Ǹ jẹ́ ikọ̀ agbábọ́ọ́lù Super Eagles ti Nigeria ṣì le lọ ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé?

Aworan tabili ere bọọlu ati Tolu Arokodare ninu aṣọ ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Naijiria Super Eagles

Oríṣun àwòrán, NG-SUPER EAGLES/GOOGLE

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Pẹlu bii ikọ Super Eagles ṣe ti bori ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu orilẹede Rwanda ninu idije igbaradi fun idije ife ẹyẹ agbaye, ọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu lo ti koroju si bi ifẹsẹwọnsẹ naa ṣe lọ.

Ifẹsẹwọnsẹ ọhun lo waye niluu Uyo lorilẹede Naijiria, to si jẹ pe goolu kan soso to waye nibi ifẹsẹwọnsẹ wa lati ọwọ Tolu Arokodare, to jẹ agbaọwọ iwaju fun ikọ Super Eagles.

Ipo kẹta ni orilẹede Naijiria wa lori tabili bayii, ti orilẹede South Africa ati Benin si wa ni ipo kinni ati ikeji.

Orilẹede South Africa ati Naijiria yoo wa wako lọjọ Isẹgun, ọjọ kẹsan an, ọsu kẹsan an ọdun 2025 niluu South Africa.

Ti orilẹede Naijiria ba bori ifẹsẹwọnsẹ pẹlu South Africa, igbagbọ si jẹyọ boya wọn si ni anfani lati lọ fun idije ife ẹyẹ agbaye lọdun to n bọ.

Ni bayii, ami ayo mẹwaa ni Naijiria ni, ti South Africa si ni mẹrindinlogun.

Ifẹsẹwọnsẹ mẹta loku bayii lati mọ boya ikọ Super Eagles yoo kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye.

Aworan Tolu Arokodare ninu aṣọ ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Naijiria Super Eagles

Oríṣun àwòrán, NG-SUPER EAGLES

Ki ni awọn araalu sọ lẹyin ifẹsẹwọnsẹ ana?

Ọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu ati Super Eagles ti bọ sori ayelujara lati fẹhonuhan lori ifẹsẹwọnsẹ pẹlu orilẹede Rwanda.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

@thewaleogun: "Ikọ yii ko ki n ṣe rara, o dara ti a ko ba lọ fun ife ẹyẹ agbaye."

@royaleweb3_: "A ni lati karamọri kini yii. Gbigba bọọlu ni idije ife ẹyẹ agbaye tumọ si bibori. A ko le mi awọn mẹta pẹlu Rwanda."

@Utd_9X: "Eyi ki n ṣe aṣeyọri ti a fẹ ṣugbọn a gba bẹẹ.."

@dapzinfash: "Ọlọrun yọọ baba yin. Mo ti kọ epe silẹ fun yin, ti ma fi ransẹ si yin ni ọkọkan."

@WorthyGodwin1: "Ko ba jẹ pe wọn gba wọle fun ara wọn, e ri pe bori lorilẹede SA. A dara pupọ ṣugbọn a ni lati igbiyanju si oooo."

@lebar4real: "Ni ifẹsẹwọnsẹ ọjọ Isẹgun. South Africa, a n bọ wa lati wa bori ni. A ni lati kọ bi a o sẹruba awọn alatako wa. O buru pe a ni ọpọ agbaọwọ iwaju ṣugbọn a ko le mi awọn."

@Joe_o_X: "Ki lo de ti ẹ fẹran goolu kan soso bayii; ṣe o buru ju ti ẹ ba mi awọn pupọ ni?"

@Ohams4NewNaija: "A nilo ọpọ goolu."

@Azeez_Maleek: "A nilo ọna miran nigba ti a ba koju South Africa. A ko le ma gba bọọlu bayii, ki a ma reti pe a o bori ni ita ile wa. Ifẹsẹwọnsẹ to kan bayii ṣe pataki. Ẹ jẹ ka ba tikẹẹti yii."

@Famousity2222: "N jẹ ere bọọlu ni eyi? Rwanda lasanlasan! Super Eagles ti tan."