Ọ̀pọ̀ 'Olosho' àti àwọn ọmọbinrin tó ń ṣe 'hookup' ni ayélujára ti sọ di oníṣẹ́ gidi lọ́wọ́ - Peller

Àkọlé fídíò, Bí ìjọba bá lè ṣe ohun tó yẹ, ayélujára lè fún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́, kódà àwọn ‘olosho’ gan níṣẹ́ - Peller
Ọ̀pọ̀ 'Olosho' àti àwọn ọmọbinrin tó ń ṣe 'hookup' ni ayélujára ti sọ di oníṣẹ́ gidi lọ́wọ́ - Peller

Gbajumọ ori ayelura, Habeeb Hamzat ti ọpọlọpọ eeyan mọ si Peller ti sọ pe ijọba ni ọpọlọpọ iṣẹ lati ṣe ;ati le ri i pe awọn ọdọ n lo ayelujara atawọn oju opo rẹ gbogbo lati pa owo lọna to ba ofin mu.

Peller sọ ọrọ yii lasiko to fi n ba BBC News Yoruba sọrọ.

Peller sọ pe ọpọ anfani wa ti awọn ọdọ bii toun le jẹ ni orilẹede Naijiria bi ijọba ba le gbe igbesẹ to ba yẹ ki awọn ọdọ le ṣamulo awọn ikanni ayelujara gbogbo fun idagbsoke ilu ati ara wọn.

Igbesi aye mi ni mo n gbe lori ayelujara

Peller joko pẹlu agbabọọlu ọmọ Naijiria, Victor Osimhen.

Oríṣun àwòrán, peller/instagram

Nigba to n sọ itan igbesi aye ara rẹ, Peller ṣalaye pe ọdun 2023 ni irinajo oun bẹrẹ lori ayelujara. o ni igbesi aye oun loun n gbe lori ayelujara nitoripe ohun ti oun n ṣelojumọ naa loun n ṣe, iyatọ ibẹ kan ni wi pe oun n gbe e si ori ayelujara fun araye lati ri.

"Nigba ti mo bẹrẹ, bii ki eeyan marun, mẹta maa wo mi lori ayelujara ni, maa dẹ tun maa pariwo tatata ni..."

o ni lọwọ yii nnkan ti ṣẹnure fun oun nitori pe Eleduwa ti fi ifẹ oun si awọn eeyan lọkan to bẹẹ gẹ to fi jẹ pe ki oun maa tii tan foonu oun ni, ọpọ eeyan ni yoo ti bo o lati wo oun lori ayelujara.

Nitori Tiktok gan awọn olosho ti dinku - Peller

Peller ati ọrẹbinrin rẹ duro ya fọto.

Oríṣun àwòrán, peller/instagram

Gbajumọ ori ayelujara naa tun ṣalaye pe "itori Tiktok gan awọn olosho ti dinku" nigboro.

O sọ eyi nigba to n yannana awọn anfani to wa lori lilo ayelujara fun awọn ọdọ.

O ni fun oun o, lilo ayelujara ti di iṣẹ to si mu ọpọlọpọ ere ati owo wa fun oun.