Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, Atiku, Obi àti ẹgbẹ́ èèyàn àríwá fajúro, bí Boko Haram ṣe pa èèyàn tó lé ní ọgọ́ta, wọn dábàá ọ̀nà àbáyọ sí ìkọlù agbébọn

Oríṣun àwòrán, HQNigerianArmy
Bi ikọ mujẹmujẹ Boko Haram se pa eeyan to le ni ọgọta ni ipinlẹ Borno, ọpọ araalu ati ẹlẹgbẹjẹgbẹ ti figbe ta lori isẹlẹ naa.
Ẹgbẹ awọn eeyan apa Ariwa orilẹede Naijiria wa rọ Aarẹ Bola Tinubu lati kede ilu o fararọ lori eto aabo, ko si fọwọ oṣi juwe ile fun awọn olori ileeṣẹ ologun lorilẹede Naijiria.
NENF ni eto aabo ni apa Ariwa n peleke si, ti awọn ileeṣẹ ologun ko si wa ọna abayọ.
Ninu atẹjade to fi lede, olori ẹgbẹ naa, Dominic Alancha ni pẹlu bi ijọba Tinubu ṣe ti gbe igbesẹ nla nipa ṣiṣe atunṣe eto ọrọ aje, o tun ni lati gbe igbesẹ nla miiran lori bi eto aabo ṣe mẹhẹ ni apa Ariwa Naijiria.
"Inu n bi wa, ẹ yọ awọn olori ileeṣẹ ologun Naijiria kuro nipo, ki ẹ fi àwọn mii rọpo wọn kiakia"
NENF ni "Ipo ti eto aabo wa n buru si ni apa ariwa Naijiria.
Lojojumọ ni awọn janduku n kọlu awọn agbegbe wa. Eyi jẹ ohun ti a ko le tẹwọgba."
NENF tun fẹsun kan awọn olori ileeṣẹ ologun pe wọn kuna lati ṣe ohun to tọ pẹlu bii wọn ṣe ti gba ọpọ owo fun eto aabo.
"Inu n bi wa, ti a si n beere pe ki wọn yọ awọn olori ileeṣẹ ologun lorilẹede Naijiria kuro nipo, ki wọn si ropo wọn ni kiakia.
Aarẹ ni lati yan awọn mii, ti wọn ni oye lati ṣe ohun to tọ ni apa ariwa," atẹjade naa ṣalaye.
A ti gba awọn asọgbo lati ti awọn ologun lẹyin ninu igbo - Gomina Zulum
Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Umara Zulum ti pe fun igbanisiṣẹ awọn akọsẹmọsẹ asọgbo lati ṣe atilẹyin fun ileeṣẹ ologun,
Ipe yii lo waye lẹyin ti ikọ agbebọn, Boko Haram ṣekupa eeyan mẹtalelọgọta, to fi mọ ologun marun un, ni abule Darajamal ni ijọba ibilẹ Bama nipinlẹ Borno.
Zulum, ẹni to ṣe abẹwo si agbegbe naa lọjọ Ṣatide, ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyi to ba ni lọkan jẹ, to si ba awọn mọlẹbi kẹdun.
"A ni lati fidi rẹ mulẹ pe, iye awọn ologun to n koju awọn janduku ko to rara ni gbogbo ẹka.
A ti kọ awọn asọgbo, ti a o da wọn sinu igbo pẹlu awọn ologun lati ṣawari ibi ti awọn agbebọn yii wa .
"Bakan naa ni wọn yoo maa pese fun awọn agbegbe wa ati inu igbo."
Ajọ isọkan orilẹede agbaye, UN koro oju si iṣẹlẹ iṣekupani to waye ni Borno
Iṣekupani to waye lati ọwọ ẹgbẹ agbebọn Boko Haram nipinlẹ Borno, eyi to ṣekupa eeyan 63 ti fa ọpọ ibinu ati ifẹhonuhan lati ọdọ ọpọ eeyan.
Ajọ isọkan orilẹede agbaye, igbakeji aarẹ nigba kan ri, Atiku Abubakar ati oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu, Labour, Peter Obi ti sọrọ lori isẹlẹ naa.
Olori ẹka ajọ isọkan agbaye ni Naijiria, Mohamed Fall ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyi to ba ni lojiji, to si tun ba ni lọkan jẹ.
O ni ko yẹ ki araalu jẹ ohun ikọlu fun awọn agbebọn, to si rọ awọn alaṣẹ pe ki wọn ri daju pe ọwọ tẹ awọn janduku naa.
"Iṣẹlẹ to waye ni ọjọ Ẹti lori bi ikọ Boko Haram ṣe sekupa ọpọ eeyan ni abule Darajamal, nijọba ibilẹ Bama nipinlẹ Borno, ba ni lọkan jẹ.
"Ko yẹ ki araalu jẹ ohun ikọlu fun awọn agbebọn.
Iwadii ni o le ni aadọta araalu to padanu ẹmi wọn, ti wọn si tun ji ọpọ gbe lọ, to si le ni ilegbe mejidinlọgbọn ti wọn dana sun."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Awọn ọmọ Naijiria gbọdọ parapọ gbe ogun ti awọn agbebọn - Atiku
Igbakeji aarẹ aarẹ nigba kan ri, Atiku Abubakar, ti bu ẹnu atẹlu ikọlu to waye nipinlẹ Borno, to si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii eyi ti ko mu ọpọlọ dana.
