Ẹ̀jẹ̀ nínú ìgbọ̀nsẹ̀ àti ìtọ̀, ǹjẹ́ ó léwu bí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Redacción
- Role, BBC News Mundo
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Nnkan yii jẹ ohun to wọpọ lawujọ, to si ma n ba ọpọ lẹru.
Ọpọ lo ma n pariwo nigba ti wọn ba ri ẹjẹ ninu itọ wọn, ti wọn yoo si ma ro pe boya wọn ti lugbadi aisan kan tabi wọn ti ni aarun jẹjẹrẹ.
Nnkan ti ko ye wọn ni pe, ọpọ idi lo le ṣokunfa eyi, ti wọn si ju ara wọn lọ.
Fermin Mearin, ọnimọ eto ilera ni Spain ṣe akọsilẹ awọn ohun to ṣokunfa ki ẹjẹ wa ninu itọ tabi igbọnsẹ fun BBC Mundo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbona inu: Eyi ma n waye ti ẹjẹ kekere ba n da lati inu, ti wọn si le ri lẹyin ti ohun ti a n pe rectum ba ti ṣi.
"Eyi tumọ si pe ẹjẹ n jade lati ibi ti opin rectum yii, to si jẹ pe ibẹ ni iṣoro wa," D dokita Mearín ṣalaye.
Hemorrhoids: ti o ma n jade ni idi eeyan jẹ ohun ti wọn ko le fi oju lasan ri, ṣugbọn wọn le ri ti wọn ba ṣe ayẹwo.
Ti egbo ba wa nibi idi yii, o le fa ki ẹjẹ ma n jade lasiko igbọnsẹ, paapa fun eeyan ti ko ba ki n mu omi daadaa, ti igbọnsẹ naa yoo si le pupọ. Eyi le fa ọpọ inira, ti yoo si ma yọ ẹjẹ.
Aisan inu: Eeyan to ba lugbadi aisan 'ulcerative colitis', eyi ma n fa igbona ni ikun ti yoo si maa yọ to ba n ṣe igbọnsẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dokita naa sọ siwaju si pe "Ninu awọn nnkan bayii, lati ṣe afikun si igbona, igbẹ gbooru ati inu didun yoo tun waye."
Wọn yoo ṣe akoba nla fun ikun nla, ti aisan Crohn yoo si kọlu ikun kekere.
Eyi ma n mu ayipa ba igbẹ lati dudu si pinpọn.
Ti igbẹ ba dudu, to si jade pẹlu ẹjẹ, o le tumọ si pe ọpọ ẹjẹ wa ninu ikun lasiko naa.
Ni awọn orilẹede kan, ilana wa ti wọn fi ma se ayẹwo to da lori ọjọ ori eeyan naa.
Eyi bẹrẹ pẹlu ṣiṣe awari ẹjẹ ninu igbẹ eeyan lati mọ boya o ni aisan jẹjẹrẹ Colon.
Ti ẹjẹ ba wa ninu itọ, wọn yoo fi iru eeyan bẹẹ sori ọpọ ayẹwo, eyi to le jẹ ki ọpọ bẹru.
"Awọn eeyan ma n wa fun ayẹwo pẹlu oye kekere, ṣugbọn pupọ ninu wọn ni lo jẹ pe wọn ko ni iṣoro nla," Mearin ṣalaye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images












