹkọ yii ni ijọba gbe jade labẹ asia Basic and Senior Secondary Education Curriculum
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba apapọ ti kede awọn ilana ẹkọ fun awọn ọmọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ atawọn ọmọ ile ẹkọ girama kekere pẹlu ikilọ pe gbogbo ile ẹkọ lo gbọdọ tẹle awọn koko ilana eto ẹkọ tuntun naa.

Awọn koko ilana eto ẹkọ tuntun yii ni ijọba gbe jade labẹ asia Basic and Senior Secondary Education Curriculum.

Ninu ipade awọn akọroyin kan to waye ni ileeṣẹ ijọba to n ri si eto ẹkọ ti kilọ fun awọn to n gbe ayederu koko ẹkọ sita, eyii ti ko ti ọwọ ijọba wa.

Wọn ni eyii ṣe pataki fun awọn akẹkọọ lati maa kọ nipa nnkan ti yoo wulo fun ọjọ ọla wọn nikan.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, awọn koko ẹkọ naa yoo wa fun saa ẹkọ ọlọdun mẹta-mẹta akọkọ; ipele ẹkọ alakọbẹrẹ kinni (pri 1-3), ipele ẹkọ alakọbẹrẹ kẹrin (Pri 4-6), ipele ẹkọ girama kinni (JSS1) ati ipele ẹkọ girama keji (SS1).

Iwọnyii ni awọn koko ẹkọ alakọbẹrẹ kinni si ikẹta (Pri 1-3)

Akẹkọọ kọọkan gbọdọ ṣe koko ẹkọ mesan an o kere tan, tabi koko ẹkọ mẹwaa o pọ ju.

  • Ẹkọ ede Gẹẹsi (English)
  • Iṣiro (Mathematics)
  • Ede abinibi Naijiria kan – Yoruba, Hausa tabi Igbo
  • Basic Science
  • Physical & Health Education
  • Ẹkọ ẹsin Kristẹni fun awọn Kristẹni tabi ẹkọ ẹsin Islam fun awọn Musulumi
  • Itan orilẹede Naijiria
  • Social & Citizenship Studies
  • Cultural & Creative Arts (CCA)
  • Arabic (Kii ṣe dandan)

Iwọnyii ni awọn koko ẹkọ alakọbẹrẹ kẹrin si ikẹfa (Pri 4-6)

Akẹkọọ kọọkan gbọdọ ṣe koko ẹkọ mesan an o kere tan, tabi koko ẹkọ mẹwaa o pọ ju.

  • Ẹkọ ede Gẹẹsi (English)
  • Iṣiro (Mathematics)
  • Ede abinibi Naijiria kan – Yoruba, Hausa tabi Igbo
  • Basic Science &Technology
  • Physical & Health Education
  • Basic Digital Literacy
  • Ẹkọ ẹsin Kristẹni fun awọn Kristẹni tabi ẹkọ ẹsin Islam fun awọn Musulumi
  • Itan orilẹede Naijiria
  • Social & Citizenship Studies
  • Cultural & Creative Arts (CCA)
  • Pre-vocational Studies
  • Ede French (Kii ṣe dandan)
  • Ede Arabic (Kii ṣe dandan)

Iwọnyii ni awọn koko ẹkọ girama kinni si ikẹta (JSS1-3)

Akẹkọọ kọọkan gbọdọ ṣe koko ẹkọ mejila o kere tan, tabi koko ẹkọ mẹtala si mẹrinla o pọ ju.

  • Ẹkọ ede Gẹẹsi (English)
  • Iṣiro (Mathematics)
  • Ede abinibi Naijiria kan – Yoruba, Hausa tabi Igbo
  • Intermediate Science
  • Physical & Health Education
  • Digital Technologies
  • Ẹkọ ẹsin Kristẹni fun awọn Kristẹni tabi ẹkọ ẹsin Islam fun awọn Musulumi
  • Itan orilẹede Naijiria
  • Social & Citizenship Studies
  • Cultural & Creative Arts (CCA)

Ẹkọ imọ isẹ ọwọ kan o kere tan:

  • Solar Photovoltaic Installation & Maintenance
  • Fashion Design & Garment Making
  • Livestock Farming
  • Beauty & Cosmetology
  • Computer Hardware & GSM Repairs
  • Horticulture & Crop Production
  • Business Studies
  • Ede French (Kii ṣe dandan)
  • Ede Arabic (Kii ṣe dandan)

Iwọnyii ni awọn koko ẹkọ girama kẹrin si ikẹfa (SS1-3)

Imọ ẹkọ marun ọtotọ lo ṣe koko

  • Ẹkọ ede Gẹẹsi (English)
  • Iṣiro (Mathematics)
  • Ẹkọ nipa iṣẹ ọwọ kan
  • Citizenship & Heritage Studies
  • Digital Technologies

Awọn to fẹ kẹkọọ imọ Sayẹnsi

  • Biology
  • Chemistry
  • Physics
  • Agriculture
  • Further Mathematics
  • Physical Education
  • Health Education
  • Foods & Nutrition
  • Geography
  • Technical Drawing

Awọn to fẹ kẹkọọ imọ Humanities

  • Itan orilẹde Naijiria
  • Government
  • Ẹkọ imọ ẹsin Kristẹni
  • Ẹkọ imọ ẹsin Islam
  • Ede abinibi Naijiria kan
  • French
  • Arabic
  • Visual Arts
  • Music
  • Literature in English
  • Home Management
  • Catering Craft

Awọn to fẹ kẹkọọ imọ owo (Business)

  • Accounting
  • Commerce
  • Marketing
  • Economics
  • Ẹkọ iṣẹ ọwọ kan
  • Solar Photovoltaic Installation & Maintenance
  • Fashion Design & Garment Making
  • Livestock Farming
  • Beauty & Cosmetology
  • Computer Hardware & GSM Repairs
  • Horticulture & Crop Production