Atiku ninu ọrọ to gbe sita lori ayelujara ni orilẹede Naijiria yoo tunbọ ma ji iya awọn agbebọn ti wọn ko ba parapọ lati gbe ogun ti wọn.
"O n ransẹ ibanikẹdun si awọn mọlẹbi ti ọrọ kan, awọn eeyan ipinlẹ Borno ati Gomina Zulum."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ilu o fararọ ni ẹka eto aabo – Obi
Oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi ti ṣe kilọ pe orilẹede Naijiria si n wọ oko orilẹede ti ogun n ba wọn ja, to si rọ Aarẹ Bola Tinubu pe ki o kede ogun tabi eto aabo to mẹhẹ.
Loju opo ayelujara X, Obi ni: "Ipari ọsẹ ẹlẹjẹ: eeyan ọgọrun padanu ẹmi wọn ni Borno, Sokoto, Katsina, Edo. Eyi fihan pe orilẹede Naijiria n koju eto aabo to mẹhẹ.
"Ko si iyatọ ninu Naijiria ati awọn orilẹede to n jagun lọwọ pẹlu bi a ṣe n padanu ọpọ eeyan."
Gomina nigba kan ri nipinlẹ Anambra kilọ pe ti ijọba ko ba gbe igbesẹ to yẹ, ikọlu si ṣe akoba nla fun orilẹede Naijiria ti ni Somalia ati Libya
"Itan fihan pe eto aabo to mẹhẹ lo ya lati da orilẹede ru ju. A ni lati gbe igbesẹ ni kiakia, lati tun orilẹede yii kọ si orilẹede to ni aabo fun araalu."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3

Oríṣun àwòrán, Boko Haram
Boko Haram ṣekúpa èèyàn 60 ní Borno, ariwo sọ
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram ti ṣekupa ọgọta eeyan ninu ikọlu orumọju kan nipinlẹ Borno.
Ilu Darul Jamal, to jẹ ibi ti ikọ ọmọ ogun Naijiria n tẹdo si ni ala Naijiria ati Cameroon ni ikọlu naa ti waye, nibi ti wọn ti ṣekupa ọmọ ogun marun un.
Ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu Naijiria ti sọ pe oun ti ṣekupa ọmọ ẹgbẹ naa ti iye wọn jẹ ọgbọn lẹyin ikọlu ọhun.
A gbọ pe ibi ti ikọlu naa ti waye jẹ agbegbe ti awọn eeyan ti fi ile wọn silẹ ṣaaju amọ wọn ti n pada sibẹ ṣaaju ikọlu ọhun.
O kere tan, ile ogun ati ọkọ akero bọọsi mẹwaa ni wọn bajẹ ni Darul Jamal, nigba ti wọn ṣekupa awọn awakọ ati agbaṣẹṣe mẹtala.
Gbogbo awọn to ku lo jẹ awọn to n gbiyanju lati tun ilu naa kọ.
Nigba to ṣabẹwo si abule naa lọjọ Abamẹta, gomina Babagana Zulum sọ pe "O ṣeni lanu pe larin oṣu diẹ sẹyin lawọn eeyan ṣẹṣẹ n pada si abule yii ti wọn si n ba iṣẹ ounjẹ oojọ wọn lọ nibẹ.
"Iye awọn ọmọ ogun ti a ni ko to lati koju ipenija yii."
O fi kun pe awọn ti tun ti ṣagbekalẹ ikọ alaabo to n ṣo inu igbo nibẹ lati jawe sobi eto abo agbegbe ọhun to mẹhẹ.
Agbẹnusọ ileesẹ ọmọ ogun ofurufu, Ehimen Ejodame sọ pe ayẹwo awọn lati oju ofurufu fi han pe awọn ọmọ agbesunmọni naa n salọ si iha ariwa ninu igbo.
O ni "Igba mẹta ọtọtọ ni a kọlu awọn agbesunmọmi naa lasiko ti wọn n salọ ninu igbo ti a si gbẹmi ọgbọn ninu wọn."
Ijọba naijiria ti tunbọ jawe sobi akitiyan tẹ lati rẹyin awọn agbesunmọmi naa ninu ọdun yii lẹyin ti awọn agbesunmọmi ọhun bẹrẹ si n kọlu awọn ibudo awọn jagunjagun rẹ.
Ẹgbẹ wo ni Boko Haram?
Ninu oṣu Kẹrin ọdun yii, gomina Zulum sọ pe Boko Haram yoo pada bẹrẹ akọlu tuntun.
Lati nnkan bii ọdun marundinlogun ṣeyin ni Boko Haram ti n da ipinlẹ Borno laamu.
Nnkan bii miliọnu meji eeyan lo ti di alairilegbe ti ẹgbẹrun lọna ogoji eeyan si dero ọrun latari awọn ikọlu ẹgbẹ alakakiti ẹsin naa.
Ọdun 2015 ni ẹgbẹ naa ṣaṣeyọri julọ latari bi ọpọ agbegbe ṣe wa ni iṣakoso rẹ nipinlẹ Borno.
Amọ ọdun kan ṣaaju ọdun naa ni orukọ ẹgbẹ ọhun tan kaakiri agbaye lẹyin ti wọn ji akẹkọọ ọgọrun ati aadọta gbe nile ẹkọ girama ilu Chibok.
Titi di asiko yii, awọn kan lara awọn akẹkọọ naa ṣi wa ni ahamọ Boko Haram.















