"Ọmọ ọdún méjìlélógún ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìyá fún àwọn ọmọ méjìléláàdọ́ta tí kò ní ìyá"

Àkọlé fídíò, "Ọmọ ọdún méjìlélógún ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìyá fún àwọn ọmọ méjìléláàdọ́ta tí kò ní ìyá"
"Ọmọ ọdún méjìlélógún ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìyá fún àwọn ọmọ méjìléláàdọ́ta tí kò ní ìyá"

Arabinrin Joy Taiwo to jẹ oludari ile awọn ọmọ alaini iya, 'Oyiza Orphanage and Foster Foundation' to n bẹ nilu Ibadan n'ipinlẹ Ọyọ ba BBC yoruba sọrọ lori ṣẹlẹ to sọ ọ di alamojutọ ọsan gangan fun awọn ọmọ mejilelaadọta nigba ti oun gan an ṣi wa ni ọmọ ọdun mejilelogun.

Iya rẹ, Arabinrin Oyiza Idris to jẹ Nọọsi nigba aye rẹ lo da ile awọn ọmọ alaini iya naa silẹ ko to di pe o jade laye lẹni ọdun marundinlaadọta lẹyin aisan ranpẹ.

Iṣẹlẹ yii lo sun Joy ati ẹgbọn rẹ de ipo agba nitori wọn ko fẹ ki iṣẹ iya wọn parun.

Aworan awọn ọmọ naa.

Arabinrin Joy tun ṣe alaye awọn okanojọkan ipenija ti wọn koju gẹgẹ bii ọmọde to n tọju awọn ọgọrọ ọmọ alaini iya. Lara awọn ipenija naa ni bi Joy ṣe n pa kilaasi jẹ nigba ti oun naa wa nile ẹkọ Nọọsi ni Fasiti ilẹ Ibadan ati bi o ṣe ni lati tun awọn idanwo kan ṣe nitori amojuto awọn ọmọ alaini iya naa.

Bakan naa lo tun ṣe alaye wi pe oun ti le ni ẹni ọgbọn ọdun ki oun to ṣe alabapade ọkọ oun, nitori gbogbo awọn ti o n kọ ẹnu ifẹ si oun saaju akoko naa ni wọn maa n sa lọ ti oun ba ti mu wọn de ile ti oun ti n tọju awọn ọmọ alaini ni iya mejilelaadọta.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe ọkọ ti oun pada fẹ ti ṣe ọpọlọpọ anfani fun awọn ọmọ naa, pupọ wọn si ni wọn ti ṣe aṣeyọri lẹnu ẹkọ wọn.